Polaris Bank Limited jẹ́ ọ̀kan lára àwon ilé-ìfowópamọ́ ilẹ̀ Nàìjíríà. Ó gba ìwé-àṣẹ lọ́wọ́ Central Bank of Nigeria, èyí tó jẹ́ olùṣàkóso àwọn ilé-ìfowópamọ́ ní orílẹ̀-èdè náà.[3] [4] Ní oṣù kẹwàá ọdún 2022, Strategic Capital Investment Limited (SCIL) gba báǹkì yìí, láti sọ ọ́ di ohun ìní wọn.[5]

Polaris Bank Limited
TypePrivately Owned Commercial Bank
GenreBanking
FoundedOṣù Kẹ̀sán 24, 2018; ọdún 5 sẹ́yìn (2018-09-24)[1]
Headquarters3 Akin Adesola Street
Victoria Island, Lagos, Lagos State, Nigeria
Key peopleMuhammad K. Ahmad
Chairman
Adekunle Sonola
Chief Executive Officer[2]
IndustryFinancial services
ProductsBanking
Financial services
Websitepolarisbanklimited.com
Àwòrán ìdánimọ̀ Polaris Bank

Àwòpọ̀ àtúnṣe

Polaris Bank jẹ́ olùpèsè ètò ìṣúná ńlá ní apá Ìwọòrùn Áfíríkà àti Central Africa pẹ̀lú olú-ilé-iṣẹ́ ní Nàìjíríà. Títí di oṣù kẹsàn-án ọdún 2010, gbogbo ohun-ìní báǹkì náà ń lọ bíi $3.9 bílíọ́ọ̀nù (NGN: 611.5 bílíọ́ọ̀nù), ìpín àwọn shareholder sì ń lọ bíi US$ 630 million (NGN: 98.4 bilionu).[6]

Ìtàn àtúnṣe

A lè tọ́pa ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ilé-ìfowópamọ́ náà sí ọdún 1989, nígba ̀ tí Prudent Bank Plc., gba ìwé-àṣẹ láti di ilé-iṣẹ́ onípìín gbangba. Ní ọdún 1990, báǹkì náà gba ìwé-àṣẹ láti máa ṣòwò kékèèké. Lọ́dún kan náà, ó yí orúkọ dà sí Prudent Merchant Bank Limited. Ní ọdún 2006, Prudent Merchant Bank Limited parapọ̀ mọ́ báǹkì mẹ́ri mìíràn láti di Skye Bank Plc.[7][8]

  • Bond Bank Limited
  • EIB International Bank Plc.
  • Reliance Bank Limited
  • Co-operative Bank Plc.

Ní oṣù karún-ún ọdún 2021, báǹkì náà ṣe ìfilọ́lẹ̀ VULte, èyí tó jẹ́ pẹpẹ ilé-ìfowópamọ́ náà lórí ẹ̀rọ-ayélujára. Ilé-ìfowópamọ́ náà ní ìpèsè fún ìṣòwò lórí ẹ̀rọ-ayélujára àti lórí ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀.[9] Ní ọdún 2014, ilé-ìfowópamọ́ náà gba Mainstreet Bank Limited.[10]

Àwọn ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. Vanguard Business News (22 September 2018). "NSE suspends trading on Skye Bank shares". Vanguard (Nigeria). Lagos. Retrieved 5 November 2018. 
  2. Polaris Bank (5 November 2018). "The Board of Directors of Polaris Bank Limited". Lagos: Polaris Bank Limited. Archived from the original on 16 December 2022. Retrieved 5 November 2018. 
  3. . Abuja.  Missing or empty |title= (help);
  4. . Abuja.  Missing or empty |title= (help);
  5. Iyatse, Geoff (2022-10-21). "Strategic Capital acquires 100 equity in Polaris Bank". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-11-01. 
  6. Unaudited Financial Report: September 2010 Archived January 4, 2011, at the Wayback Machine.
  7. Obinna, Chima (24 September 2018). "A Decade after, Like Lehman Brothers, Like Skye Bank?". This Day. Lagos. Retrieved 5 November 2018. 
  8. OMEJE, Chikezie (2018-09-22). "Skye Bank takeover: A journey from Afribank to Polaris Bank". The ICIR (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-09-06. 
  9. . Lagos.  Missing or empty |title= (help);
  10. "MainStreet Bank, Acquired by Polaris Bank Ltd. on October 31st, 2014 | Mergr". Mergr.com. 31 October 2014. Archived from the original on 20 August 2022. Retrieved 20 August 2022.