Peggy Ovire
Peggy Ovire Enoho tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Peggy jẹ́ olùgbéré-jáde, òṣèré àti módẹ́ẹ̀lì ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà òun ni ó gba amì-ẹ̀yẹ fún “Òṣèrébìnrin tí ọjọ́ iwájú rẹ̀ dára jùlọ ti (English)” níbi ayẹyẹ City People Entertainment Awards ti ọdún 2015. [1][2][3][4][5][6][7]
Peggy Ovire | |
---|---|
Peggy Ovire in "Husbands of Lagos" | |
Ọjọ́ìbí | Peggy Ovire Enoho October 21 Surulere, Lagos State |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Ambrose Alli University |
Iṣẹ́ | Actor |
Ìgbà iṣẹ́ | 2013–present |
Notable work | A Long Night |
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeOvire jẹ́ ọmọ ìlú Ughelli ní Ìpínlẹ̀ Delta, àmọ́ wọ́n bi sí Ìpínlẹ̀ Èkó òun ni àníkẹ́yìn àwọn òbí rẹ̀. Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti ìlú Ìtìrẹ́ ní agbègbè Súrùlérè àti ilé-ẹ̀kọ́ oníwé mẹ́wàá ti Ansarudeen ní ìlú Súrùlérè kan náà ní Ìpínlẹ̀ Èkó Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Fásitì ti Ìpínlẹ̀ Delta tí ó wà ní ìlú (Abraka), àmó tí kò parí níbẹ̀. Ó padà sí ilé-ẹ̀kọ́ fásitì ti Ambrose Alli láti parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ nínú ìmọ̀ Okòwò àti ìṣúná.[8]
Iṣẹ́ rẹ̀
àtúnṣeṢáájú kí Ovire tó di ìlú-mòọ́ká nínú Nollywood, ó ti kọ́kó ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí módẹ́ẹ̀lì.[4] Ovire ṣe àlàyé nínú ìfọ̀rọ̀nwánilẹ́nu wò kan pẹ́lú Ìwé-ìròyìn Yhe Puch wípé eré òun àkọ́kọ́ ni Uche Nancy gbé jáde .[4][9] Ó dinlààmì-laaka nínú iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣèré nígbà tí ó kópa nínú eré àtìgbà-dégbà onípele ti àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Husbands of Lagos tí wọ́n ma ń ṣàfihàn rẹ̀ lórí àwọn ẹ̀rọ amóhù-máwòrán ilẹ̀ Nàìjíríà. [4][7]
Àwọn amì-ẹ̀yẹ àti ìfisọrí
àtúnṣeOvire gba amì-ẹ̀yẹ ti Òṣèrebìnrin tí ọjọ́ iwájú rẹ̀ dára jùlọ ní ọdún 2015 nínú ayẹyẹ City People Entertainment Awards.
Àwọn eré tí ó ti gbé jáde
àtúnṣeYàtọ̀ sí wípé ó jẹ́ òṣèré, Òvíre tún jẹ́ olùgbéré-jáde tí ó sì gbé àwọn eré bí Ufuoma, Fool Me Once, àti The Other Woman jáde.
Àwọn àṣàyàn eré àti eré oríbẹ̀rọ amóhù-máwòrán
àtúnṣe- A Long Night
- Royal Switch
- Game Changer
- Husbands of Lagos (TV series)
- Playing with Heart
- Marry Me Yes or No
- The Apple of Discord
- Last Engagement
- Second Chances(2014) gẹ́gẹ́ bí Lọ́ládé
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Acting doesn’t pay my bill - Enoho Ovire". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2013-11-15. Retrieved 2019-11-27.
- ↑ "Beauty queen turned actress, Peggy Ovire is a year older today". Nigerian Entertainment Today (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2015-10-21. Retrieved 2019-11-27.
- ↑ Ikeru, Austine (2018-11-07). "Peggy Ovire Biography and Net Worth". Austine Media (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2020-10-01. Retrieved 2019-11-25.
- ↑ 4.0 4.1 4.2 4.3 Published. "I’ve never been married-Peggy Ovire". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-11-25.
- ↑ "Ovire Peggy Biography,Age,Family,Husband,Child,Movies and Net Worth". AfricanMania (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-09-10. Retrieved 2019-11-25.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "Peggy Ovire Biography; Career, Movies & Net Worth". Issuu (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-11-25.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ 7.0 7.1 Published. "I always fall ill after shooting movies – Peggy Ovire". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-11-25.
- ↑ "5 things you probably don't know about actress". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2015-10-21. Retrieved 2019-11-25.
- ↑ "Ovire Enoho: My dad is my greatest influence". The Nation Newspaper (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-01-14. Retrieved 2019-11-25.