Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn pe ẹ̀yà àti èdè ló wà ní Áfríkà, oríṣiríṣi ẹ̀yà orin ni wọ́n ń kọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀yà àti orílẹ̀-èdè sì ní àṣà orin. Díè nínú àwọn orin ní Áfríkà ni amapiano, Jùjú, Fuji, Afrobeat, Highlife, Makossa, Kizomba, àti àwọn orin míràn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èlò orin sì ni wọ́n ń lọ̀ ní Áfríkà. Àwọn àṣà orin kọ̀kan ní Latin American bi cumbia, salsa music, son cubano, rumba, conga, bomba, samba àti zouk jẹ́ àṣà tí àwọn ọmọ Áfríkà tí wọ́n kó lẹ́rú dá kalẹ̀.[1]

Ara ǹkan tí ó tún mú orin Áfríkà yàtò ni ìpè àti ìdáhùn tí ó ma ń wà nínú orin wọn: ènìyàn tàbí ohun èlò kan ma kọrin, àwọn tó kù sì ma gbe tẹ̀lé. Ọ̀pọ̀lopọ̀ àwọn orin Áfríkà jẹ́ orin àtenudẹ́nu láti ìran kan sí òmíràn.

Orin jẹ́ nkan tí ó ṣe pàtàkì sí àwọn ẹ̀sìn ní Nàìjíríà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀sìn ma ń fi orin pìtàn láti ìran kan sí òmíràn, wọ́n sì ma ń jó sí orin tí wọ́n ń kọ.

Àwọn Ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. "Definitions of Styles and Genres: Traditional and Contemporary African Music". CBMR. Columbia University. Retrieved 3 March 2016.