Rélùwéè
Rélùwéè tí a tún mọ̀ sí ọkọ̀ ojú-irin jẹ́ ọ̀nà kan pàtakì tí ọmọnìyàn ṣàgbékalẹ̀ rẹ̀ láti fi ma ṣèrìnàjò láti ibì kan sí òmíràn. Ìyàtọ̀ rélùwéè sí ọkọ̀ ajúpópó ni wípé kìí rìn lójú títì tí a tẹ́ pẹrẹsẹ, àyà fi ojú irin tí a ti tó kalẹ̀ láti ibìkán sí ibòmíràn [1]
Àwọn irin tí wọ́n tó kalẹ̀ kí ọkọ̀ ojú-irirn yí ń gbà ni kìí fi bẹ́ẹ̀ ń mú ìnira dání pẹ̀lú lílọ bíbọ̀ ọkọ̀ náà lórí irin. Ilé-iṣẹ́ ọkọ̀ ojú-irirn ni ó ń ṣe alámójútó gbòkègbodò ìrìnà ọkọ̀ ojú-irin. [2] Ọkọ̀ ojú-irin yí ni ó ma ń lo ina mànà-máná, epo Diesel tàbí kí wọ́n lo kóòlù láti lè jẹ́ ọkọ̀ náà ó gbéra láti ibìkan sí òmíràn. Púpọ̀ àwọn ojú-irin tí ọkọ̀ yí ń gbà ma ń sábà alamí tó ń dúró bí màjàlà fún àwọn adarí ọkọ̀ reluwé náà. Ọkọ̀ rélùwéè fini lọ́kàn balẹ̀ bí a bá ń sọ nípa ìrìnà ọkọ̀. Ọkọ̀ ojú ìrírí ní agbára láti kò èrò tó pọ̀ gidi lásìkò kan náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé kò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn láti ló, ó sì gbówó lórí yàtọ̀ sí àwọn ọkọ̀ tókù.
Àwọn itọ́ka sí
àtúnṣe- ↑ "Railways". World Bank. 2016-08-30. Retrieved 2023-01-07.
- ↑ Yi, Sirong (2018). "Strengthening of the Railway Transport Capacity". Principles of Railway Location and Design. Elsevier. pp. 473–534. doi:10.1016/b978-0-12-813487-0.00007-x.