Pípẹ̀ka Èdè
Idí tí àwọn ẹ̀ka-èdè fi ń yàtọ̀ sí ara wọn
Gẹ́gẹ́ bí ìtàn àtẹnudẹ́nu ti sọ àti bí àkọsílẹ̀ ṣe fi yé wa, ìlú Ilé-Ifẹ̀ ni gbogbo ọmọ Yorùbá ti ṣẹ̀ wá, a ní láti ṣe àgbéyẹ̀wò ìdí tí èdè Yorùbá fi wá pẹ̀ka sí oríṣìíríṣìí ọ̀nà.
Àkọsílẹ̀ fi yé wa pé nígbà tí ó di wí pé àwọn ìran Odùduwà bẹ̀rẹ̀ sí ní í pọ̀ sí i, tí wọ́n sì ń fọ́n káàkiri sí tòsí àti ọ̀nà jínjìn, bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ sí ní í yàtọ̀ sí ara wọn díẹ̀ díẹ̀. Ohun tí a ń sọ ni pé nígbà tí àwọn ọmọ Yorùbá bẹ̀rẹ̀ sí ní í gbèèrú sí i, wọn kò le è dúró sí ojú kan nítorí pé ojú kan kò le è gbà wọ́n mọ́, wọ́n ní láti má a fọ́n káàkiri. Èyí ni àwọn Òyìnbó ń pè ní ‘population explosion and expansion’.
A rí i pé nígbà tí ó di pé eléyìí ń ṣẹlẹ̀, ogun abẹ́lé bẹ̀rẹ̀ sí ní í wáyé, ogun òkèèrè náà bẹ̀rẹ̀ sí ní í jẹyọ. Eléyìí bẹ̀rẹ̀ sí ní í fa ìgbòkègbodò àti ìfọ́nkáàkiri. Nígbà tí èdè àìyedè, ogun àti ọ̀tẹ̀ wọlé, ó di wí pé kí àwọn tí a kó ní ìkogun má a di ẹrú fún àwọn tí ó ṣẹ́gun wọn. Eléyìí wá ń fa òwò-ẹrú ṣíṣe (slave trade). Bí a bá wo àwọn orílẹ̀ èdè tí ó wà lẹ́yìn odi Nàìjíríà bí i Tógo, Benin Republic, Sierra Leone, Gambia, Cuba, Brazil àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, a ó rí wí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ní wọ́n tà ní ẹrú sí àwọn orílẹ̀-èdè yìí. Kí ni ìtumọ̀ èyí? Bí àwọn náà ṣe ń bímọ, tí wọ̣́n ń gbèèrú sí i ni ẹ̀ka-èdè bẹ̀rẹ̀ sí ní í jẹyọ lóríṣìíríṣìí. Ìṣípòpadà tàbí gbígbéra lọ láti agbègbè kan lọ sí ibòmíràn náà ń fa kí ẹ̀ka-èdè má a yàtọ̀ sí ara wọn.
Ohun mìíràn ni òwò-ṣíṣe pẹ̀lú àwọn tí èdè tàbí ẹ̀ka-èdè wọn yàtọ̀ síra. Eléyìí má a ń fa bí àwọn ẹ̀ka-èdè ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ní í yàtọ̀ sí ara wọn. Báwo ni èyí ṣe máa ń wáyé? Nígbàtí àwọn oníṣòwò àti oníbàárà bá bẹ̀rẹ̀ síí dínàá-dúrà, tí wọ́n sì ń kọ́ èdè araa wọn, ìyàtọ̀ díẹ̀ díẹ̀ má abá èdè abínibí wọn.
Ìgbéyàwó láàárín àwọn tí ó ti agbègbè mìíràn, tí ẹ̀ka-èdè tí wọ́n ń sọ sí, yàtọ̀ sí ara wọn, a má a ń fa kí oríṣìíríṣìí ẹ̀ka-èdè má a jẹ yọ. Fún àpẹẹrẹ, tí Ọ̀yọ́ àti Èkìtì bá fẹ́ ara wọn gẹ́gẹ́ bí lọ́kọ-láya, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n ti ń gbé pọ̀, tí wọ́n sì ń bímọ, ẹ̀ka èdè wọn a bẹ̀rẹ̀ sí níí yàtọ̀ díẹ̀díẹ̀. Eléyìí á mú ìyàtọ̀ wáyé nínú ìsọ̀rọ̀ àwọn ọmọ lẹ́yìn ọjọ́ pípẹ́.
Bí àjàkálẹ̀ àrùn bá bẹ́ sílẹ̀, tí ó wá di wí pé àwọn ènìyàn ń sá kúró láti agbègbè kan sí ibòmíràn, èdè má a ń ti ipasẹ̀ eléyìí pín sí ẹ̀ka oríṣìíríṣìí.
Bákan náà, ìbáṣepọ̀ láàárín ẹ̀yà kan àti òmíràn má a ń fa kí ẹ̀ka-èdè bẹ̀rẹ̀ sí ní í yàtọ̀ sí ara wọn. Igbó dídí, omi kíkún àti àwọn òkè ńlá tí ó pín àwọn àwùjọ tí wọ́n ń sọ èdè kan náà níyà a má a mú kí ìyípadà de bá bí àwọn ènìyàn wọ̀nyìí ṣe ń sọ èdè wọn. Àwọn nǹkan mẹ́ta wọ̀nyìí wọ́pọ̀ nínú ìdí tí ẹ̀ka-èdè fi má a ń wáyé.
Lákòótán, ìfẹ́ lati mọ àwọn ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn ẹ̀yà mìíràn tí ó mú kí a súnmọ́ wọn sí i a má a fa ìyàtọ̀ láàrin àwọn ẹ̀ka-èdè.