Pepper soup

Ọbẹ̀ aláta ní ilẹ̀ Africa

Pepper soup jẹ́ ọbẹ̀ láti Nàìjíríà, tí a sè nípa lílo orísìírísìí ẹran tàbí ẹja, ata gígún, iyọ̀, efinrin àti calabash nutmeg gẹ́gẹ́ bí ohun èlò tí ó ṣe pàtàkì. Ó jẹ́ ọbẹ̀ tí ó ta tí ó ní ìrísí tí ó fúyẹ́, tí ó sì lómi. Pẹ̀lú orúkọ rẹ̀, ọbẹ̀ náà kì í ṣe èyí tí ó gbọ́dọ̀ ta, èyí tí ó túmọ̀ sí, adùn rẹ̀ le gidi gan-an, pẹ̀lú líle, kíkorò, igi, àti adùn, àti pẹ̀lú níní ọwọ́rọ́.[1] Wọ́n gbà pé ó jẹ́ oúnjẹ fún àwọn kan ní Western Africa, àti díẹ̀ nínú àwọn Ìwọ-Oòrùn ilẹ̀ Áfíríkà gbàgbọ́ pé ọbẹ̀ náà ní egbòogi nínú.

A bowl of Peppersoup with different meats.

Àgbéyẹ̀wò

àtúnṣe

Pepper soup jẹ́ ọbẹ̀ tó wọ́pọ̀ ní Nàìjíríà tí ó jẹ́ ṣíṣè nípa lílo orísìírísìí ẹran, ẹja, ata àti calabash nutmeg gẹ́gẹ́ bí ohun èlò pàtàkì.[2] [3] Pepper soup ta gidi gan-an[4] ó dẹ̀ máa ń lọ dáadáa pẹ̀lú ọtí tútù tàbí ọtí ẹlẹ́rìndùndùn. Nígbà tí wọ́n bá sè é gẹ́gẹ́ bí ní àpéjọ pàtàkì, pepper soup gbajúmọ̀ dáadáa ní Pub. Ní Nàìjíríà, wọ́n máa ń jẹ ẹ́ ní "ààyè ìgbádùn" gẹ́gẹ́ bí ìgbafẹ́ tàbí oúnjẹ " ní ìmọ̀sílára gidi ".[5] Pepper soup cubes, èyí tí a pò pọ̀ mọ́ ata tí a lò nínú pepper soup, ni ilé-iṣẹ́ kan ní Nàìjíríà ń ṣe àgbéjáde rẹ̀.

Àpèjúwe

àtúnṣe

Pepper soup jẹ́ ọbẹ̀ olómi.[6] Ó lè di ṣíṣè pẹ̀lú àpapọ̀ orísìírísìí ẹran,[7] bí ẹja, edé, ṣàkì, inú ẹ̀ran, ẹran adìẹ, ewúrẹ́,[8][9] [10] [11] ẹran tàbí awọ màlúù. Àwọn ohun èlò tí a tún lè fi kún un ni tomatoes, àlùbọ́sà aláwọ̀ ewé, ata wẹẹrẹ, kànáfùrú, cinnamon àti òrom̀bó.[12] Fufu, oúnjẹ tí a sè láti ara ẹ̀gẹ́ ṣíṣè àti gígún cassava tàbí àwọn túbà mìíràn,máa ń di lílò nígbà mìíràn gẹ́gẹ́ bí ohun èlò, èyí tí ó máa ń mú ọbẹ̀ náà ki tí ó sì máa ń jẹ́ kí ó ìrísí kíki. Nígbà mìíràn, wọ́n máa ń jẹ ẹ́ pẹ̀lú àwọn oúnjẹ mìíràn bi ìrẹsì tàbí iṣu ṣíṣè, tàbí jíjẹ pẹ̀lú àwọn ohun èròjà yìí. Ní Ìwọ-Oòrùn ilẹ̀ Áfíríkà, ìta ni wọ́n ti máa ń sè é nínú cauldron.

Pepper soup ni wọ́n gbà pé ó jẹ́ oúnjẹ láàárín àwọn ènìyàn riverine ní Nàìjíríà. Ó jẹ́ ọbẹ̀ tó gbajúmọ̀ ní Nàìjíríà (agbègbè ìwọ oòrùn ), àti àwọn ìlú mìíràn tí wọ́n ti ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì ní ìwọ oòrùn Áfíríkà. Awọn èèyàn ilẹ̀ Ìwọ-Oòrùn Áfíríkà kan gbàgbọ́ pé ọbẹ̀ adìẹ pepper soup ní iye egbòogi, tí ó sì máa ń wo àwọn aláìsàn sàn. Pepper soup nígbà mìíràn tún máa ń di jíjẹ fún àwọn obìnrin tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ, nítorí pé àwọn kan gbàgbọ́ pé ó máa ń ṣe ìrànwọ́ fún jínjinná ara lápapọ̀ àti yíyọ omi ti Ọmú.[13] Ó sábàá máa ń di jíjẹ lẹ́yìn ayẹyẹ ìgbéyàwó, fún ọ̀nà láti dá okun ara padà.

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Nigerian Pepper Soup". Serious Eats (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-07-23. 
  2. McWilliams, J.E. (2005). A Revolution in Eating: How the Quest for Food Shaped America. Arts and Traditions of the Table: Perspectives on Culinary History Series. Columbia University Press. p. 33. ISBN 978-0-231-12992-3. https://books.google.com/books?id=mcDVbt86uSYC&pg=PA33. 
  3. Eko Magazine. Newswatch Communications Limited. 1992. p. 3. https://books.google.com/books?id=dlXhAAAAMAAJ&q=Pepper+Soup,+delicacy. 
  4. Kallon, Z.K. (2004). Zainabu's African Cookbook: With Food and Stories. Citadel Press. p. 54. ISBN 978-0-8065-2549-5. https://books.google.com/books?id=aOa64BA21m8C&pg=PA54. 
  5. Harris, J.B. (1998). The Africa Cookbook: Tastes of a Continent. Simon & Schuster. p. 124. ISBN 978-0-684-80275-6. https://archive.org/details/africacookbookta0000harr. 
  6. Long, L.M. (2016). Ethnic American Cooking: Recipes for Living in a New World. Rowman & Littlefield Publishers. p. 168. ISBN 978-1-4422-6734-3. https://books.google.com/books?id=HTWNDAAAQBAJ&pg=PA168. 
  7. Olarewaju, Olamide (October 12, 2015). "DIY Recipes: Easy way to make Nigerian peppersoup". Pulse Nigeria. Archived from the original on May 20, 2017. Retrieved September 11, 2016. 
  8. "Pepper Soup". The Congo Cookbook. April 11, 2013. Retrieved September 11, 2016. 
  9. Massaquoi, R.C.J. (2011). Foods of Sierra Leone and Other West African Countries: A Cookbook. AuthorHouse. p. 22. ISBN 978-1-4490-8154-6. https://books.google.com/books?id=bKwN7Absx6AC&pg=PA22. 
  10. Megill, E.L. (2004). Sierra Leone Remembered. AuthorHouse. p. 36. ISBN 978-1-4184-5549-1. https://books.google.com/books?id=tw-RlOWNUjwC&pg=PA36. 
  11. Asika-Enahoro, C. (2004). A Slice of Africa: Exotic West African Cuisines. iUniverse. p. 17. ISBN 978-0-595-30528-5. https://books.google.com/books?id=ddL44UDqyu8C&pg=PA17. 
  12. Montgomery, B.V.; Nabwire, C. (2001). Cooking the West African Way: Revised and Expanded to Include New Low-fat and Vegetarian Recipes. Easy Menu Ethnic Cookbooks 2nd Edition. Ebsco Publishing. p. 51. ISBN 978-0-8225-0570-9. https://books.google.com/books?id=PAL3hEQJVkkC&pg=PA51. 
  13. Webb, L.S. (2000). Multicultural Cookbook of Life-Cycle Celebrations. Cookbooks for Students Series. Oryx Press. p. 69. ISBN 978-1-57356-290-4. https://archive.org/details/multiculturalcoo00lois.