Olu Falae

Olóṣèlú
(Àtúnjúwe láti Olu falae)

Samuel Oluyemisi Falae CFR (Ọjọ́ọ̀bí Ọjọ́ kọkànlélógún oṣù Ọ̀wàrà, ọdún 1938). Tí a mọ̀ sí Olu Falae, jẹ́ òṣìṣẹ́ Iléeṣé - ìfowópamọ́,[1] alákòóso àti olóṣèlú láti Àkúrẹ́, Ìpínlẹ̀ Òǹdó. Akọ̀wé ìjọba ológun Babaginda ni lọ́dún January 1986 sí December 1990[2] ó sì jẹ́ mínísítà owóńná fún àsìkò ránpẹ́ ní ọdún 1990. Ó díje dupò Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà[3] ní ìjọba Olómìnira elẹ́kẹ̀ẹtà àti ẹlẹ́ẹ̀kẹrìn.

Samueli Olúyẹ́misí Fálaè
Alakoso Eto Inawo
In office
1988–1991
Akowe Ijoba Apapo
In office
1986–1988
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí21 Oṣù Kẹ̀sán 1938 (1938-09-21) (ọmọ ọdún 86)
Akure, Naijiria



Ìgbé àyè àti ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí Falae sínú ìdílé Olóyè  Joshua Alekete àti Abigail Aina Falae ní  ọjọ́ kọkànlélógún oṣù Ọ̀wàrà, ọdún 1938 ní ìlú Abo, Àkúrẹ́. Ọmọ ìlú Òǹdó ni Joshua Falae ṣùgbọ́n torí àwọn àǹfààní tó wà nínú àgbẹ̀ kókó, ẹbí Falae àti díẹ̀ lára àwọn ọmọ Àkúrẹ́ kó lọ sí ìletò kan tó súnmọ́ tí wọ́n pé ní Ago-Abo tí a tún mọ̀ sí Ìlú Abo níbi tí wọ́n tẹ̀dó sí bíi olùdásílẹ̀. Wọ́n padà fi Bàbá Falae jẹ olóyè abúlé Ago - Abo. Ìlú Ìgbàrà-Òkè ni wọ́n tí bí àti tọ́ Ìyá Falae ó sì kú lásìkò tó ń bímọ ní ọdún 1946 nígbà tí Falae jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ péré. Bàbá àti Ìyá Bàbá ré ni wọ́n tọ dàgbà. Ìyá bàbá rẹ̀ ni (Olóyè Ọ̀sanyìntuke Falae - (ọmọ Adedipe) tí ó jẹ ọmọọmọ iya Déjì tí Àkúrẹ́ àti ọmọ Elemo ti Àkúrẹ́, Olóye Adedipe Oporua Atosin (Òun fúnra rẹ̀ ọmọ-ọmọ Déjì Arakale ti Àkúrẹ́, Bàbá Òṣùpá). Falae lọ sí ilé - ẹ̀kọ́ alákọ̀bẹ́ẹ̀rẹ̀ Anglican ní ìlú Àkúrẹ́ níbi tí ó pàdé ìyàwó rẹ̀ tí ó fẹ́ Rachel Òlátúnbọ̀sún Fáshọ̀rántí, àbúrò olórí Afẹ́nifẹ́re Reuben Fáṣhọ̀rántí. Lẹ́yìn tí ó parí ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀, ó ṣe ìdánwò láti wọlé sí Kọ́lẹ́jì Igbóbì, wọ́n sì gbà á wọlé ní ọdún 1953. Nígbà tí ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ni Igbóbì, ó lọ parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ni Kọ́lẹ́jì Ìjọba, Ìbàdàn n

Ní ọdún 1958 fún ìwé ẹ̀rí gíga ilé - ẹ̀kọ́. Ó padà di Olùkọ́ ní Ilé-ẹ̀kọ́ Girama Oyemekun, Àkúrẹ́. Ó lọ sí Yunifásítì  Ìbàdàn ó sì kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ẹ̀kọ́ ọ̀rọ̀ -ajé (Economics). Lẹ́yìn náà ó lọ sí Yunifásítì Yale ní ìlú Amẹ́ríkà . Ní Yunifásítì Ìbàdàn, ó sójú gbọ́gan ibùgbé rẹ̀ ní ẹgbẹ́ aṣojú àwọn akẹ́kọ̀ọ́, ó sì jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ olótùú tí magasínì tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nínú ọgbà ilé ẹ̀kọ́.

Ipa rẹ̀ nínú ìṣèlú

àtúnṣe

Nígbà tí ó parí ẹ̀kọ́ dìgírì nínú ètò ọ̀rọ̀ ajé Falae darapọ̀ mọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba gẹ́gẹ́ bí igbákejì akọ̀wé, Ẹgbẹ́ àwọn àpapọ̀ áwọn òṣìṣẹ́ Orílẹ̀èdè. Ó padà di olùrànlọ́wọ́ akọ̀wé àgbà. Ní ọdún 1971, wọ́n gbé lọ sí Iléeṣé ìṣètò gbòógì (Central Planning Office). Lásìkò rẹ̀ ní iléeṣẹ́ yìí, ẹ̀ka yìí kópa nínú ìgbékalẹ̀ Ètò ìdàgbàsókè fún Orílẹ̀èdè ìkẹta (Third National Development Plan) àti Ṣíṣe àtúnyẹ̀wò iṣẹ́ tí ìjọba bá ti yí padà. Ní ọdún 1977, wọ́n yan Falae gẹ́gẹ́bí akọ̀wé àgbà (ẹ̀ka Ọ̀rọ̀ - ajé), ọ́físì àwọn aṣojú ìjọba. Ní ọdún, ó di olùdarí àgbà Báǹkì Nigerian Merchant, tí a mọ̀ sí United Dominion Trust. Lásìkò ìṣàkóso rẹ̀ ni Báǹkì náà, iléeṣẹ́ náà mú àlékún bá owó yíya tí wọ́n fi àṣẹ sí. Falae padà sí iṣẹ́ ìjọba ní ọdún 1986, nígbà tí wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bíi akọ̀wé fún ìjọba. Lásìkò yìí, ó lérò wí pé Nàìjíríà nílò àtúntò ọrọ̀ - ajé. Ní ọdún 1985, ṣáájú ìgbaaṣẹ́ rẹ̀, ìjọba ológun béèrè fún èrò àwùjọ tí IMF (Èròngbà Àtúnṣe Ọrọ̀-ajé) Economic Structuring Proposal gẹ́gẹ́ bíi ìdí fún owó yíyá láti ara owó náà. Wọ́n kò gbà èrò yìí wọlé. Ìjọba tó ń ṣàkóso nígbà yẹn gbé Ètò Àtúnṣe Àgbékalẹ̀- Structural Adjustment Programme (SAP).

Ó fi ipò akọ̀wé ìjọba silẹ láti ṣe mínísítà ètò owóńná ìjọba àpapọ̀ ní ọdún 1990 ní àsìkò ìjọba ológun Ibrahim Babaginda. Wọ́n yọ ọ́ ní iṣẹ́ ní Oṣù Ògún ọdún 1990. Lẹ́hìn náà, ó darapọ̀ mọ́ ètò ìyípadà ìjọba àwarawa.




Àwọn Itoka si

àtúnṣe
  1. "Ex-Minister of Finance, Olu Falae, kidnapped". Premium Times Nigeria. 2015-09-21. Retrieved 2021-11-11. 
  2. "PROFILE: Olu Falae - Nigeria National Conference". Nigeria National Conference. 2014-03-17. Retrieved 2021-11-11. 
  3. "Presidential race between Falae and Obasanjo". The New Humanitarian. 1999-02-16. Retrieved 2021-11-11.