Rárà
Rárà jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ewì àbáláyè ni ilẹ́ ẹ̀ Yorùbá. Gẹ́gẹ́ bí mo tí ṣe ṣe àlàyé nínú ọ̀rọ̀ àkọ́sọ, agbègbè Ìbàdàn àti Ọ̀yọ́ ni irú ewì báyìí tí wọ́pọ̀. Òun ni ọ̀kan nínú àwọn ewì `tí a máa ń fi ń yin ẹnikẹ́ni tí a bá ń sun ún fún yálà ní ìgbà tí ó bá ń ṣe ìnáwó tàbí àríyá kan. Bí ó ti jẹ́ ohun tí a fí ń yin ènìyàn náà ni ó tún jẹ́ ohun tí a lè fi pe àkíyèsí ènìyàn sí ìwà àléébù tí ó ń hù. Bákan náà, rárà jẹ́ ọ̀nà kan tí a fi máa ń ṣe àpọ́nlé ènìyàn ju bí ó tí yẹ lọ, nígbà tí a bá sọ pé ó ṣe ohun tí ó dà bí ẹni pé ó ju agbára rẹ̀ lọ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ orúkọ ni a máa ń bá pàdé nínú un rárà ó sì dà bí ẹni pé àwọn orúkọ wọ̀nyí jẹ́ orúkọ àwọn ẹni àtijọ́ tí ó jẹ́ bí i baba ńlá ènìyàn tí ó ṣẹni sílẹ̀.
Nítorí pé ọ̀rọ̀ iyìn àti ẹ̀pọ́n la máa ń bá pàdé nínú un rárà, èyí máa ń mú inú àwọn ènìyàn tí ó bá ń gbọ́ rárà náà dùn, orí a sì máa wu. Ní ààrin orí wíwú àti yíyá báyìí ni àwọn ènìyàn tí à ń sun rárà fún yíò tí máa fún àwọn asunrárà náà ní ẹ̀bùn tí wọn bá rò pé ó tọ́ sí wọn.
Rárà sísun báyìí pé oriṣI méjì tàbí mẹ́ta ni agbègbè ibi tí wọn ti ń suún. OríṣI kan ni àwọn èyí tí obìnrin-ilé máa ń sun. tí àwọn obìnrin ilé wọ̀nyí kò ń ṣe gbogbo ìgbà. Ìgbà tí ọmọ-ilé kan ọkùnrin tàbí ọmọ-osu, tàbí ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó ilé bá ń ṣe ìnáwó ni wọn tóó sun ti wọn. OríṣI kejì nit i àwọn ọkùnrin tí ó máa ń lu ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀. Àwọn ẹni kẹta ni àwọn ọkùnrin tí kò ń lú sí tiwọn.
II. ÌGBÀ TÍ A MÁA Ǹ SUN RÁRÀ
Jákèjádò ilẹ̀ ẹ Yorùbá, ó ní ìgbà tí a máa ń sába ń kéwì. Gẹ́gẹ́ bí mo ti sọ nínú ọ̀rọ̀ àkọ́sọ àti bí òwe àwọn Yorùbá tí ó sọ wí pé “Ẹ̀ṣẹ́ kì í ṣẹ́ lásán”, bákan náà ni fún rárà, a kì í déédé sun rárà láìjẹ́ pé ó ni nǹkankan pàtàkì tí à ń ṣe.
Gẹ́gẹ́ bí a ti rí i àti bí a ṣe gbọ́ láti ẹnu àwọn asunrárà tí a wádìí lọ́dọ̀ ọ wọ́n, àwọn àsìkò tí a máa ń sun rárà jẹ àsìkò ti a bá ń ṣe àríyá tàbí àjọyọ̀. Gẹ́gẹ́ bí àwọn asunrárà Aláàfin ìlú Ọ̀yọ́ tí wo, ó jẹ́ ìwá àti ìṣe wọn láti máa lọ̀ ọ́ sun rárà fún Aláafìn ní àǹfin rẹ̀. Lẹ́hìn ti ààfin sísun fún yìí, wọn a tún máa sún tẹ̀lé ọba yìí bí ó bá ńlọ sí ìdálẹ̀ kan. Wọ́n ń ṣe èyí kí àwọn ẹni tí ọba náà kọjá ni ìlú u wọn lè mọ́ ẹni tí ń kọjá lọ.
Ní ìlú Ọ̀yọ́ àti Ìbàdàn, ó dà bí ẹni pé a ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ fún rárà sísun yìí. Ọjọ́ yìí ní à ń pè ní ọjọ́ ọ Jímọ́ọ̀ Ọlóyin. Ọjọ́ yìí máa ń pé ní ọjọ kọkàndílọ́gbọ̀n sí ara wọn. Ọjọ́ yìí ni á gbọ́ pé ó ṣe pàtàkì nínú ìkà oṣù àwọn Yorùbá. Ọjọ́ yìí ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdílé wá sí ààrin ìlú láti oko tí wọ́n ń gbé yálà láti wá ṣo ìpàdé e mọ̀lẹ́bí tàbí láti wá ṣe ohun pàtàkì míràn. Ní ọjọ́ yìí, àwọn ènìyàn máa ń pọ̀ nínú ìlú jú bí ó ṣe máa ń wà tẹ́lẹ̀ lọ.
Ní Ọ̀yọ́ ní ọjọ́ Jímọ́ọ̀ Olóyin yìí, àwọn asunrárà náà yíò máa káàkiri ilé awọn Ọ̀yọ́ Mèsì àti àwọn ìjoyé ìlú yókù. Lẹ́hìn ti èyí wọn ó padà sí àafin láti wá jókòó sí ojú aganjú. Níhìín ni wọn yíò tí máa sun rárà kí gbogbo àwọn àlejò tí ó bá ń lọ kí Aláàfin. Wọ́n ń ṣe èyí láti lè rí ẹ̀bùn gbà lọ́wọ́ àwọn àlejò náà; àti láti lè jẹ́ kí Aláàfin mọ irú àlejò tí ń bò.
Bákan náà a gbọ́ pé ní ayé àtijọ́ ní ìgbà tí ogun wọ́pọ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá, àwọn jagunjagun máa ń ní asunrárà tí í máa sun rárà tẹ̀ lé wọn bí wọn bá ńlọ sí ogun1. Mo rò pé wọ́n ń ṣe èyí láti lé fún àwọn jagunjagun náà ní ìṣírí. Bákan náà wọ́n a tún máa sọ fún wọn bí ó ti ṣe yẹ kí wọ́n ṣe lójú ogun.
Lẹ́hìn ti kí a sún rárà fún àwọn ọba, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà tí a tún ń sun rárà jẹ́ àwọn àsìkò ìnáwó tàbí àríyá. Ni ìgbà tí ènìyàn bá ń ṣe Ìgbéyàwó àwọn onírárà a máa sun rárà fún onínàwó náà. Fún àpẹẹrẹ ni ibi ìyàwó tí àwọn obìnrin bá ń sun rárà fún ẹni tí ń gbé Ìyàwó náà wọn ó máa wí báyìí:
Ẹ mọ̀mọ̀ ṣeun mì o
Torí ẹni tó ṣúpó
Opó laá póṣú
Èèyàn tó gbẹ̀gbà,
Aá pé n bẹ́gbà ló gbà.
Ògo dodo nìyàwó alẹ́ àná,
Ọmọ ‘Bísí Adé.
Ọmọ lójúu Lájùnmọ̀kẹ́,
Ọmọ Gẹ́gẹ́ọlá,
Abiamọ ọ̀ mi Àjàmú,
Ẹní gbé ‘yàwó ṣògo dodo”,
Ìgbà tí a tún máa ń sun rárà ni ibi ìnáwó ìsọmọ lórúkọ. Irú ìsọmọlórúkọ yìí gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tí a ṣe tìlù tìfọn. Bákan náà bí a bá ń sin òkú àgbàlagbà ó lè jẹ́ ìyá, bàbá, tàbí ẹ̀gbọ́n ẹni. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ibi tí a bá gbé ń ṣe nǹkan tí ó lè mú ìdùnnú lọwọ, yálà ilé ṣíṣí ní tàbí ìwuyè ni a ti i máa ń rí àwọn asunrárà.
Ní ayé ìsin yìí a tún máa ń rí àwọn asunrárà nì ìgbà tí àwọn ènìyàn bá ń ṣe ọdún. Nínú ọdún iléyá ti àwọn mùsùlùmí tàbí ọdún un kérésìmesì tí àwọn onígbàgbọ́, àwọn onírárà a máa káàkiri ilé àwọn ẹlẹ́sìn wọ̀nyi, láti kí wọn kú ọdún nípa rárà sisun. Àwọn ọlọ́dún wọǹyí yìò sì máa fún àwọn asunrárà náà lẹ́bùn. Àwọn asunrárà ọkùnrin tí ó máa ń fi rárà ṣe iṣẹ́ ṣe ni wọ́n máa ń ya ilé kiri láti sun rárà.
- S.E. Láníyan (1975), ‘Rárà’, DALL, OAU, Ifẹ̀, Nigeria.