Orúkọ Àdúgbò ní Ègbá àti Àwórì, Ìpínlẹ̀ Ògùn, Nàìjíríà

Egba

Awori

Egba ati Awori

ÈGBÁ ÀTI ÀWÓRÌ

àtúnṣe
1.	Ìta oseìn: 	ibi tí àwon ajagun tí màa ń bo soìnmolè tí wón bá fé lò jagun, ni ìgbákìgbá tí wón bá ti boo shin náà wòn maá n sègun. 

2. Pansekè: igi kan ni tí ó ní èso, tì éso náà bá ti gbe yóò máa dun sékéséké, ibi tí igi na ise ni aso

3. Onikólóbo: àdúgbò ti won tí lo kolobo láti gba owó okò ní ayé àtijó

4. Aké: àdúgbò orí rún ègbá, ààfin gbogbo ègbá.

5. Imó: agbolé, tí won tí amò tí ó dára jù légbà

6. Àjítàádùn: isé àádùn síse ni emit í ó kókó te àdúgbò náà dó ń se.

7. Arule olónì: ní ayé àtijó èni kan wà tí won máa ń sìn ní abúlé yìí

8. Ìta Èko: Àdúgbò tí wón tí ń ta èko, ní ìgbà náà ibè nìkan ni wón ti ń ta èko.

9. Ìjàyè: Ibi tí àwon ará ìbàdàn tèdó sí ní ìgbà tí won ja ogun àjàyè

10. Àgó òwu: Àdúgbò tí ajagun tà kan ní ìlú ìbàdàn tí ó jé akódé tèdó sí.

11. Sàpón: Ní ayé àtijó ìyá a kan wà tí ó jé wípé èwà ní ó máa ń tà èyì sì se ànfàń púpò fún àwon àpón tí kòì tí láya, ní ìgbà kígbà tí ó wun àwon àpón yìó ní wón máa ń lo ra èwà tí ó sì jé pé wón á rí ìyá eléwà yìí níbè ìdí éléyìí ni a se ń pè ìyá eléwà yìí ní sàpón lóore.

12. Adédòtun: Orúko bale tí ó kókó tèdó sí Àdúgbò yen ní wón fi ń pèé.

13. Ìdí Àrà: Igi ńlá kan wàn ní àdúgbò yìí ní ayé àti jó tí ó jé wípé ìgbà túgbà tí àwon àgbè bá ń ti oko bò wón máa ń simi sí abé igi náà nítorí pé ibojì àti atégùn wà ní abé igi náà.

14. Ìjógun: Àdúgbò tí àwon àwórì tí ńjagun ní ayé àti jo ìdí ògún ni wón pè ní ìdógun

15. Ìmòré: Ní ayé àtijo igi kan wà tí ó ń so èso kan tí à ń pè ni òré, igi yìí pò ní àdúgbò yìí tí ó fi jé pé nígbà tí wón tèdó sí bè ni wón soódi imòòré.

16. Ìrobè: Àdúgbò tí awon aborè tí máa ń fi ènìyàn bore, ìdí èyí ni wón fi ń pèé ní ìborè.

17. Ojà Àgbó: Agboolé yìí jé ibi tí àwon tí ó kòkòtèdó síbè tí ń sé isé òsìn eran, wón dó ojà sílè tí won ti ńta àgbò, ní torú ìdí èyí ni wón se so ibè ní òjà àgbò.

18. Ìlú Gùn: Àdúgbò yìí jé àdúgbò tí ó gùn jù ní gbogbo ègbá.

19. Ìjejà: Ní ìgbà kan Oba kan náà ní àdúgbò yìí tí o burú tí ó sì jé wí pé àsé tí ó bá pa ní abé gé. Ó so fún àwon ará ìlú rè ní ojó kan wí pé tí won bá náa ojà sùgbón wok o, Oba pàsè kí wón lo je ojà náà run.

20. Láfénwá: Orúko eni tí ó kókó àdúgbò yìí ni oláféniwá ìdí èyí ni wón fi so àdúgbò yìí ni orúko eni tí ó kókó tebè dó.

21. Mókóla: Ní ayé ojo un ní ìgbà tí àwon ajagunlà ti ń jagun, wón jagun wón kérú wón kérù, ibi tí wón dé simi tí wón kó àwon erù won sí ni wón sinmi sí ibè tí wón pè ní omokólá.

22. Asérò: Abúlé yìí ni àwon kan kókó tèdó sí tí ogun fí léewá, nígbà tí wón dé ibè, bí tí n sì bò ní ibi tí wón lo gégé bí àwon èrò se pò tó ní wón ti sì dé ibi tí wón tèdó sí, ibi tí wón sit i sí kúrò ní wón ń pè ní Asérò

23. Ìgbésa: Àdúgbò yìí jé ibi kan tí ó jé pé igbó ni ó pò níbè télè sùgbón ìgbà tí àwon ènìyàn tèdó síbè ní ó di ìlú èyí ni wón se ń pè ní igbésà.

24. Ìkujà: Jé abúlé kan tí akínkanjú kan ti kòyá fún àwon ará abúlé lówó àwon adigun jalè Akinkanjú yìí máa ń jà, ìdí èyí ni wón fi ń pè é ní ìkijà.

25. Kútò: Ikútòmíwá ni àpè sale orúko yìí ní ìgbà kan okùnrin kan wà ní abúlé kan tí ó jé ohun nìkàn ni ó ń gbé ibè, ní ojó tí eranko búburu kan wá bá ní ibi tí ó ń gbé ni eran kò náà paá je kí ó tó kú ni ó ké tí enìkan fi gbó ohùn rè tí ó si sàlà yé fún ìdí èyí ni wón fi so abúlé ní kútò.

26. Olósun: Ení tí ó ti bè dó jé abo òsun tí wón sì ń pèé ni eni tí ó òsun tí ó di Olósun báyìí.

27. Ológùn-ún: Ìse Òde ni eni tí ó kókó dé bè n se tí ó sì máa ń bo ògún nígbà tí ó bá ti oko ode dé tí owó si de tí wón sì ń pèé ní ilé eni tí ó ń bo ògún, tí won ń dàpè ni ilé Ológùn-ún báyìí.

28. Ìbèrè kòdó: Okùnrin tí won fi ń be àpèjúwe ibí yìí kò dó sí ilé yìí, eni tí ó jé àbúrò rè ni ó wá padà dó sí ilè yìí. Béèrè ni won máa ń pe ègbón ni tiwon gégé bí ó se wà ní àwon ìlú tàbí agbègbè kòòkàn lode òní, tí okùnrin náà sì máa ń so fún òpòlopò ènìyàn pe ibí yìí ló ye kí béérè òun dó sí, sùgbón tí kò dó síbè, òun yóò wá máa pe ibí yìí ni “ìbi tí béérè kò dó sí” tí won ń dà pè ní Ìbèrèkòdó báyìí.

29. Ìgbórè: Bàbá kan àti ìyàwó rè ni wón ń rìn kiri tí wón fid é ibi tí àdúgbò yìí wa báyìí, wón gbé erèé lówó wón sì gbo ó ni ibè wón sì fi din àkàrà je, Báyìí ni wón ń se àpèjúwe ibe ni “Ibi tí àwon ti gbo erèé” tí o di Ìgbórè báyìí

30. Ìbàsà: Ibí yìí jé ibì kan tí wón tí ń bo àwon àsà ilè Yorùbá ní ayé ìgbà náà, wón sì so ibè ní ilé “ibo àsà tí ó di Ibasa lónìí.