Radio Congo Belge (French, "Belgian Congo Radio") jẹ́ ilé isé rédíò kan ní Belgian Congo (tí a wá padà mọ̀ sí Democratic Republic of the Congo) tí ó kó ipa nínú ìdàgbàsókè àti ìpolongo orin Congolese rumba káàkiri Áfríkà lẹ́yìn of Ogun àgbáyé kejì.

Wọ́n dá Radio Congo Belge kalẹ̀ ní Léopoldville (tí a mọ̀ sì Kinshasa) gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti ma fún àwọn òyìnbó tí ó ń gbé ní Congo àti German nígbà náà ní ròyìn nígbà Ogun Àgbáyé Ẹlẹ́ẹ̀kejì. Ó gbé ròyìn jáde fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ọjọ́ kínní oṣù Kẹ̀wá ọdún 1940.

Gégé bí onítàn Gary Stewart ṣe sọ, Radio Congo Belge, pẹ̀lú Radio Brazzaville àti Congolia, "kó ipa nínú sí ṣàfihàn oríṣiríṣi irú àwọn orin ní etí odò Odò Congo".[1]

Lẹ́yìn òmìnira Congo-Léopoldville ní ọdún 1960, wọ́n yí orúkọ ìkànnì náà padà sí Radiodiffusion Congolaise ("Congolese Radio Broadcasting"). Àwọn ìkànnì rédíò mìíràn tí ó wà nígbà náà ni OTC àti Radio Léopoldville.

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Stewart 2000, p. 19.