Professor Moshood Abiola Peller ( tí wọ́n bí ọdún 1941, ní Ìséyìn – ní Ọjọ́ kejì Oṣù kẹjọ, Ọdún 1997, Onípànù) jẹ́ Onídán orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti ọkàn lára àwọn Ògbóǹtarìgì Onídán ní ilẹ̀ Áfíríkà.[1][2][3]

Orúkọ bíbí rẹ̀ jẹ́ Fọlọ́runshọ Abíọ́lá, Peller lọ sí ilé-ìwé Mùsùlùmí ní Ìséyìn àti Ilé-ìwé Native Authority Primary ní Ìséyìn. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní má ṣe idán ní ọdún 1954 tí ó gbé dé Ìlú Ìbàdàn, Èkó àti Ọ̀yọ́ fún eré. Ní ọdún 1959, Ó yí iṣẹ́ ààyò rẹ̀ padà àti wí pé ó di aṣojú fún G.B.O àti padà wọ iṣẹ́ òwò. Ìfẹ́ rẹ̀ fún idán tẹ̀ síwájú àti ní ọdún 1964, ó lọ sí Ilé-ìwé magical arts in Índíà, ó lo oṣù méjìdínlógún ní ilé-ìwé náà àti lẹ́yìn tó parí, ó lọ gbé ní Liberia. Ní ọdún 1966, ó ní ìmúrasílẹ̀ àfihàn ní Federal Palace Hotel, Èkó. Wọ́n padà pa á ní ọdún 1997.

Àwọn ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. "Magicians Use Occultic Power To Perform Miracles - Prof Peller’s Son".
  2. Amadi, Ognanna; Njoku, Ben; Amaraegbu, Bridget; Sowolu, Loloa (June 5, 2010). "Like father like son Peller’s son speaks". Vanguard (Nigeria). http://www.vanguardngr.com/2010/06/like-father-like-son-pellers-son-speaks/. Retrieved January 27, 2016. 
  3. Bayo Onanuga (2000), People in the News, 1900-1999: A Survey of Nigerians of the 20th Century, Independent Communications Network Limited, p. 483