Oluyemi Kayode
Olusare fún Nàìjíríà
Olúyẹ́misí Káyọ̀dé jẹ́ asáré orí ọ̀dàn ọmọ Nàìj́iríà. Wọ́n bí ní (July 7, 1968 – October 1, 1994). Káyọ̀dé jáwé olúborí nínú ifẹsẹ̀-wọnsẹ̀ 4 x 100 m nínú ìdíje ti 1992 Olympic Games ní Barcelona, Spain, òun pẹ̀lú ikọ̀ rẹ̀ ChidiImoh, Olapade Adeniken àti Davidson Ezinwa. Ó tún gba àmì silver medal níńu 200 metres níbi ìdíje 1993 African Championships òun nìkan sì ni ọmọ ilẹ̀ Nàìjírí̀a tí ó t́iì gba irúfẹ́ àmì ẹ̀yẹ yìí ńińu irú ìfẹsẹ̀-wọnsẹ̀ yí ní ọdún 1993 àti 1994. Ó gbé ipò kẹfà nínú ìfẹsẹ̀-wọnsẹ̀ ti 200 metres nínú id̀íje 1994 Commonwealth Games. Káyọ̀dé kú nínú ìjà̀nb́a ọkọ ní Northern Arizona ní oṣù October 1994.[1] wọ́n sọ pápá ìṣeré kan ní orúkọ rẹ̀ ní ìlú Adó-Èkìtì ní ìrántí rẹ̀.
Àwọn Ìtọ́ka sí
àtúnṣe- ↑ "Oluyemi KAYODE - Profile". iaaf.org. Retrieved 2018-05-22.