Orílẹ̀-èdè Yorùbá

ÀKÀNDÉ SAHEED ADÉBÍSÍ

ORÍLẸ̀-ÈDÈ YORÙBÁ

Yorùbá gẹ́gẹ́ bí Orílẹ̀-Èdè jẹ́ àti-ìran-díran Odùduà pẹ̀lú gbogbo àwọn tí wọn ń sin Ọlọrun ni ọ̀nà ti Odùduà ń gbà sìn-ín; ti wọn si bá a jade kúrò ni agbedegbede ìwọ̀ oòrùn nígbà tí ìrúkèrúdò dé nipa ìgbàgbọ́ rẹ̀ yìí. Akikanjú yii pinnu láti lọ tẹ orílẹ̀ èdè miran dó nibi tí wọn yóò gbé ni àǹfàní ati sin Ọlọrun ni ọ̀nà ti wọn gbà pé ó tọ́ ti ó si yẹ. Bí wọn ti ń rìn káàkiri ni Yorùbá, bí Orìlẹ̀-Èdè n gbòòrò síi, ti ó si fi jẹ́ pé l’onii gbogbo àwọn ènìyàn tí wọn ń bá ni gbogbo ibi tí wọn ti ń jagun tí ó di ti wọn àti ibi tí wọn gbé ṣe àtìpó, tí wọn si gbé gba àṣà, ati ìṣe wọn, titi ti ọkunrin Akíkanjú, Akọni, Olùfọkànsìn, Olóógun, Àkàndá ẹ̀dá, yii fi fi Ile-Ifẹ ṣe ibùjókòó ati àmù Yorùbá. Ile-Ifẹ yii si ni àwọn Yorùbá ti fọ́nká kiri si ibi ti wọn gbé wà l’onii ti à ń pè ni ‘Ilẹ̀ K’áàrọ̀, O jí i re’.

L’ónìí, kì í ṣe ibi tí a pè ni ‘Ìlẹ̀ k’áàrọ̀, O jí i ré’ yii nìkan ni àwọn Yorùbá wà gẹ́gẹ́ bi ẹ̀yà kan. Wọn fọ́n yíká Ilẹ ènìyàn dudu ni, àti àwọn orílẹ̀-èdè mìíran l’ábẹ́run ayé.

Eyi ni ibi ti àwọn ẹ̀yà ti à ń pè ni Yorùbá wà l’onii:

1. ORÍLẸ̀-ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ: Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ògún, Èkó, Oǹdó, Kwara, Èkìtì ati Ọṣun. A sì tún ń ri àwọn Yorùbá diẹdiẹ ni àwọn ìpínlẹ̀ wọnyi:

(i) Ìpínlẹ̀ Kano: Àwọn ẹ̀yà Yorùbá ti ó wà nibi ni àwọn tí à ń pè ní ‘Báwá Yorúbáwá ati Gogobiri:

(ii) Sokoto: Àwọn ìbátan wọn tí ó wà nibi ni à ń pè ni Beriberi. Gẹ́gẹ́ bi òwe ti ó wí pé ‘Oju ni a ti ń mọ dídùn ọbẹ̀. Ilà oju àwọn ẹ̀yà yii fi ìdí ọrọ yii múlẹ̀.

(iii) Ìpínlẹ̀ Ilẹ̀ Ìbínní dé etí Odò Ọya: Awọn wọnyi ni àwọn ìlú tí ọmọ Eweka gbé ṣe àtìpó ati ibi tí wọn jẹ oyè sí, àwọn bíi Onìṣà Ugbó, Onìṣà Ọlọ́nà àti Onìṣà Gidi (Onitsha), pàápàá jùlọ àwọn tí wọn ń jẹ oyè tí à ń pè ni Òbí. Àwọn kan sì tún ni ìran Ègùn bíi:

Ègùn Ànùmí ni ilẹ Tápà; Ègùn Àwórí ni Ẹ̀gbádò; Ègùn Àgbádárígì ní Ìpínlẹ̀ Èkó.

2. ORÍLẸ́ ÈDÈ BENIN, TOGO, GANA ATI SÀRÓ

Awọn ni Ègùn ilẹ Kutonu, Ègùn Ìbàrìbá ilẹ Benin; Aina, Aigbe àti Gaa ni ilẹ Togo ati Gana; àti àwọn Kiriyó (Creoles) ilẹ Sàró (Sierra Leone).

3. ORÍLẸ̀ ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Àwọn orílẹ̀ èdè tí ó wà l’áàrin Amẹ́ríkà ti àríwá àti ti gúúsù (Cuba, Trinidad and Tobago, Jamaica and other Caribbean islands); ati àwọn Ìpínlẹ̀ òkè l’ápá ìlà-oòrùn ti Amẹ́ríkà ti Gúúsù: (Brazil, etc).

Bí ó tilẹ jẹ́ pé àwọn ọmọ Odùduà tàn kálẹ̀ bíi èèrùn l’ode oni, ẹ̀rí wa pé orílẹ̀ èdè kan ni wọ́n, ati pé èdè kan náà ni wọn ń sọ nibikibi tí wọn lè wà. Ahọ́n wọn lè lọ́ tàbí kí ó yí pada nínú ìsọ̀rọ̀ síi wọn, ṣùgbọ́n ìṣesí, ìhùwà, àṣà àti ẹ̀sìn wọn kò yàtọ̀; gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa sì ti máa ń pa á l’ówe, a mọ̀ a sì gbà pé; Bi ẹrú ba jọ ẹrú, ilé kan náà ni wọn ti wá’. Awọn idi pàtàkì ti ahọ́n àwọn ọmọ Yorùbá fi yí pada díẹ̀ díẹ̀ díẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èdè Yorùbá kan náà ni wọn ń sọ niyi:

(a) Bí àwọn akọni ti ń jade kúrò ni Ilé-Ifẹ̀ láì pada bọ̀ wá sile mọ́, ni wọn ń gbàgbé díẹ̀ nínú èdè ìbínibí wọn.

(b) Ibikibi ti àwọn akọni yii bá sì ṣe àtìpó sí tàbí tẹ̀dó sí ni wọn ti ń ba ènìyàn. Otitọ ni wọn gba orí l’ọ́wọ́ àwọn ti wọn ń bá ti wọn sì ń di ‘Akẹ́hìndé gba ẹ̀gbọ́n’, ṣugbọ́n bi wọn bá ti ń di onile ni ibi ti wọn tẹ̀dó, tàbí ti wọn ṣe àtìpó si yii, ni wọn mú díẹ̀-díẹ̀ lò nínú èdè, àti àṣà wọn nitori pe bi ewé bá pẹ́ lára ọṣẹ bi kò tilẹ di ọṣẹ yoo dà bí ọṣẹ; àti pé ti ó bá pẹ́ ti Ìjẹ̀ṣà bá ti jẹ iyán, kì í mọ òkèlè ẹ̀ bù mọ́; òkèlè ti ó yẹ kí ó máa bù nlanla yoo di ródóródó. Eyí ni ó sì ń fa ìyàtọ̀ díẹ̀-díẹ̀ nínú ìṣesí àwọn Yorùbá nibikibi ti wọn bá wà l’ónìí.

(d) Bi àwọn ọmọ Yorùbá ti ṣe ń rìn jinna sí, sí Ile-Ifẹ ni ahọ́n àwọn ẹ̀yà náà ṣe ń yàtọ̀. Awọn tó gba ọna òkun lọ ń fọ èdè Yorùbá ti ó lami, ti a sì ń dàpè ni ÀNÀGÓ, àwọn ti wọn sì gba ọna igbó àti ọ̀dàn lọ ń sọ ogidi Yorùbá, irú wọn ni a sì ń pè ni ará òkè.

Pàtàkì nínú àwọn ẹ̀yà Yorùbá ti ó kúrò ni Ile-Ifẹ ti ó sì gba apá òkè lọ nínú igbó ati ọ̀dàn niyi:

Ọ̀yọ̀; Ìjẹ̀ṣà; Àkókó; Èkìtì; Ọ̀wọ̀; Oǹdó; Ìgbómìnà; Ọ̀fà; Ìlọrin; àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn ti o si gba ẹsẹ̀ odò lọ ni Ẹ̀gbá; Ẹ̀gbádò; Ìjẹ̀bú; Ìlàjẹ; Ikalẹ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.