Àwon omo Yorùbá

Àwọn ọmọ Yorùbá ń jẹ ẹ̀yà tó ń gbé ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn àti àríwá apa àrin Nàìjíríà, àti gúúsù pẹ̀lú apa àrin Benin. Lápapọ̀, àwọn agbègbè yí ń jẹ ilẹ̀ Yorùbá. Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ọmọ Yorùbá ń gbé ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Níbẹ̀, wọn jẹ okanlelogun nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ará Nàìjíríà. Àwọn ọmọ Yorùbá ń jẹ ogójì mílíọ̀nù papò, wọn dẹ́ jẹ ìkan nínú àwọn ẹ̀yà tó tóbi jú ní Áfríkà. Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ọmọ Yorùbá máà ń sọ èdè Yorùbá. Èdè Yorùbá náà jẹ èdè Nìjẹ̀r-Kóńgò tó ní olùbánisọ̀rọ̀ ìbílẹ̀ tó pọ̀ jù.