Pius Nwankwo Okeke (ti a bí ní ọjọ́ ọgbọ́n Oṣù Kẹwá Ọdún 1941) jẹ amọrawo àti olùkọ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó ṣe alábàápín lọpọlọpọ sí ìwádìí ààyè Afíríkà. À mọ ọ si Bàbá tí Astronomy ní Nàìjíríà.[1]

Ìgbésí Aye Ibẹrẹ

àtúnṣe

Pius Nwankwo Okeke ni a bí ni ọjọ́ ọgbọ́n oṣù Kẹwá ọdún 1941 ni Oraukwu.[2][3] Okeke lo si ile iwe alakobere ni Oraukwu, níbi tí o tí gboyè ní Math, lẹ́yìn naa ló lọ si ilé-ìwé gírámà ni Washington memorial Grammar school láti 1957 titi di 1962. Okeke lọ si ilé ẹ̀kọ́ imọ pajawiri ni ilu Èkó, níbi tó ti ṣe ipele A. Ni 1965, wọn gba wọlé si University of Lagos lati kọ ẹkọ fisiksi. Ṣùgbọ́n nítorí ogún abele, wọn gbé é lọ si University of Nigeria, níbi tí o tí pari ẹ̀kọ́ gboyè ninu ẹ̀kọ́ Fisiksi ni ọdún 1971. O tesiwaju gẹ́gẹ́ bí ọmọ ilé ìwé gíga junior iwadi ni fasiti naa ki o tó parí PhD ni ọdún 1975, ó sì di ẹni àkọ́kọ́ ti ó gba ṣé bẹ.[4]

Àwọn itọkasi

àtúnṣe
  1. "Our Historical Backgroud". NASRDA-Centre for Basic Space Science (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-11-05. 
  2. https://africanews.space/meet-the-father-of-astronomy-in-nigeria-prof-p-n-okeke/
  3. "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2022-11-05. Retrieved 2023-12-06. 
  4. "Okeke Pius | The AAS". www.aasciences.africa. Archived from the original on 2022-11-05. Retrieved 2022-11-05.