Phasianidae jẹ́ àwọn ẹyẹ tí ó ń gbé inú ilẹ̀ bi àwọn ẹyẹ àparò, ẹye ìgà, adìyẹ igbó, àwọn adìyẹ, ẹyẹ bí adìyẹ awó , àti ẹyẹ pòpòndò . Ọ́pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹyẹ fún ìdáraya nió wà ní ẹbí yìí.[1] Ẹbí yìí tóbi púpọ̀, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, wọ́n máa ń pín wọn sí àwọn mọlẹ́bí méjì, Phasianinae, àti Perdicinae. Nígbàmíràn, wọ́n máa ń tọ́jú àwọn ẹbí àti ẹyẹ míràn bí ẹbí yìí. Fún àpẹẹrẹ, àwọn ààjọ  American Ornithologists Union kó àwọn Tetraonidae (grouse), Numididae (ẹyẹ awó), àti Meleagrididae (àwọn tòlótòló) as bíi mọ̀lẹ́bí ní ẹbí Phasianidae.

Satyr

Ètò àti àtànkálẹ́

àtúnṣe

Ìrandíran Phasianidae ni ó tóbi jùlọ nínú ẹ̀ka Galliformes, tí ó sì pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà 150. Àwọn tó wà ní ẹgbẹ́ yìí ni àwọn ẹyẹ àparò àti ẹyẹ ìgà, adìyẹ  igbó, ẹyẹ bí adìyẹ awó àti ẹyẹ pòpòndò. Wọ́n ti dá àwọn tọkí àti adìyẹ òpìpì mọ̀ pé ìran wọn ni àwọn ẹyẹ tó dàbí ẹyẹ àparò àti ẹyẹ ìgà .

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. McGowan, P. J. K. (1994). "Family Phasianidae (Pheasants and Partridges)". In del Hoyo, J.; Elliot, A.; Sargatal, J.. New World Vultures to Guineafowl. Handbook of the Birds of the World. 2. Lynx Edicions. pp. 434–479. ISBN 84-87334-15-6.