Orúkọ Àbíkú
Orúkọ àbíkú ni àwọn orúkọ tí wọ́n máa ń sọ àwọn ọmọ àbíkú.[1] Láyé àtijọ́ àwọn baba wa gbà pé àbíkú ọmọ wà. Irú àwọn ọmọ báwọ̀nyí ni wọ́n ń pè "lólówó ọmọ" tàbí "apààrà", èyí ni, alálọbọ̀ tàbí ayọ́runbọ̀. Wọ́n sì gbà pé bí obìnrin bá ṣe àgbákò irú àwọn ọmọ yìí, bí ó ti ń bí i ni yóò máa kú títí tí àwọn òbí ọmọ náà yóò fi rí ojú rere Ọlọ́run tàbí tí wọ́n yóò fi le fi òògùn de ọmọ náà mọ́lẹ̀
Ẹni tí ó bá sì rántí pé àwọn bàbà-ńlá wa gbà pé àkúnlẹ̀yàn ni àdáyébá kò le dá wọn lẹ́bi púpọ̀ pé wón gbà pé àbíkú ọmọ ń bẹ. Bí àbíkú ọmọ bá kú, àwọn Yorùbá kìí sin wọ́n sínú ilé, inú ìgbẹ́ ni wọn sin wọ́n sí; nígbà mìíràn bí àbíkú yìí bá ti da òbí rẹ̀ láàmú púpọ̀, wọn kì í tilẹ̀ sin irú ọmọ bẹ́ẹ̀, wọn á gbé e sọnù sínú igbó ni. Yorùbá sì gbà pé bí a bá ṣe ọmọ náà níkà lẹ́yìn tí ó bá kú tán, bí ó bá tún wálé ayé kì yóò kú mọ́; nítorí ìdí èyí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ a máa wmrọ́ wọn lápá àti lẹ́sẹ̀ kí wọn ó tó sin wọ́n.
Àwọn mìíràn a sì máa gbé wọn sọnù sínú igbó ní ìrètí pé bí a bá le fi ìyà jẹ òkú wọn báyìí, bí wọn bá tún ayé wá, wọn yóò dójú ti ikú. Àwọn òbí mìíràn sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú òògùn èyí tí wọ́n ń dàpè ní "gbékúdè", èyí le jẹ́ ońdè tàbí ìfúnpá tàbí ìkóbẹ̀rẹ́ tàbí gbẹ́rẹ́, abbl. Bí àwọn mìíràn bá sì bí àbíkú, wọn a máa ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ babaláwo tàbí alágbigba tàbí ọlọ́sanhìn láti mọ ohun èèwọ̀ ọmọ yìí tí kò fi ní kú. Láti ìdí àyẹ̀wò báyìí ni ati ń fún ọmọ ní orúkọ bíi "Kèésunko". Èèwọ̀ ti ọmọ mìíràn le jẹ́ pé wọ́n kò gbọ́dọ̀ gbé e wọ ilé baba iya rẹ̀ tí yóò fi le rìn wọ inú ilé náà fún ara rẹ̀.
Díẹ̀ nínú àwọn orúkọ àbíkú
àtúnṣe- Ańdù - Ańdùlọ́wọ́; À ń du ọmọ yìí lọ́wọ́.
- Dójó - Arádojo; ara òbí tàbí ọmọ ti d'ojo.
- Àńwóókọ - À ń wá orúkọ
- Mamóóràá - Màá mú owó òbí rà á
- Apààrà - Alálọbọ̀ ọmọ
- Àńwòó - À ń wo ọmọ yìí lójú
- Ámọnúrẹ̀ - A kò mọ inú ọmọ yìí
- Táájó - Ọmọ tó aájò fún
- Kúkọ̀yí - ikú kọ èyí
- Abíiná - A bí èyí ná ọmọ
- Máko - Má kó mi lẹ́rù lọ
- Lúkúlà - Ẹni tí ó kú là
Kòwárí - Kò wá ilẹ̀ yìí rí
- Dúrójayé - Dúró kí o jayé
- Adékọ̀gbẹ́ - Adé kọ ìgbẹ́
- Làḿbẹ̀ - Ọlọ́run là ń bẹ̀ sí ọmọ yìí
- Ajídáhùn - Ó jí, ó sì dáhùn
- Orúkọtàn - Kò sí orúkọ nílẹ̀ mọ́
- Kòsọ́kọ́ - Kò sí ọkọ́ tí a ó fi sin òkú ọmọ
- Ìgbẹ́kọ̀yí - Ìgbẹ́ ti kọ ọmọ yìí
- Dúrósinmí - Dúró láyé kí o sin mí
- Kòtóyẹ́ - Ọmọ yìí ò tó yẹ́ sí
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Abiku Names". Ethnic name search engine. 2009-07-22. Retrieved 2024-07-19.