Okomu National Park
Okomu National Park, tí a mọ̀ tẹ́lẹ̀ sí Okomu Wildlife Sanctuary, jẹ́ igbó kan tí ó wà ní inú Okomu Forest Reserve ní ìjọba ìbílẹ̀ Ovia South-West ti Ìpínlẹ̀ Ẹdó, orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Pápá ìṣeré náà wà fi kìlómítà ọgọ́ta jìnà sí Benin City.[1] Igbó tí ó wà ní ẹgbẹ́ pápá ìṣeré náà jẹ́ ilé fún àwọn oríṣiríṣi àwọn ẹranko, pẹ̀lú pẹ̀lú àwọn tí irú wọn ti fẹ́ parun ní ilẹ̀ àgbáyé. Igbó náà ń dínkù si nítorí abúlé tí ó wà níbẹ̀, ó sì jẹ́ ìdásí mẹ́ta títóbi rẹ̀ tẹ́lẹ̀.[2] Àwọn ilé isé kọ̀kan tún ń gegi nínú igbó náà.[3]