Ewì

(Àtúnjúwe láti Poet)

Ewì jẹ́ ìlò èdè lọ́nà àrà tí akéwì ń lò láti ṣàlàyé ọ̀rọ̀ tàbí gbé èrò ọkàn rẹ jáde lọ́nà tó yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ geere. Láwùjọ Yorùbá, ewì lè wà ní àkọsílẹ̀ tàbí agbárí. Ó dá yàtọ̀ gedegbe sí ọ̀rọ̀ sísọ ṣákálá. Kíké ni wọ́n máa ń kéwì. Akéwì ni Yorùbá máa ń pe ẹni tí ó ń kéwì.[1]

Oríṣi Ewì Yorùbá

àtúnṣe

Yorùbá ní oríṣi Ewì méjì; Ewì Alohùn (Oral Poetry) àti Ewì àpilẹ̀kọ (written Poetry). Ewì Alohùn ni àwọn ewì àjogúnbá láti ọwọ́ àwọn bàbà ńlá wa. Kò pọn dandan kí irú ewì báyìí wà ní àkọsílẹ̀. Ohùn ẹnu, nígbà mìíràn pẹ̀lú ìlù, agogo ni a fi ń gbé e kalè. Bí àpẹẹrẹ; Ìjálá, Oríkì, Ẹ̀sà Égúngún, Ẹkún Ìyàwó, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ewì àpilẹ̀kọ ní àwọn ewì tí a fi ọgbọ́n àtinúdá gbé kalẹ̀ fún kíkà, yálà ní ilé-ẹ̀kọ́ tàbí fún ara ẹni. Ewì àpilẹ̀kọ lọ́pọ̀ ìgbà lò ma ń yí padà sí alohùn pàá pàá jùlọ ní ayé òde òní tí imọ̀ mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà ti gbòde kan kan. [2] [3]

Àwọn Ìtọ́kasi

àtúnṣe
  1. "poetry - Definition, Types, Terms, Examples, & Facts". Encyclopedia Britannica. 2019-10-11. Retrieved 2019-10-22. 
  2. "Àkójọpọ̀ ewì alohùn Yorùbá (Book, 1993) [WorldCat.org]". WorldCat.org. 1999-02-22. Retrieved 2019-10-22. 
  3. "9789782432063: Àkójọpọ̀ ewì àbáláyé àti ewì àpilẹ̀kọ (Paperback fountain series)". AbeBooks: 9782432067. Retrieved 2019-10-22.