Ọmọ́wùmí Dàda jẹ́ òṣèré ọmọ Nàìjíríà, tí ó gbajúmọ̀ jùlọ fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Folákẹ́ nínu eré tẹlifíṣọ̀nù ti M-Net kan, Jemeji. [1] Ó tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kópa nínu fíìmù èdè Yorùbá kan, Somewhere in the Dark ní ọdún 2017, èyítí ó gba àmì ẹ̀yẹ ti fíìmù abínibí tí ó dára jùlọ níbi ayẹyẹ AMVCA Awards ti ọdún 2017, [2] fíìmù náà sì ṣokùn fa yíyàn rẹ̀ fún ti amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ òṣèré tí ó dára jùlọ (ẹ̀ka ède Yorùbá) níbi ayẹyẹ Best of Nollywood Awards ní ọdún 2017 bákan náà.[3]

Omowumi Dada
Ọjọ́ìbí2 Oṣù Kẹ̀wá 1989 (1989-10-02) (ọmọ ọdún 35)
Ilu Eko, Ipinle Eko, Naijiria
Iléẹ̀kọ́ gígaUniversity of Lagos
Iṣẹ́Osere
Ìgbà iṣẹ́2013–iwoyi


Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀

àtúnṣe

A bí Dàda ní Ìpínlẹ́ Èkó, níbi tí ó ti lọ sí Ìfàkọ̀ International Nursery and Primary School fún ètò ẹ̀kọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀. Ní àkókò náà, ó darapọ̀ mọ́ Ẹ̀gbẹ́ Àṣà ilẹ̀ Yorùbá. Ó tẹ̀síwájú láti lọ sí Ilé-ìwé Command Day Secondary School, tó wà ní ìlu Oshòdì, fún ètò-ẹ̀kọ́ girama rẹ̀ sááju kí ó tó lọ kẹ́ẹ̀kọ́ Creative Arts ní ilé-ìwé gíga University of Lagos.[4]

Dáda bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òṣèrè rẹ̀ pẹ̀lú ṣíṣe àwọn ipa kékeré ní àwọn eré ìpele ní àkókò ìgbà tí ó wà ní Ilé-ẹ̀kọ́ gíga. Àkọ́kọ́ ipa gbòógì tí ó ṣe lóri ìpele wáyé nínu eré Moremi Ajasoro, èyítí Fẹ́mi Òké ṣe olùdarí rẹ̀.[4] Ní ọdún 2013, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ fíìmù rẹ̀ pẹ̀lú ipa kan nínu fíìmù Òyà pẹ̀lú àjọsepọ̀ òṣèré Túnjí Sotimirin, lẹ́hìn náà ló tẹ̀síwájú láti ṣe ìfihàn nínu àwọn fíìmù míràn tó fi mọ́ fíìmù tí Kúnlé Afoláyan darí, Omugwo ní àjosepọ̀ pẹ̀lú Patience Ozokwor àti Ayọ̀ Adésànyà.

Dàda ti ṣe ìfihàn nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré tẹlifíṣọ̀nù, tó fi mọ́ àwọn eré EbonylifeTv bi Married to the Game,[5] Best Friends àti Dere, eré tí n ṣe ìbádọ́gba “Cinderella“ ti Disney ní ilẹ̀ Áfíríkà.[6] Ó tún kópa nínu eré tẹlifíṣọ̀nù Mnet tí àkọ́lé r̀ jẹ́ Jemeji, ó sì ti ní àwọn ipa nínu Tinsel, So Wrong so Wright, Needles Eyes, Bella’s Place àti àwọn míràn.[5]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Onoshe, Nwabuikwu (11 March 2018). "The gift of Jemeji". Punch Newspaper (Lagos, Nigeria). https://punchng.com/the-gift-of-jemeji/. Retrieved 6 April 2019. 
  2. Ibrahim, Tanko (5 March 2017). "AMVCA 2017: See full list of winners". Punch Newspaper (Lagos, Nigeria). https://punchng.com/amvca-2017-see-full-list-of-winners/. Retrieved 6 April 2019. 
  3. Izuzu, Chibumga (7 September 2017). "Bolanle Ninalowo, IK Ogbonna, Rachel Okonkwo, Omowumi Dada, "What Lies Within" among nominees". Pulse Nigeria (Lagos, Nigeria). Archived from the original on 19 October 2021. https://web.archive.org/web/20211019113032/https://www.pulse.ng/entertainment/movies/bon-awards-2017-bolanle-ninalowo-ik-ogbonna-rachel-okonkwo-what-lies-within-among/x1yd04j. Retrieved 6 April 2019. 
  4. 4.0 4.1 Onoshe, Nwabuikwu (30 April 2017). "Some people think I’m a snob— Omowunmi Dada". Punch Newspaper (Lagos, Nigeria). https://punchng.com/some-people-think-im-a-snob-omowunmi-dada/. Retrieved 6 April 2019. 
  5. 5.0 5.1 Olofinjana, Sola (8 October 2018). "BEING AN ACTRESS IS MY CALLING – FAST RISING ACTRESS, OMOWUNMI DADA". City People Magazine (Lagos, Nigeria). http://www.citypeopleonline.com/being-an-actress-is-my-calling-fast-rising-actress-omowunmi-dada/. Retrieved 6 April 2019. 
  6. "EBONYLIFE TV CONCLUDES FILMING OF THE MOVIE ‘DERE’ IN CALABAR". Calabar News (Lagos, Nigeria). 8 October 2016. Archived from the original on 20 October 2021. https://web.archive.org/web/20211020043600/https://calabarblog.com/ebonylife-tv-concludes-filming-movie-dere-calabar/. Retrieved 6 April 2019.