Chad jẹ́ orílẹ̀ èdè Àrin Áfríkà tí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀yà. Àwọn oríṣiríṣi agbègbè ní orílẹ̀ èdè sì ló ní ọ̀nà ijó àti orin wọn. Àwọn ẹ̀yà Fulani, fún àpẹẹrẹ, ma ń lo fèrè, àwọn griot sì ma ń lo kinde olókùn márùn-ún àti oríṣiríṣi ìho, àwọn agbègbè Tibesti sì ma ń lọ lutes àti fiddles. Àwọn orin tí wọ́n ń fi ìho àti trópẹ́tì kọ, tí wọ́n sì ń pè ní "waza" tàbí "kakaki" ni wọ́n ma ń lò ní ayẹyẹ ìfiọba joyè àti àwọn ayẹyẹ òtòkùlú míràn ní orílẹ̀ èdè Chad àti Sudan.

Àwòrán àwọn olórin ilẹ̀ Chad

Orin-ìyìn orílẹ̀-èdè Chad ni "La Tchadienne," tí Paul Villard àti Louis Gidrol ko ní ọdún 1960 pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ọmọ ilé ìwé Gidrol.

Àwọn orin tó gbajúmọ̀ àtúnṣe

Lẹ́yìn òmìnira Chad, àwọn ènìyàn Chad bẹ̀rẹ̀ sì ń ko oríṣiríṣi orin , pàápàá jùlọ àwọn orin tó soukous orin Democratic Republic of the Congo.[1] Irú àwọn orin míràn tí wọ́n tún ń ko ni sai, ẹgbẹ́ Tibesti ni ó mú irú àwọn orin yìí gbajúmọ̀.[2]

Àwọn Ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. "The Phat Planet World Music". May 13, 2006. Archived from the original on May 13, 2006.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. "Listing". www.cp-pc.ca. Archived from the original on 2006-10-01. Retrieved 2020-01-13.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)