Pápáa Bonga
Pápáa Bonga jẹ́ pápáa epo ròbì kan ni Nàìjíríà. Ó wà ní License block OPL 212, Gúúsù ìwọ̀ oòrùn agbègbè Niger Delta ní Nàìjíríà, pápá náà jẹ́ ilẹ̀ tí ó tó 60 km2. Wọ́n ṣe ìwárí pápá náà ní ọdún 1996, ìjọba sì fi owó sí ṣíṣe iṣẹ́ lórí ẹ̀ ní ọdún 2002. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ń ṣe epo ní pápá náà ní oṣù kọkànlá ọdún 2005. Wọ́n ń ṣe epo petirólù àti gásì ní pápá náà.
Ilé-iṣẹ́ Shell Nigeria ni ó ni ìdá márùn-ún lé làádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún ilẹ̀ pápá náà. Àwọn tó kù tí ó nílẹ̀ níbẹ̀ ni Exxon (20%), Nigerian AGIP (12.5%) àti Elf Petroleum Nigeria Limited (12.5%)