Bébà jẹ́ ohun elo inọ̀wé tẹ́ẹ́rẹ́ tí s pèsè látinú ẹ̀rọ nipa pípo kẹ́míka pọ̀ tàbí lílọ ewé tàbí igi papọ̀ láti sọ wọ́n di Ìwé Ni kete ti Omi bá ti ro kúrò lára ohun tí a lọ̀ rí a fẹ́ fi ṣe ìwé nínú asẹ́ tí a ko sí ni a ó ma fọn ká sí ibi tí a ó ti tẹ̀ẹ́ tàbí fún un tí a ó sì sa tí yóò fi gbẹ.

Bébà ṣíṣe bẹ̀rẹ̀ ní Asia tabí ilẹ̀ Ṣáínà ní nkan bí ọdún 105 CE[1] sẹ́yìn láti inú ẹbí Han eunuch Cai Lun, bíótilẹ̀ jẹ́ wípé àwọn onímọ̀ nípa ilẹ̀ ti ṣàwárí ẹ̀rún bébà kan ní ilẹ̀ Ṣáínà ní nkan bí sẹ́ntúrì kejì BCE ní China ṣáájú kí àwọn ẹbí náà tó tún ṣe ìfilọ́ọ́lẹ̀ rẹ̀. China.[2]


Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ ni wọ́n fi ń ṣe bébà tẹ́lẹ̀, àmọ́ lónìn ín, wọ́n ti ń ṣe bébà lọ́pọ̀ yanturu pẹ̀lú irinṣẹ́ ńláńlá, tí àwọn irinṣẹ́ kan sì tún ń bébà ní ìwọn batà mẹ́wá nígígù sí ìwọ̀n bàtà ẹgbẹ̀rún méjì ní fífiẹ̀ láàrín ìṣẹ̀jú péréte. Wọ́n sì le ṣe bébà tí ó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbàọ́rùn un mẹ́fà láàrín ọdún kan. [ ti ko jẹrisi ni ara ] Bébà jẹ́ ohun èlò pàtàkì tí kò sí ohun tí a kò lè fi ṣe tàbí lòó fún. A lè fi tẹ̀wé jáde, a lè fi ya àwòrán jáde, a lè fi ṣe pátákó ajúwe, a lè fi kọ nkan, a tà lè fi pa nkan rẹ́ pẹ̀lú.


Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Hogben, Lancelot. "Printing, Paper and Playing Cards". Bennett, Paul A. (ed.) Books and Printing: A Treasury for Typophiles. New York: The World Publishing Company, 1951. pp. 15–31. p. 17. & Mann, George. Print: A Manual for Librarians and Students Describing in Detail the History, Methods, and Applications of Printing and Paper Making. London: Grafton & Co., 1952. p. 77
  2. Tsien 1985, p. 38