Qasem Soleimani
Qasem Soleimani tí wọ́n bí ní ọjọ́ kọkànlá oṣù kẹta ọdún 1957 jẹ́ ọ̀gágun àti olórí Ogun àṣírí orílẹ̀ èdè Iran láti ọdún 1998 títí di ọdún 2020 tí àwọn ọmọ ogun orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà pa á. Òun ni olórí ogun the Islamic Revolutionary Guard Corps (IRGC) lórílẹ̀ èdè Iran. [1]. Lọ́wọ́́lọ́wọ́ báyìí, ikú Qassem Soleimani tí fa ìbẹ̀rù-bojo sí gbogbo àgbáyé láti ìlérí àti ìrọ̀kẹ̀kẹ̀ ogun tí orílẹ̀ èdè Iran àti Amẹ́ríkà ń pè sí ara wọn. Èrò ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni wípé, bí àjọ àgbáyé, United Nations kò bá tètè pẹ̀tù sáwọ̀ náà, ó lè dogun àgbáyé kẹta. Lórí ikú Qassem Soleimani, orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà àti Iran gbé pẹ̀rẹ̀gí ogun kaná. [2] [3] [4]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "The second most powerful person in Iran: A profile of Qassem Soleimani". Sky News. 2020-01-03. Retrieved 2020-01-08.
- ↑ "The life of Qassem Soleimani, Iran's revered military mastermind who fought the US for years until he was killed in an airstrike". Business Insider Nederland. 2020-01-03. Retrieved 2020-01-08.
- ↑ Wolf, Zachary B.; Stracqualursi, Veronica (2020-01-07). "The evolving US justification for killing Iran's top general". CNN. Retrieved 2020-01-08.
- ↑ "https://time.com". Time. 1970-01-01. Archived from the original on 2020-01-08. Retrieved 2020-01-08. External link in
|title=
(help)