Patricia Tolliver Giles

Patricia Tolliver Giles (née Patricia Denise Tolliver, wọ́n bí i ní ọdún 1973) [1] ó jẹ́ adâjọ́ tí ó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìjọba àpapọ̀ ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà United States ó sì ń ṣiṣẹ́ ní ilé-ẹjọ́ agbègbè ìlà oòrùn ti Virginia (United States District Court for the Eastern District of Virginia). Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi igbákejì amòfin àgbà ní agbègbè ìlà oòrùn ti Virginia ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà láàárín ọdún 2003 sí ọdún 2021.

Patricia Giles
Judge of the United States District Court for the Eastern District of Virginia
Lọ́wọ́lọ́wọ́
Ó gun orí àga
November 1, 2021
Appointed byJoe Biden
AsíwájúLiam O'Grady
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí
Patricia Denise Tolliver

1973 (ọmọ ọdún 50–51)
West Point, New York, U.S.
EducationUniversity of Virginia (BA, JD)

Ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n wo Giles dàgbà ní Hampton, Virginia.[2][3] Giles kẹ́kọ̀ọ́ gboyè àkọ́kọ́ (Bachelor of Arts) ní ilé ẹ̀kọ́ gíga ti Virginia (University of Virginia) ní ọdún 1995 bẹ́ẹ̀ ni ó gba ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú òfin ní ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti ń kọ́ nípa ìmọ̀ òfin ti Virginia (University of Virginia School of Law) ní ọdún 1998.[4]

Bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́

àtúnṣe

Lẹ́yìn tí Giles kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti ń kọ́ nípa ìmọ̀ òfin, ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé òfin fún adájọ́ Gerald Bruce Lee ti ilé-ẹjọ́ ẹlẹ́kajẹ́ka ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà tí ó jẹ́ ti agbègbè ìlà-oòrùn Virginia láti ọdún 1998 sí 2000. Láti ọdún 2000 sí ọdún 2003, ó jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Cooley Godward LLP. Láti ọdún 2003 sí ọdún 2019, ó di ipò mú gẹ́gẹ́ bí igbákejì amòfin àgbà ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà ní ẹ̀ka tó ń rí sí àwọn ẹ̀sùn tó ní agbára. Ó ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì amòfin ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà fún agbègbè Virginia láti ọdún 2003 sí 2021, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí igbákejì alákòóso fún amòfin àgbà ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà. [4]

Wò pẹ̀lú

àtúnṣe

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. United States Senate Committee on the Judiciary: Questionnaire for Judicial Nominees: Patricia Tolliver Giles
  2. "Warner & Kaine Announce Eastern District of Virginia Judicial Recommendations". Federal Information & News Dispatch. April 27, 2021. "Ms. Giles was raised in Hampton, Virginia, the daughter of a career military family." 
  3. Green, Frank (Oct 27, 2021). "Virginia gets two new federal judges; two new vacancies are expected". Richmond Times Dispatch. https://richmond.com/news/local/crime-and-courts/virginia-gets-two-new-federal-judges-two-new-vacancies-are-expected/article_67c82d85-ca77-5586-a5f4-d6c424d57346.html. 
  4. 4.0 4.1 "President Biden Names Fifth Round of Judicial Nominees", White House, June 30, 2021 Àyọkà yìí mú ìkọ̀wé láti orísun yìí tí ó wà ni ìgboro.
àtúnṣe
Àdàkọ:S-legal
Preceded by
Liam O'Grady
Judge of the United States District Court for the Eastern District of Virginia
2021–present

Àdàkọ:S-inc Àdàkọ:S-end

Àdàkọ:United States 4th Circuit district judges