Mòsámbìkì: Ìyàtọ̀ láàrin àwọn àtúnyẹ̀wò

Content deleted Content added
New page: MOZAMBIQUE Abe Portugal ni Mozambique wa tele. Bèbè gúsù-ìlà-oòrùn Aáfíríkà ni Mozambique wa. Ó tóbi ju Portugal gan-an lo. Àwon ìlú tí ó wà ní bèbè Moza...
(Kò ní yàtọ̀)

Àtúnyẹ̀wò ní 08:53, 16 Oṣù Kẹta 2008

MOZAMBIQUE

Abe Portugal ni Mozambique wa tele. Bèbè gúsù-ìlà-oòrùn Aáfíríkà ni Mozambique wa. Ó tóbi ju Portugal gan-an lo. Àwon ìlú tí ó wà ní bèbè Mozambique bíi Laurence Marquis (tí ó jé olú-ìlú Mozambique) àti Beira ni àwon okò ojú omi ti n gúnlè. Okò ojú irín ni ó so àwon ìlú wònyí mó àwon ilè tí ó kan Mozambique gbàngbàn. Àwon ènìyàn tí ó wà ní Mozambique tó 7,376,000. Púpò nínú won ni ó jé Bantu. Púpò nínú won ni ó n sisé ní South Africa níbi tí wón ti n wa ohun àlùmó-ónni ilè (minerals). Àwon mìíràn n se isé àgbè. Wón n gbe òwú, kasú, ìrèké àti béè béè lo. Orí ilè peere ni wónm ti n gbin àwon wònyí. Orí òkè ni wón tí n gbin tíì (tea).

Vasco da Gama ni ó se àwárí Mozambique ní 1498. Àwon ara Portugal bèrè síí wá sí ibè ní nnkan bí 1500. Mozambique sì bèrè síí se pàtàkì fún òwò erú. Àwon ilé-isé (companies) ni ó n darí ilè yìí láti 1891 sí 1942. Odún 1942 ni ìjoba Portugal bèrè síí darí ilè yìí. Ní 1960 àti 1970, Portugal kó òpòlopò omo ogun lo sí Mozambique láti bá àwon tí ó n jà fún òmìnira jà.