Rose Okoji Oko
Rose Okoji Oko (27 Kẹsán 1956 – 23 March 2020) je oloselu áti asofin agba(Senator) Naijiria nigba ayé rè. Ó jẹ́ okàn lara àwon ìgbìmọ̀ aṣòfin ìjọba àpapọ̀ lábé ẹgbẹ́ òṣèlú People’s Democratic Party (PDP),ó si ṣe asojú agbegbe Yala/Ogoja ní ilé ìgbìmọ̀ asòfin keje ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1] Òun ni obinrin akoko ti ayan si ọfiisi gegebi aṣoju agbegbe rẹ, a yan si ipo ní May 2011. O jẹ ara àwon Senato ti o ṣoju fun awọn ènìyàn ariwa Cross river.[2] Ni May 2015, a yan sipo gege bi obinrin akoko tí o se asoju Agbegbe rẹ.
Rose Okoji Oko | |
---|---|
Senator àgbègbè àríwá Cross River | |
In office June 2015 – March 2020 | |
Constituency | Cross River North |
Member, House of Representatives | |
In office June 2011 – June 2015 | |
Constituency | Yala/Ogoja |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | ìpínlẹ̀ Cross River, Nàìjíríà | 27 Oṣù Kẹ̀sán 1956
Aláìsí | 23 March 2020 London, UK | (ọmọ ọdún 63)
Àwọn òbí | Agbo Ojeka |
Education | SSC, B.A in Linguistic, M.A in Linguistic, PhD in Linguistic, M.B.A |
Alma mater | WTC Primary School Enugu, Federal School of Art and Science Ogoja, University of Calabar, University of Wisconsin, Management Institute of Canada Yunifásitì ìlú Port Harcourt, |
Àárò Ayé ati Èkó rè
àtúnṣeA bi Bose Okoji ni 27 September 1956 si inú idile Thomas Ojeka(Baba) ati Agbo Ojeka(Momo) ni ìlú Opkoma, agbegbe ìpinlè ijoba Yala , ìpínlè Cross River. O jé omo akoko ninu omo méjì tí ìyá rè bí, ósì jé omo keje nínú omo medogun tí bàbá rè bí. Ó gba ìwé ẹ̀rí akobere rè ní ilé-ìwé women training college, ìlú Enugu. Ó pada kàwé ní Yunifásitì tí ìlú Calabar láti gba àmì-èye Linguistics, léyìn náà ni ó tèsíwájú Yunifasiti ti Wisconsin, Madison, USA. [2]
Òsèlú
àtúnṣeNi ọdun 1999 Rose darapo mó àwon egbé tí ó dá ẹgbẹ People's Democratic Party (PDP) kalè ní Ìpínlè Cross River. Laarin ọdun 2002 sí 2004, lẹhin ti o ti fẹhinti kuro ni iṣẹ ìjoba, o se iforukọsilẹ egbé oselu National Democratic Party (NDP) sí Ipinle Cross River. Ni ọdun 2003 Naijiria ṣe idibo ijọba tiwantiwa akọkọ lati igba ti ìjoba tiwantiwa gba ipò lowo ìjoba ologun, Okoji Oko sì dije fun ile igbimọ aṣofin agba, láti se asoju ariwa ipinlẹ Cross River State lábé egbé oselu NDP, o fìdíremi nínú idije náà, oludije labe egbé oselu PDP ló sì jawe olubori. [3]
O tesiwaju gege bi alaga igbimo awon alagbese fun egbe NDP titi di odun 2007, nigba to dije ninu ibo ijoba tiwantiwa eleekeji lorile-ede yii gege bi oludije gomina fun ipinle Cross River, idije to fabo lowo oludije PDP. O tún díje ní odun 2007 láti di Gomina ìpínlè Cross River sùgbón o fìdíremi sí oludije lábé egbé oselu PDP. Ni ọdun kanna, ó darapo mó egbé oselu PDP. O padà díje sí ipò Sanato ni odún 2015 láti soju apa ariwa ìpínlè Cross River, ó sì jawe olubori, ní odun 2019, a tun yan si ipò náà. [4]
Ikú rè
àtúnṣeRose Okoji se alaisi ni 23 March, 2020 ni ile-iwosan kan ni Ilu Lọndọnu, UK léyìn aìsàn osù kan [5]
Àwon Ìtókasí
àtúnṣe- ↑ "UPDATED: Another Senator, Rose Oko, is dead". Vanguard News. 2020-03-24. Retrieved 2022-05-19.
- ↑ 2.0 2.1 "Rose Oko biography, net worth, age, family, contact & picture". Nigeria Business Directory - Find Companies, People & Places in Nigeria. 1956-09-27. Retrieved 2022-05-19.
- ↑ "Biography Of Rose Okoji Oko". Media Nigeria. 2018-06-06. Archived from the original on 2022-11-29. Retrieved 2022-05-20.
- ↑ "Rose Oko exemplified the spirit of unity in the 9th Senate – Lawan - P.M. News". PM News Nigeria. 2020-10-07. Retrieved 2022-05-20.
- ↑ Ayado, Solomon (2020-03-24). "Nigerian Senator Rose Okoji Oko dies in UK". Businessday NG. Retrieved 2022-05-20.