Priscilla Studd
Priscilla "Scilla" Studd (saájú ọdún 1887 si ọdún 1929, Omidan Priscilla Livingstone Stewart) jẹ́ ajíhìnrere ni ijọ alátẹnumó-ọmọ lẹ́yìn Krístì, o si jẹ ìyàwó ọ̀gbẹni Charles Studd.
Priscilla Livingstone (Stewart) Studd | |
---|---|
Missionary to China | |
Ọjọ́ìbí | Lisburn, Ireland |
Aláìsí | 1929 |
A bi i ni Lisburn, l'ẹba Belfast, ni ìlú Ireland, (eleyi ti o ti di apá ariwa ilẹ̀ Ireland l'ode oni) Priscilla Stewart gúnlẹ̀ ni ìlú Shanghai ni ọdún 1887 gẹ́gẹ́ bi ọ̀kan lára àwon ọgọrun ajíhìnrere ti iṣẹ́ iranṣẹ aarin gbungbun ilẹ China o si jẹ ọkan làra àwon ọ̀wọ́ ti o pọ jù ti o de papọ. Alaye fi idi rẹ múlẹ̀ wípé o fi ìwòjú ati ìṣe han gẹ́gẹ́ bi ọmọ ilẹ̀ Ireland pẹ̀lú ojú rẹ ti o jẹ aláwọ̀ buluu ati irun rẹ ti o jẹ alawọ omi wúrà. Lẹ́yìn ti o ti gbé́ fun ìgbà diẹ ni Shanghai, òun pẹ̀lú àwon obìnrin mẹta miran lọ bere si ṣe iṣẹ́ ni ilu Ta-Ku-Tang.