Olatokunbo Olopade
Olatokunbo Oduyinka Olopade, CON jẹ́ onímọ̀ amòfin lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ẹni tí wọ́n yàn sípò àgbà onídàájọ́ ní ìpínlẹ̀ Ogun. Òun ni ìdájọ́ obìnrin àkọ́kọ́ láti ìgbà ìdásílẹ̀ ìpínlẹ̀ náà. [1][2]
Olatokunbo Oduyinka Olopade | |
---|---|
Chief Judge of Ogun State | |
In office 27 September 2011 – August 2018 | |
Asíwájú | Oluremi Jacobs |
Arọ́pò | Mosunmola Dipeolu |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 1953 (ọmọ ọdún 70–71) |
Ayé Àti Iṣẹ́ Rẹ̀
àtúnṣeỌdún 1953 ni wọ́n bí Olopade. Ó kẹ́kọ̀ọ́ alákọbẹ̀rẹ̀ àti gíràmà ní ilé-ìwé Queens, Èdè àti Adéọlá Odùtọ́lá College, Ìjèbú-òde lẹ́sẹsẹ̀. Ó gba òye nípa òfin ní Fásítì Ifẹ̀, tí wọ́n sì pè é sí Ilé-ìgbìmọ̀ ní ọdún 1976. Ó ti ṣiṣẹ́ tẹ́lẹ̀ ní ẹ̀ka ètò ìdájọ́ fún ìpínlẹ̀ Edo àti Èkó. Ṣáájú yíyàn rẹ̀ bí adájọ́ àgbà, ó jẹ́ agbẹjọ́ro ìpínlẹ̀ (1978), olùdarí ti ìbánirojọ́ gbogbo ènìyàn (1993), lẹ́hìn náà adájọ́ àgbà (2011). [3] Ní Oṣù Kẹjọ ọdún 2018, ó fẹ̀hìntì kúrò ní ipò rẹ̀ pẹ̀lú Honorable Justice Mosunmola Dipeolu tó rọ́pò rẹ̀ ní agbára iṣẹ́.[4]
Ó jẹ́ olùgbà ti ọlá orílẹ̀-èdè, alákoso àṣẹ ti Niger. [5]
Àwọn Ìtọ́ka Sí
àtúnṣe- ↑ "Amosun swears in first female Chief Judge". Vanguard. Retrieved 2018-09-05.
- ↑ "Ogun Gets First Female Chief Judge". PM News. Retrieved 2018-09-05.
- ↑ "Ogun Swears In First Female Chief Judge". Nigerian Voice. September 27, 2011. Retrieved 2018-09-05.
- ↑ "Ogun State Gets Acting Chief Judge as Justice Olatokunbo Olopade Retires". August 27, 2018. Archived from the original on 2020-12-05. Retrieved 2018-09-05.
- ↑ "Office of the Chief Registrar High Court of Justice". Ogun State Government. Archived from the original on 2018-09-16. Retrieved 2018-09-05.