Omololu Falobi
Omololu Falobi (1971-oṣù kẹwàá 5, 2006) jẹ́ oníṣẹ́ ìròyìn ní orílẹ̀ èdè Naijiria, ó sì jẹ́ ajìjàgbara àrùn AIDS. Ní ọdún 1997 ó ṣe ìdásílẹ̀ JAAIDS. Wọ́n ṣe ìdàsílẹ̀ ẹ̀yẹ Ọmololu Falobi ní orúkọ rè.[1]
Ní ọdún 1998, ó ṣe ìdásílẹ̀ JAAIDS, tí ó jẹ́ àjọ tí kìí ṣe ti ìjọba pẹ̀lú èròńgbà láti kó àwọn oníṣẹ́ ìròyìn tí ó wà lórílẹ̀ èdè jọ láti kọ́ wọ́n ní ẹ̀kọ́ nípa ìjàmbá àrùn AIDS àti ọ̀nà dẹ́kun rẹ̀.[2] Ní ọdún 2004 àti ọdún 2005, ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn aṣojú Joint United Nations Programme on HIV/AIDS.[3]
Ó fi ilẹ̀ ṣaṣọbora ní ọjọ́ karùn-ún oṣù kẹwàá, ọdún 2006 ní ìlú Èkó (Lagos), ní dédé ago mẹ́wàá ọ̀sàn-án; kò pẹ́ tí ó kúrò ní olú ilé tí ó wà ní Èkó. Ẹni tí ó fẹ́ paá tẹ̀le tí ó sì yín ìbọn fún ní ọ̀pọ̀ ìgbà tí ó fi ku.[4]
Ẹbí
àtúnṣeÓ fẹ́ arábìnrin Aderonke Falobi tí ó sì jẹ́ bàbá ọlọ́mọ mẹ́ta tí ṣe, Ayomide, Olamide, àti Aramide Falobi.[5]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "The Omololu Falobi Award". AVAC (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2014-02-18. Retrieved 2020-10-19.
- ↑ "On World AIDS Day, we remember our Brother OMOLOLU FALOBI". Nigeria Health Watch (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2014-12-02. Retrieved 2020-10-19.
- ↑ "Omololu Falobi, Nigerian Journalist/HIV-AIDS Activist, 1971-2006 | Internews". internews.org. Archived from the original on 2017-07-08. Retrieved 2020-10-19.
- ↑ "Killed: Omololu Falobi, JAAIDS Founder and Executive Director | Chicago Afrobeat Project | Carrying the Torch Since 2002". Chicago Afrobeat Project (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-10-19.
- ↑ "Pioneering AIDS Journalist Omololu Falobi Dies". POZ (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2006-10-09. Retrieved 2020-10-19.