Òmuò-Òkè-Èkìtì

(Àtúnjúwe láti Omuo-Oke-Ekiti)

Ìlú Òmùò-Òkè Èkìtì jẹ́ ìlú ńlá kan tí ó wà ní apá Ìlà oòrùn Èkìtì ni Òmùò òkè wà. Ìjọba ìbílẹ̀ ìlà Oòrùn ni ìpínlẹ̀ Èkìtì ni Òmùò-òkè tẹ̀dó sí. Òmùò-òkè tó kìlómítà méjìlélọ́gọ́ọ̀rin sí Adó-Èkìtì tí ó jé olú-ìlú ìpínlẹ̀ Èkìtì. Òmùò-òkè ni ìpínlẹ̀ Èkìtì parí sí kí a tó máa- lọ sí ìpìnlẹ̀ Kogi. Ìdí nìyí tí ó fi bá àwọn ìlú bí i, Yàgbà, Ìjùmú, Ìyàmoyè pààlà. Bákan náà ni ó tún bá Erítí Àkókó pààlà ní ìpínlẹ̀ Oǹdó. Ìwádìí fihàn wí pé àwọn ìlú bí Ejurín, Ìlíṣà, Ìṣàyà, Ìgbèṣí, Àhàn, Ìlúdọ̀fin, Orújú, Ìwòrò, Ìráfún ni ó parapọ̀ di Òmùò òkè, Ọláitan àti Ọládiípò (2002:3) Iṣẹ́ òòjọ́ wọn ni iṣẹ́ àgbẹ̀ àti òwò ṣíṣe. Ìdí ti wọn fi ń ṣe iṣẹ́ òwò ni wí pé, Òmùò òkè ni wọn ti máa ń kò ẹrù lọ sí òkè ọya. Ẹ̀ka èdè Òmùò-òkè yàtọ̀ sí Òmùò kọta Òmùò Ọbádóore. Òmùò Èkìtì jẹ́ àpapọ̀ ìlú mẹ́ta. [1] [2]

  1. Òmùò-òkè Èkìtì
  2. Òmùò kọta
  3. Òmùò Ọbádóore

Èdè Òmùò-òkè farapẹ́ èdè Kàbbà, Ìgbàgún àti Yàgbàgún ni ìpinlẹ̀ Kogi. O ṣe é ṣe kí èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí Òmùò-òkè ló bá ìpínlẹ̀ Kogí pààlà. Bákan náà ni àwọn ènìyàn Òmùò-òkè máa ń sọ olórí ẹ̀ka èdè Yorùbá àti èdè Gẹ̀ẹ́sì ni pàápàá àwọn tó mọ̀ọ̀kọ̀-mọ̀ọ́kà.

Ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ rẹ̀

àtúnṣe

Ìtàn àgbọ́sọ ni ó rọ̀ mọ́ ìtàn ìsẹ̀dálẹ̀ ìlú Òmùò-òkè gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rí ni àwọn ilẹ̀ Yorùbá káàkiri. Ilé-Ifẹ̀ ni orírun gbogbo ilẹ̀ Yorùbá bẹ́ẹ̀ ló ṣe rí ní Òmùò-òkè. [3] Olúmoyà pinnu láti sá kúró ni Ifẹ̀ nítorí kò faramọ́ ìyà ti wọn fi ń jẹ́ ẹ́ ni Ifẹ̀. Kí ó tó kúró ni Ilé-Ifẹ̀, ó lọ ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ Ifá. Àyẹ̀wò tí ó lọ ṣe yìí fihàn wí pé yóò rí àwọn àmì mẹ́ta pàtàkì kan ni ibi ti ó máa tẹ̀dó sí. Ibi tí ó ti rí àwọn àmì mẹ́ta yìí ni kí ó tẹ̀dó síbẹ̀. Àwọn àmì àmì mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà ni

  • ibi tí erin fi ẹsẹ̀ tẹ̀
  • igbó ńlá
  • Odò

Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti rìn títítí ni ó wà dé ibi ti ifá ti sọ tẹ́lẹ̀ fún un. Nígbà ti ó rí odò, ó kígba pé “Omi o” ibi ni orúkọ ìlú náà “Òmùwò” ti jáde. Òmùwò yìí ni ó di Òmùò-òkè títí di òní. Olúmoyà rìn síwájú díẹ̀ kúró níbí odó yìí pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀. Ó dé ibìkan, ibi yìí ni òun àti àwọn tí ó ń tẹ̀le kọ́ ilé si. Ibi ti ó kọ́ ilé sí yìí ni ó pè ni “Ìlẹ́mọ” Orúkọ ilé yìí “Ìlẹ́mọ” wà ni Òmùò òkè títí di òní. Olúmoyà gbọ́rọ̀ sí ifá lẹ́nu, ó sọ odò náà ni “Odò-Igbó” àti ibi ti ó ti rí ẹsẹ̀ erin ni “Erínjó”. Akíkanjú àti alágbára ọkùnrin ni Olúmoyà ó kó àwọn ènìyàn rẹ̀ jọ. ó kọ ilẹ òrìṣà kan tí ó pè orúkọ òrìṣà yìí ni “Ipara ẹ̀rà”. Ibi yìí ni wọn ti máa ń jáwé oyè lé ọba ìlú náà. Báyìí ni Olúmoyà di olómùwò àkọ́kọ́ ti ìlú Òmùwò tí a mọ̀ sí Òmùò-òkè ní òní.[4]


Àwọn Itọ́kasí

àtúnṣe

Ìtàn yí ò kì ńṣe ìtàn ìlú Omuo òkè ní ẹkùn rẹ rẹ. Ìlú Omuo òkè ni o jẹ ìlú kan tí wọn lé kúrò ní orí ilé tiwọn tẹ̀dó sì ni agbegbe iyagba ni Ìpínlẹ̀ Kogi. Lílé tí wọn le wọn yí ni ó ṣokùnfà bí wọn ṣe wá si'lu Omuo Ekiti nígbà náà. Èyí lomu ki wọn tán ọba tí ó wà lórí ìtẹ́ nígbà náà àti àwọn ìjòyè Omuo Ekiti. Bayi ni àwọn ìgbìmò wọ̀nyí fún àwọn ará ìyá yí ni ilẹ̀ tí o kọ́ gun sí ìlú ilamoye ni ìpínlè Kogi (ibiyi ni Omuo npeni igun {Edge}). Olomuo igbana ni o sọ fún wọn pé Omuo Oke níwọ̀n ó máa jẹ. SÍHÀBÀ ni orúkọ oyè tí Olomuo ìgbàanì fún ẹni tí yio dúró gẹ́gẹ́ bíi olórí fún wọn. Àdúgbò (Quarters) ni Omuo Oke je n'ilu Omuo. Àwọn Àdúgbo tí ó wà n'ilu Omuo Ekiti ni; Ilisa, Iworo, Ijero, Ahan, Edugbe, Ekurugbe, Omodowa, Ehuta, Ìloro, Oruju, Oya, Kota, Oda odò, Araromi, Ahan Ayegunle, Òmùò-òkè.

  1. "Omuo Oke Map". Nigeria Google Satellite Maps. Retrieved 2021-01-12. 
  2. "Strange tales from Ekiti". The Sun Nigeria. 2016-12-08. Retrieved 2021-01-12. 
  3. Ojomoyela, Rotimi (2017-01-05). "Omu-Ekiti: A Community replete with strange tales and mysteries". Vanguard News. Retrieved 2021-01-12.