Orin-ìyìn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Lédè Yorùbá

Ẹ dìde, ẹ̀yin ara
Orin-ìyìn National Nàìjíríà Nàìjíríà
Ọ̀rọ̀ orinJohn A. Ilechukwu, Eme Etim Akpan, B. A. Ogunnaike, Sota Omoigui and P. O. Aderibigbe, 1978
OrinÀwọn Ọ̀lọ́pàá Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lábẹ́ àkóso B. E. Odiasse, 1990
LílòỌdún 1978
Ìtọ́wò orin
noicon
noicon

Ìṣẹ̀dálẹ̀ rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n gba orin-ìyìn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Arise O Compatriots" tí ìtumọ̀ lédè Yorùbá jẹ́ "Ẹ dìde Ẹ̀yin Ará" wọlé gẹ́gẹ́ bí orin-ìyìn orílẹ̀ èdè náà lọ́dún 1978, tí wọ́n sìn fi í rọ́pò orin ìyìn àtijọ́ tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Nigeria, We Hail Thee", tí ìtumò rẹ̀ lédè Yorùbá jẹ́ "Nàìjíríà, Ayìn Ọ́" It was adopted in 1978 and replaced the previous national anthem, "Nigeria, We Hail Thee".[1]

Ohùn orin-ìyìn jẹ́ àpapọ̀ ọ̀rọ̀ àti awẹ́-gbólóhùn tí wọ́n pò pọ́ láti márùn-ún àwọn orin ìyìn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí wọ́n fi díje àpapọ̀ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ẹgbẹ́ akọrin àwọn Ọ̀lọ́pàá lábẹ́ ìṣàkóso Benedict E. Odiase ni wọ́n pawọ́n pọ̀ tí wọ́n sọ ọ́ di Orin-ìyìn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí à ń kọ́ báyìí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé abala méjì ni Orin-ìyìn yìí wà, abala àkọ́kọ́ ni wọ́n sáàbà máa ń kọ, ṣùgbọ́n nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀, wọ́n máa ń kọ abala kejì gẹ́gẹ́ bí "Orin Ìwúre fún Nàìjíríà" ní àwọn ayẹyẹ mìíràn.[2] [3]

Orin-ìyìn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Lédè Yorùbá, Abala Àkọ́kọ́

àtúnṣe
Dìde ẹ̀yin ara
Wá jẹ́ ìpè Nàìjíríà
Ká fìfẹ́ sin ilẹ̀ wa
Pẹ̀l'ókun àti ìgbàgbọ́
Kí iṣẹ́ àwọn Akoni wa,
kó má ṣe já sásán
Ká sìn ín tọkàn tara
Ìlẹ̀ tómìnira, àtàlàáfíà
Sọ dọ̀kan

Orin-ìyìn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Lédè Yorùbá Abala Ìkejì

àtúnṣe
Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá
Tọ́ ipa ọ̀nà wa
Fọnà han aṣáájú
Kọ́dọ̀ Ọ́ wa mòtítọ́
Kódodo àtìfẹ́ pọ̀ sí i
Káyé won jẹ́ pípé
Sọ wọ́n dẹni gíga
Kálàáfíà òun ẹ̀tọ́ lè
Jọba nílẹ̀ wá.

Àkálẹ̀ Orin-ìyìn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà Lédè Gẹ̀ẹ́sì

àtúnṣe

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Nigeria’s National Anthem Composer, Pa Ben Odiase, Dies". Gazelle News. 2013-06-12. Archived from the original on 2017-09-27. https://web.archive.org/web/20170927112428/http://www.thegazellenews.com/2013/06/12/nigerias-national-anthem-composer-pa-ben-odiase-dies/. Retrieved 2013-07-08. 
  2. "Nigerian National Anthem". Nigeria High Commission. 2020-02-08. Archived from the original on 2020-02-03. Retrieved 2020-02-08. 
  3. "National Anthem of Nigeria (Lyrics, History)". 2020 World Population by Country. 2019-08-28. Archived from the original on 2020-02-17. Retrieved 2020-02-08.