Òwò ẹrú (Brasil)

(Àtúnjúwe láti Owo eru (Brazil))

ADEYEMO AKINLOYE STEVE

ÀKỌ́SÍLẸ̀ DÍẸ̀ LÓRÍ I ÌGBÉ AYÉ ỌMỌ YORÙBÁ ILẸ̀ BRAZIL KAN TÍ Ó FI ÌGBÉ AYÉ RẸ̀ TAKO ÒWÒ ẸRÚ (LÁTI ỌWỌ́ : ASA J. DAVIS)

Alága, gbogbo ẹ̀yin ọ̀fọ̀ọ̀kùn, iyì ńlá ni fún mi láti wà ní ìjókòó lónìí láti sọ̀rọ̀ lórí ‘Ìlàjú Yorùbá’. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ṣiṣẹ́ rí ni ọgbà Fásitì Ìbàdàn, n kò rò wí pé mo yẹ ní emi tí ó lè máa ka àpilẹ̀kọ lórí ọ̀rọ̀ Ìlàjú Yorùbá, mo lè ti ṣe àwọn ìwádìí tí ó jẹ mọ́ àkòrí yìí lóòótọ́ fún àwọn àkókò kan. Bí a bá fi ojú inú wo ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwa àtọ̀húnrìnwá ni a ti ń ṣe ìwádìí orírun wa dé ilẹ̀ Yorùbá. Ọ̀pọ̀ oníwádìí ìjìnlẹ̀ ni wọ́n kọ ìpàkọ́ sí ìwádìí òpin ọ̀rọ̀ ẹrú ní ilẹ̀ Brazil bí o tilẹ̀ jẹ́ wí pé gbogbo ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí àti agídí paraku lórí òwò ni ó mú àwọn ẹlẹ́nuugbọ̀rọ̀ dìde láti máa tako òwò ẹrú ní ilẹ̀ Brazil. A gbọ́dọ̀ mọ̀ láti ilẹ̀ wí pé àti dúdú àti funfun ni wọ́n jọ pa ọwọ́ pọ̀ gbé ogun tí òwò ẹrú ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ni kò fi ara mọ́ àtakò yìí. Ọ̀kan nínú àwọn tí ó tako òwò ẹrú yìí jẹ́ ọmọ Yorùbá ilẹ̀ Brazil kan. Ẹ jẹ́ kí á wo ìsẹ̀lẹ̀ yìí:

Ní ọjọ́ kan ẹrú aláwọ̀ dúdú kan jáde ni ilé olówó rẹ̀, ó sì lọ sí ọ̀dọ̀ agbejọ́rò aláwọ̀ dúdú kan pẹ̀lú ọwọ́ tí agbẹ́jọ́rò yìí yóò lò láti sọọ́ di òmìnira. Tohùn-tẹnuè ni bàbá olówó ẹrú wọ inú Ọọ́fíìsì agbẹjọ́rò ọ̀rẹ́ ẹ rẹ̀ yìí tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bèèrè lọ́wọ́ ẹrú yìí, ìdí tí ó fi fẹ́ fi òun sílẹ̀. Ó sọ síwájú wí pé òun ń tẹ́ ẹ lọ́rùn àti wí pé kò yẹ kí ó ba inújẹ́ rárá níwọ̀n ìgbà tí oun ti ń ṣe bíi baba fun-un. Ní tòótọ́ ẹrú yìí ń rí ìtọ́jú kò sì sí ìdí fún-un láti kùn rárá, ìdí nìyí tí ẹrú yìí kò fi rí àtakò kankan fún ọ̀rọ̀ olówó rẹ̀ yìí. Ṣùgbọ́n ní ìgbà tí agbẹjọ́rò yìí rí i wí pé ẹrú yìí kò rí ìdáhùn ni ó bá fọ èsì wí pé : ní tòótọ́ ẹrú yìí yóò gba ìtúsílẹ̀ nítorí pé kò ní òmìnira láti ba inú jẹ́ bí ó ṣe wù ú. Báyìí ni ẹrú yìí ṣe gba ìtúsílẹ̀.

Ó sì ba ni lọ́kàn jẹ́ wí pé àwọn ẹrú tí ọwọ́ tẹ̀ padà lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n bá ti sá lọ ni wọ́n ń pa, ìdí nìyí tí òǹkọ̀wé yìí ṣe kọ ọ́ sílẹ̀ pé: Àwọn ènìyàn dúdú mẹ́rin yìí, tí àwọn ènìyàn ń tì ní ìtìkutì (àbí kí á sọ wí pé tí àwọn igun ń tì ní ìtìkutì) kìí ṣe ènìyàn lasan o; ìràwọ̀ mẹ́rin ni wọ́n, ìmọ́lẹ̀ mẹ́rín ni wọ́n, bẹ́ẹ̀ sì ni ìròrí mẹ́rin ni wọn pẹ̀lú. Láàrin rògbòdìyàn ni a sọ wọ́n di eruku, tí ó bá sì di ọjọ́ iwájú àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n yóò kọ nípa wọ́n sí àwùjọ àwọn ìràwọ̀ àti àwọn oòrùn.

Àwọn ènìyàn kò sì ṣe bẹ́ẹ̀ kọ àkọsílẹ̀ àwọn ènìyàn dúdú tí ó ní ọwọ́ nínú òwò ẹrúu rẹ̀, ìwọ̀nba èyí tí a sì rí ni ó wá láti ọ̀dọ̀ aláwọ̀ funfun àti wí pé ìwọ̀nba péréte ni àwọn aláwọ̀ dúdú tí a kọ àkọsílẹ̀ wọn. Àwọn aláwọ̀ funfun kò kọ ibi ara sí ọ̀rọ̀ Luiz Gama, wọn kìí sì sáábà fọn rere rẹ rárá ṣùgbọ́n ìrìn-àjò rẹ̀ láti ẹrú lásán di olókìkí ènìyàn ni ó yẹ kí á kọ ibi ara sí ju bí a ti ṣe yìí lọ. Abala méjì ni ó wú mi lórí jù nínú ìgbé ayé Gama; àkọ́kọ́ ni dídàgbà rẹ̀ nínú òfíì àti ọ̀láà. Ní àsìkò yìí ni ó wá ìyá a rẹ̀ tì, tí a sì ta òun náà sí oko ẹrú ní ọ̀nà àìtọ́. Èkejì ni ìlàkàkà rẹ̀ láti tako òwò ẹrú ní àsìkò tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ń fàdí sẹ́yìn. Ṣùgbọ́n ju gbogbo rẹ lọ, ìgbé ayé Gama yàtọ̀ tààrà pẹ̀lú u bí ó ti jẹ́ agbẹnusọ fún ènìyàn dúdú àti ẹni tí ó gba ara rẹ̀ là fúnra ara rẹ̀. Ó ṣe ni láàánú wí pé ọ̀gbẹ́mi yìí kò fi bẹ́ẹ̀ sọ púpọ̀ nípa ìtàn ìgbésí ayé ara rẹ̀, lẹ́yìn díẹ̀ tí a mọ̀ láti ara ìwé kan tí ó kọ nípa ìtàn ìgbésí ayé e rẹ̀. A bí Gama ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n osù kẹfà ọdún 1830 (28/6/1830) ní ìlú Sao Salvador. Luiza Mahin, Ànàgó (Olómìnira) ni ìyá a rẹ̀ ṣùgbọ́n òyìnbó Potogí tí ó ní owó lọ́wọ́ ni bàbá rẹ̀. Gama kò sọ orúkọ bàbá rẹ̀ síta ṣá. Tí a bá wo àyíká tí a ti bí Gama, a ó rí i wí pé ní tòótọ́ ni, ti àwọn ènìyàn bá pè é ní “àyà koko ni ti Ìnàkí”, “kìí –gbọ́-kìí-gbà”, “oníròbínújẹ ọkàn” àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n Rui Brabosa pè é ní “ẹni tí kìí ṣe ojo rara”. Tí a bá sì fẹ́ẹ́ mọ ohun tí ó bí àwọn àpèjẹ yìí, a gbọ́dọ̀ kọ ibi ara sí gbogbo ohun tí ó dìrọ̀ mọ́ ìbí rẹ̀ àti ìdàgbàsókè rẹ̀. Ní àkọ́kọ́, a bí Gama ní àsìkò tí àwọn àyípadà kan bẹ̀rẹ̀ sí í dé sí Brazil léyìn tí Brazil yọ kúrò ní oko ẹrú (1840-1889). Àwọn àyípadà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ní dé bá ilẹ̀ Europe fúnra rẹ̀ ń ṣe àkóbá fún Brazil ní àsìkò yìí. Ní àfikún, ní àárìn àwọn aláwọ̀ dúdú, àsìkò yìí ni dúkùú ń wáyé láti ọ̀dọ̀ àwọn dúdú lórí ìlòdì sí òwò ẹrú. Àsìkò yìí gan-an tí gbọ́nmi-síi, omi-ò-tóo ń wáyé ní ìlú rẹ̀, Bahia lórí ọ̀rọ̀ òwò ẹrú yìí ní pàtàkì. Ibi Gama si papọ̀ mọ́ rògbòdìyàn tí àwọn ọmọkùnrin gbé dìde ní ọdún 1835, ọmọ ọdún márùn-ún péré ni Gama ní àsìkò yìí. Ọ̀kan nínú àwọn ohun tí ó ṣe okùnfà irú ìgbé ayé tí Gama gbé ni rògbòdìyàn ìlú rẹ̀ tí a dà pè ní Incon fidecia da Bahia (rògbòdìyàn ìlú Bahia) eléyìí tí ó ti bẹ̀rẹ̀ bíi Ọgbọ̀n ọdún kí á tó bí Gama. Èyí sì mú àwọn ènìyàn ìlú Brazil ní ẹ̀mí ní ìgbà náà. Bẹ́ẹ̀ sì ni a ríi kà wí pé àwọn ènìyàn pàtàkì orílè èdè Brazil kan ti gba ẹ̀kọ́ ní orílè èdè Europe níbi tí ìròrí àwọn ènìyàn ti kún fún ìgbòmìnrira. Ẹ̀yí sì ni àwọn ènìyàn mú bọ̀ wá sí ilé ní àsìkò yìí. Àwọn nǹkan mìíràn tí ó dá ọ̀tẹ̀ sílẹ̀ ni bí àwọn olówó kò ṣe jẹ́ kí tálákà ó ní àti bí àwọn ọmọ Brazil kò ṣe rí ààyè nínú ipò gíga ilé ìjọ́sìn. Àwọn ọmọ Brazil gan-an tún ń bá ara wọn jà ní àtàrí àwọ̀ dúdú àti àwọ̀ funfun. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n sì máa ń dẹ́yẹ sí dúdú níbi àti dé ipò gíga, èyí sì ń bí dúkùú àti ọ̀tẹ̀ ní àsìkò yìí. Òmíràn nínú ohun tí a fi sàmì ìgbé ayé Gama ni rògbòdìyàn 1835, Ohun tí ó bí ọ̀tẹ̀ yìí ni bí àwọn aláwọ̀ dúdú tí ó jẹ́ ẹlẹ́sìn Islam kan ṣe kó ara wọn jọ láti gba ìjọba lọ́wọ́ àwọn ìjọba ilẹ̀ Brazil. Ìjà yìí jẹ́ ìjà ẹ̀sìn (Jihad) tààrà. Ìjọba ilẹ̀ Brazil náà sì gbé ojú agan sí àwọn èèyàn yìí tààrà. Ní àsìkò yìí Gama jẹ́ ẹni bí ọdún mẹ́rin péré. Látàrí rògbòdìyàn yìí, ìjọba ilẹ̀ Brazil fi ohùn ṣe ọ̀kan láti wá ini kan ní ilẹ̀ Aáfíríkà tí wọn yóò kó àwọn aláwọ̀ dúdú àárín wọn lọ nítorí pé wọ́n ń da àlááfíà ìlú rú. Ẹni tí wọ́n bá sì gbá mú ní àtàrí rògbòdìyàn yìí, pípa ni wọ́n ń pa wọ́n tàbí kí wọn fún wọn ní ẹgba lọ́pọ̀lọpọ̀, wọn a sì tún máa tì wọ́n mọ túúbú. Ó sì sòro fún ọmọ tí kò tíì pé ọdún mẹ́fà ní àsìkò yìí láti gbé ojú kúrò ní ìyà àjẹkúakátá yìí. Rògbòdìyàn yìí sì fa ikú fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ aláwọ̀ dúdú nípa kíki okùn bọ̀ wọ́n lọ́rún. Àwọn Obìnrin náà jẹ nínú ìyà yìí. Wọ́n fi ìyà jẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ nítorí pé wọ́n jẹ́ ọrẹ àwọn ànàgó lásán, wọ́n sì yin àwọn mìíràn ní ìbọn pa. Kì í ṣe ẹgba tí wọ́n ń fún àwọn ènìyàn gan-an ni ó ṣe àkóbá fún Luiz Gama ní ìgbà èwe, ṣùgbọ́n bí iye ẹgba náà ṣe pọ̀ tó ní ojúmo kan. Nítorí wí pé wọn a máa na elòmíràn ní ẹgba bíi àádọ̀tá lójúmọ́; àwọn ènìyàn tí wọ́n sì dájọ́ ẹgba fún sì pọ̀ gan-an. Àwọn ẹrú tí ó wà láàrin àwọn ènìyàn yìí ni wọ́n dá padà fún olówó wọn lẹ́yìn ìjìyà wọn. Èyí tí kò bá sì lè ṣiṣẹ́ dáadáa ni àwọn olówó wọn tún tà padà fún elòmíràn. Ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ó níí ṣe pẹ̀lú bí Gama ṣe dàgbà ni ó sẹlẹ̀ ní ìgbà tí ó wà ní ọmọ ọdún méje. Àwọn kan kó ara wọn jọ, tí wọ́n já ìjọba gbà tipátipá ṣùgbọ́n kò pẹ́ tí ìjọba fi ṣẹ́gun wọn pẹ̀lú ohun èlò ogun. Wọ́n pe rògbòdìyàn yìí ní Sabinada. Ìdí ni wí pé Sabino ní ó síwájú rògbòdìyàn yìí, ó sì ṣe é ṣe kí bàbá Gama kópa nínú rògbòdìyàn yìí. Ní ìsojú Gama ni ilé jíjó, èèyàn pípa ati bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ ṣe sẹlẹ̀ ní àsìkó rògbòdìyàn yìí. Inú n rògbodìyàn yìí ni ó ti wá ìyá rẹ̀ tì, tí bàbá rẹ̀ náà si báa run. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣé ìrìbọmi onígbàgbọ́ fún Gama, kò fi ẹ̀sìn Islam àti ìgbàgbọ́ aláwọ̀ dúdú ìyá a rẹ̀ ṣeré rára. Ẹ̀kẹ́ta gbògíì nínú ohun tí ó ṣe okùnfà irú ìgbé ayé tí Luiz Gama gbé ni títà tí bàbá rẹ̀ tàá sí oko ẹrú. Kékeré ni ojú rẹ sì ti là sí ìyànjẹ tí ìyá rẹ̀ máa n takò nígbà ayé rẹ̀. Ṣùgbọ́n ó jẹ́ ẹní tí ìyá rẹ̀ fi ìfẹ́ hàn sí láti kékeré. Títa lẹ́rú rẹ̀ jẹ́ kí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrírí tí ó dìrọ̀ mọ́ òwò ẹrú. Ìdí ni wí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀ nítorí pé ìlú Bahama tí rògbòdìyàn pọ̀ sí jùlọ láti tako òwò ẹrú ni Gama ti wá, èyí ni ó sì fàá tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn fi ń rà á ní àràtúntà. Ọ̀kan nínú àwọn tí ó rà á lẹ́rú ni Cardoso jẹ́, ní tòótọ́ Cardoso fi ìyà jẹ̀ ẹ́ ṣùgbọ́n òun náà ni ó jẹ́ kí Gama ka ìwé. Ní ọdún 1848, Gama gba iṣẹ́ ológun lẹ́yìn ìgbà tí ó ti sa kúrò ní ipò ẹrú, ó sì gba okùn méjì kí wọ́n tó lé e dànù nítorí wí pé ó gbé ẹnu sí ọ̀gá rẹ̀ kan. Lẹ́yìn tí ó kúrò nínú iṣẹ́ ológun, ó bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ṣiṣẹ́ ṣùgbọ́n àtakò òwò ẹrú rẹ̀ ń jẹ́ kí wọn ó lé e dànù kí wọn sì kà á kún aláìgbọràn àti alágídí ènìyàn. Ní ọdún 1864, òwò ẹrú bẹ̀rẹ̀ sí í wá sí òpin díẹ̀díẹ̀ látarí ọwọ́ tí àwọn ènìyàn àti ìjọba gbé láti mú kí òwò ẹrú wá sí òpin. Lẹ́yìn àsìkò yìí, Gama bẹ̀rẹ̀ sí ní lọ́wọ́ sí títú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹrú sílẹ̀ ní Brazil, ó sì gbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbésè lórí ọ̀rọ̀ yìí. Ní ọdún 1871, òfin tí ó fi ọwọ́ sí ìtúsílẹ̀ ẹrú di gbígbà wọlé. Ni gbogbo ìgbà tí àwọn alásẹ bẹ̀rẹ̀ sí fi ara mọ́ pípa òwò ẹrú rẹ́ díẹ̀díẹ̀, Luiz Gama kò fi ar amọ́ èyí, ó ń jà fitafita wí pé kí òwò ẹrú parẹ́ káíkíá ni. Ìdí ni wí pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn alásẹ ń fi ojú òfin òwò ẹrú gbo ilẹ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí. Luiz Gama tún mú ọ̀rọ̀ yìí lọ sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin níbi tí wọn kò ti fi ara mọ́ ìdáǹdè ẹsẹ̀kẹsẹ̀ fún gbogbo ẹrú. Títí tí Gama fi kú ni 1882, àbá yìí kò tí ì di òfin. Kí ó tó kú, ó tún dara pọ̀ mọ́ ìwé ìròyìn kan tí ó n ṣiṣẹ́ lákọlákọ láti tako òwò ẹrú, orúkọ ìwé ìròyìn yìí ni Radical Paulistane ó sì ṣiṣẹ́ kíkan kíkan pẹ̀lú ìwé ìròyìn yìí láti rí i wí pè òwò ẹrú di ohun ìgbàgbé kíákíá. Ní ọjọ́ kẹtàlá, oṣù kárùn-ún ọdún 1888, tí ó jẹ́ ọdún kẹfà lẹ́yìn ikú Luiz Ganzaga Pinto da Gama ni aba tí ó fagi lé òwò ẹrú di òfin ní ilẹ̀ Brazil. Ṣùgbọ́n ìgbẹ́ ayé Gama gẹ́gẹ́ bí amòfin, òǹkọ̀wé àti olóṣèlú fi hàn gbangba pé ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ sí òmìnira tẹrú-tọmọ ni. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni Frederick Douglass ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà pẹ̀lú Cugoana, Equiano, àti Antoine Amo ṣe ní ilẹ̀ Europe. Gbogbo ìgbìyànjú àwọn wọ̀nyí ni ó mú àyípadà rere wáyé ní séńtúúrì kọkàndínlógún.

Iwe ti a yewo

àtúnṣe

SOME NOTES ON THE LIFE AND TIME OF AN AFRO-BRAZILIAN ABOLITIONIST OF YORUBA DESCENT By A Davis, Amherst College.