Rafiat Folakemi Sule (tí wọ́n bí ní 3 August 2000), jé agbábọ́ọ̀lù ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó ń gbá bọ́ọ̀lù náà ní ipò àgbásíwájú fún A.S.D. Pink Sport Time,[1] ní Italian Serie A. Ó fìgbà kan wọ aṣọ ti ẹgbẹ́ Rivers Angels, ó sì jẹ́ agbábọ́ọ̀lù tó ju ọ̀pọ̀ bọ́ọ̀lù sáwọ̀n fún ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Wọ́n ṣàpejúwe rè gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ní ojú àṣá tó lè rí bọ́ọ̀lù tó máá wọlé sáwọ̀n láti ọ̀nà jínjìn.[2]

Rafiat Sule
Personal information
OrúkọRafiat Folakemi Sule
Ọjọ́ ìbí3 Oṣù Kẹjọ 2000 (2000-08-03) (ọmọ ọdún 24)
Ibi ọjọ́ibíKaduna, Nigeria
Playing positionForward,
Club information
Current clubPink Sport Bari
Number17
Senior career*
YearsTeamApps(Gls)
Jagunmolu FC
2015–2017Bayelsa Queens24(31)
2017–2019Rivers Angels27(17)
2019–2020Bayelsa Queens10(11)
2020–Pink Sport Bari13(0)
National team
2018-2019Nigeria national team5(3)
* Senior club appearances and goals counted for the domestic league only. † Appearances (Goals).

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́

àtúnṣe

Ní oṣù karùn-ún ọdún 2015, Sule ṣe àwítúnwí ìgbàgbọ́ rè nínú àwọn ajùmọ̀gbábọ́ọ̀lù rẹ̀ àti alámòójútó wọn fún ìdíje ti wọ́n ń gbá nígbà náà.[3] Ó sọ ọ́ di mímọ̀ pé ó dá òun lójú pé àwọn ọmọ ẹgbé Bayelsa Queens máa parí ìdíje náà pẹ̀lú ipò tó dára.[3] Lásìkò ìdíje ti ọdún 2015, Sule ju bọ́ọ̀lù mọ́kànlá sáwọ̀n.[4] Ó fi àṣeyọrí yìí sọrí bàbá rẹ̀ tó ti dolóògbé àti sí àwọn akẹgbe rè fún ìwúnilórí wọn, ó sì ṣàpejúwe àṣeyorí náà gẹ́gẹ́ bí i ohun tó wá lójijì torí òun ò sí ní ipa ọnà láti fọwọ́ ba ohun tí òun ń fé. Sule tún rí àṣeyọrí yìí gẹ́gẹ́ bí àjùmọ̀ṣe òun ̀ti àwọn akegbẹ́ rẹ̀.[5] Ní ọdún 2016, ìkópa rẹ̀ nínú ẹgbé Bayelsa Queens mu kí wọ́n yàn án fún agbábọ́ọ̀lù tó dára jù lọ fún osụ̀ karùn-ún ọdún 2016.[6] Ní oṣù kẹta ọdún 2017, ẹgbẹ́ RIvers Angels mú kí Sule pẹ̀lú, Cecilia Nku, Halimatu Ayinde àti Tochukwu Oluehi tọwọ́ bọ̀wé pẹ̀lú wọn.[7]

Ní àpérò Ladies in Sports conference ti ọdún 2017, wọ́n fún Sule ní àmì-ẹ̀yẹ fún agbábọ́ọ̀lù tó dára jù lọ fún ìdíje tó kọjá.[8][9]

Ó darapọ̀ mọ́ Italian Serie A, ti ẹgbẹ́ A.S.D. Pink Sport Time tó wà ní Bari. Èyí wáyé ní oṣù kẹjọ ọdún 2020.[1]

Àmì-ẹ̀yẹ

àtúnṣe
  • 2015 top scorer
  • 2016 top scorer
  • Nigeria Pitch Awards - Most valuable player in 2016 Nigeria Women Premier League[10]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 "Sule Rafiat Folakemi Archivi". 
  2. "New blood set to booast Flamingoes". Super Sports. November 2015. Retrieved 2017-08-07. 
  3. 3.0 3.1 "Rafiat Sule : Bayelsa Queens Are In Confident Mood". allnigeriasoccer.com. May 10, 2015. Retrieved 2017-08-07. 
  4. "Young Queen Sule dedicates award". Super Sport. October 2015. Retrieved 2017-08-07. 
  5. "Bayelsa Queens Striker, Rofiat Sule Dedicates NWPL Golden Boots Award To Late Dad, Coaches". Sahara Reporters sports. October 2015. Retrieved 2017-08-07. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  6. "Igbinovia, Five Others Get Player Of The Month Award Nomination". allnigeriasoccer.com. Retrieved 2017-08-07. 
  7. "NWABUOKU, NKU, AYINDE AND OLUEHI JOIN RIVERS ANGELS". Goal.com. March 2017. Retrieved 2017-08-07. 
  8. "Falode, others task Ladies in Sports on development". Eagle Online. 12 June 2017. Retrieved 2017-08-07. 
  9. "Ladies In Sports Chat Way For Women Sports". Sports Day. 2017. Archived from the original on 2017-10-19. Retrieved 2017-08-07. 
  10. "PITCH AWARDS: Oshoala, Ndidi, Ikeme emerge winners". Ripples Nigeria. 2017. Retrieved 2017-08-07.