Onchocerciasis
Onchocerciasis, tí a tún mọ̀sí jìgá àti àrùn Robles, jẹ́ ààrùn tí àkóràn ṣòkunfà pẹ̀lú àràn àfòmọ́ Onchocerca volvulus.[1] Lára àwọn ààmì ni ìhún-ara gan an, àwọn wíwú inú àwọ̀ ara, àti àìríran.[1] Òhun ni òkunfà kejì àìríran tí ó wọ́pọ̀ ti àkóràn fà, lẹhin trachoma.[2]
Onchocerciasis | |
---|---|
An adult black fly with the parasite Onchocerca volvulus coming out of the insect's antenna, magnified 100x | |
Ìpínsọ́wọ̀ àti àwọn òkunfà ìta | |
ICD/CIM-10 | B73. B73. |
ICD/CIM-9 | 125.3 125.3 |
DiseasesDB | 9218 |
Àràn àfòmọ́ ń tàn káàkíri nípa àwọn ìgéjẹ ti eṣinṣin dúdú ti irúfẹ́ Simuliumu.[1] Lọ́pọ̀ ìgbà ni ọ̀pọ̀ ìgéjẹ gbọ́dọ̀ wáyé ṣáájú kí àkóràn tó wáyé.[3] Àwọn eṣinṣin yíì ń gbé lẹ̀bá àwọn odò èyí tí ó ṣòkunfà orúkọ àrùn náà.[2] Nígbà tí o bá tìwà nínu ènìyàn, àwọn àràn náà ń ṣẹ̀dá ìdin tí o ń jáde nínu àwọ ara.[1] Níb́i ni wọn tì le ṣàkóràn fún eṣinṣin dúdú míìràn tí yóò gé ènìyàn jẹ.[1] Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni a ń ṣàwarí mímọ̀ àrùn náà èyí tí ó wà lára: ṣíṣe ìṣàyẹ̀wò omi ara ti àwọ̀ ara si omi iyọ̀ ara bí ó ti yẹ àti wíwò kí ìdin náà ó jáde, wíwo ojú fún ìdin náà, àti wíwo inú aẁọn ara wíwú lábẹ́ àwọ̀ ara fún àwọn àràn ńlá.[4]
àjẹ̀sára lodì sí àrùn náà kòsí.[1] Ìdẹ́kun ni nípa ìyẹra fún gígéje àwọn eṣinṣin.[5] Èyí lèjẹ lára lílo ogùn lílé kòkòrò àti ìwọṣọ dáradára.[5] Àwọn ìlépa míìràn ni láti dín iye àwọn eṣinṣin kù nípa fífí wọn ogùn apa kokorò.[1] Àwọn ipa láti ṣàmúkúrò aarùn yíì nípa ìtọjú àwọn ọ̀wọ́ ènìyàn lẹ́ẹ̀mejì lọ́dún ni o ńlọ lọ́wọ́ ní ọ̀pọ̀ agbegbè ní àgbayé.[1] Ìtọjú àwọn tí ó ní àkóràn nípa egbòògi náà ivermectin ní gbogbo oṣù mẹ́fà-mẹ́fà sí méjìlá.[1][6] Ìtọjú yíì maa ńpa ìdin ṣùgbọ́n kòle pa àwọn ìdin tí ó ti dàgbà.[7] Ìtọjú náà doxycycline, tí o maa ńpa ẹgbẹ́ ńpè ní bakiteríà Wolbachia, jọ èyí tí o lè gba agbára lọ́wọ àwọn aràn náà, àwọn kan sì gbaniníyànjú pẹ̀lú .[7] Ìyọkúrò àwọn wíwú inú ara lábẹ àwọ̀ ara nípa iṣẹ́ abẹ ni a tún lèṣe.[6]
Bíi 17 sí 25 mílíọ́nù àwọn ènìyàn ni o ní àkóràn jìgá, pẹ̀lú ìdá bíi 0.8 mílíọ́nù tí wọn ní ìpàdánù ìríran.[3][7] Ọ̀pọ̀ àwọn àkóràn ń wáyé ní ìwọ̀ gúùsù Afíríkà, bí o tìlẹ̀ jẹ́pé àti ṣàwarí àwọn ìṣẹlẹ̀ kan ní Yemen àti ní àwọn agbegbè ìyàsọtọ̀ Aarin àti Gúúsù Amẹríkà.[1] Ní 1915,oluwosàn Rodolfo Robles ni ó kọ́kọ́ so arùn ojú mọ́ aràn.[8] Tí a ṣàkọsílẹ̀ lọ́wọ Àjọ Ìlera Àgbayé gẹ́gẹ́bí àrùn tí a gbàgbé ti ipa ọ̀nà oorùn.[9]
Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.00 1.01 1.02 1.03 1.04 1.05 1.06 1.07 1.08 1.09 "Onchocerciasis Fact sheet N°374". World Health Oragnization. March 2014. Retrieved 20 March 2014.
- ↑ 2.0 2.1 "Onchocerciasis (also known as River Blindness)". Parasites. CDC. May 21, 2013. Retrieved 20 March 2014.
- ↑ 3.0 3.1 "Parasites – Onchocerciasis (also known as River Blindness) Epidemiology & Risk Factors". CDC. May 21, 2013. Retrieved 20 March 2014.
- ↑ "Onchocerciasis (also known as River Blindness) Diagnosis". Parasites. CDC. May 21, 2013. Retrieved 20 March 2014.
- ↑ 5.0 5.1 "Onchocerciasis (also known as River Blindness) Prevention & Control". Parasites. CDC. May 21, 2013. Retrieved 20 March 2014.
- ↑ 6.0 6.1 Murray, Patrick (2013). Medical microbiology (7th ed.). Philadelphia: Elsevier Saunders. p. 792. ISBN 9780323086929. http://books.google.ca/books?id=RBEVsFmR2yQC&pg=PA792.
- ↑ 7.0 7.1 7.2 Brunette, Gary W. (2011). CDC Health Information for International Travel 2012 : The Yellow Book. Oxford University Press. p. 258. ISBN 9780199830367. http://books.google.ca/books?id=5vCQpr1WTS8C&pg=PA258.
- ↑ Lok, James B.; Walker, Edward D.; Scoles, Glen A. (2004). "9. Filariasis". Medical entomology (Revised ed.). Dordrecht: Kluwer Academic. p. 301. ISBN 9781402017940. http://books.google.ca/books?id=C7OxOqTKYS8C&pg=PA301.
- ↑ Reddy M, Gill SS, Kalkar SR, Wu W, Anderson PJ, Rochon PA (October 2007). "Oral drug therapy for multiple neglected tropical diseases: a systematic review". JAMA 298 (16): 1911–24. doi:10.1001/jama.298.16.1911. PMID 17954542. http://jama.jamanetwork.com/article.aspx?doi=10.1001/jama.298.16.1911.