Roselle juice
Roselle juice tí a mọ̀ sí bissap, wonjo, foléré, dabileni, tsobo, zobo, siiloo, soborodo tàbí Sobolo ní àwọn apá ibìkan ní Áfíríkà,[1] karkade ní Egypt, sorrel ní Caribbean, àti agua de Jamaica ní Mexico, jẹ́ ohun mímu tí a ṣe láti ara òdòdó ti roselle, ọmọ Hibiscus. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lápapọ̀ "ohun mímu" máa ń dùn ó sì máa ń tutù, ó jẹ́ egbòogi nígbà tí wọ́n bá sì bù ú ní gbígbóná wọ́n tún lè pè é ní hibiscus.
Bottles of sobolo | |
Alternative names | Bissap, tsobo, sobolo, sorrel |
---|---|
Serving temperature | Cold |
Main ingredients | Roselle flowers, water, sugar |
Variations | Ginger |
Àdàkọ:Wikibooks-inline
|
Ìsàpèjúwe
àtúnṣeRoselle juice, tí wọ́n sábàá máa ń gbé sínú ẹ̀rọ a-mú-nǹkan-tútù, jẹ́ ohun mímu tí ó dára tí a máa ń rí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè Ìwọ-Oòrùn Áfíríkà àti Caribbean.[2][3] Ó jẹ́ ohun mímu aláwọ̀ pupa. Àwọn Burkinabes, Senegalese, àti Ivorians ń pè é ní bissap, àwọn Nigerians ń pè é ní zobo nígbà tí Ghanaians ń pè é ní Zobolo.[4] Ó dà bí gírèpù lẹ́nu àti bí júìsì kékeré, wọ́n sì lè bù ú pẹ̀lú ewé míǹtì. Ó tún lè di mímu pẹ̀lú ohun aládùn tí ènìyàn bá yàn láàyò - - nígbà mìíràn pẹ̀lú ọsàn tàbí jíńjà, ọ̀pọ̀n òyìnbó, tíì ewéko, vanilla, àti àwọn mìíràn .[5] Ní Ghana, Nigeria, àti Senegal, roselle juice máa di mímu ní tútù, ṣùgbọ́n ní Egypt, wọ́n máa ń mu ú ní lílọ́wọ́rọ́.[6]
Àǹfààní ìlera
àtúnṣeRoselle juice, tí ó ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí egbògi, ti di fífi hàn pé ó máa dènà ẹ̀jẹ̀ ríru ó sì máa ń dín ìfúnpá gíga kù.[7] Ó tún ní ìpele vitamin C tí ó ga, a máa ń lò ó láti ṣe ìtọ́jú òtútù ó sì tún máa ń ṣe àlékún fún àgọ́ ara.[8][9] Àwọn ìwádìí kan tún ti fi ìṣe a-dènà-ààrùn hàn.[10]
Zobo
àtúnṣeZobo jẹ́ ohun mímu ìbílẹ̀ ní Nàìjíríà. Wọ́n ṣe é láti ara ewé hibiscus gbígbẹ àti àwọn èròjà mìíràn.[11] Wọ́n sábàá máa ń ta ohun mímu náà ní ilé oúnjẹ àti ní ẹ̀gbẹ́ títì. Ohun mímu Zobo máa ń di mímu níbi ayẹyẹ ó sì lè jẹ́ mímu nílé fún àwọn mọ̀lẹ́bí. [12][13][14][15]
Àgbéyẹ̀wò
àtúnṣeOhun mímu Hibiscus máa ń di ṣíṣe nípa gbígbé ewé hibiscus kaná pẹ̀lú ginger, garlic fún bíi wákàtí kan.[16] Wọn máa ń mu ún ní gbígbóná tàbí tútù ó dá lórí bí ọjọ́ bá ti rí ní agbègbè tí wọ́n bá ti ṣe é. Àwọn èròjà mìíràn tí a lò láti ṣe ohun mímu zobo ni nutmeg, cinnamon, cloves, òrom̀bó, ọ̀pọ̀n òyìnbó àti àwọ̀ àtọwọ́dá. Wọ́n máa ń jọ àwọn ẹ̀rún tí yóò sì ku ohun mímu zobo nìkan. Ohun mímu roselle ní adùn tí ó jọ ti ohun mímu cranberry ó sì máa ń jẹ́ àwọ̀ pupa.[17][18][19]
Ohun mímu zobo máa ń di rírọ sínú kòǹdoro mímọ́ èyí tí ó lè di dídè pa láti ba à lè dènà bíbàjẹ́ .[20][21]
Hibiscus sabdariffa
àtúnṣeÈyí ni èròjà tó ṣe pàtàkì jù lọ tí à ń lò láti ṣe zobo, ẹ̀fọ́ eléwé ni tí ó fara jọ spinach tí ó ṣẹ̀ wá láti West Africa.[22] Hibiscus sabdariffa, tí a tún mọ̀ sí roselle, jẹ́ egbògi oní ọdọọdún tí ó lè di gbíngbìn títí ọdún máa fi parí pàápàá jù lọ láàárín oṣù kọkànlá àti oṣù kẹrin ọdún tó ń bọ̀.
Hibiscus sabdariffa tún jẹ́ mímọ̀ sí spinach dock, sour grass, tàbí sour grabs.[23]
Àwọn orúkọ mìíràn
àtúnṣeZobo tún jẹ́ mímọ̀ sí hibiscus tea, hibiscus drink àti roselle drinks nítorí pé ohun mímu náà di rírí láti ara ewé hibiscus. Tí a tún mọ̀ sí Chapman ìbílẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí àwọn èso yòókù àti àwọn àwọ̀ àtọwọ́dá ti di fífi sí i. Látàrí kíkorò ohun mímu zobo, wọ́n máa ń pè é ní tíì kíkorò bákan náà.[24][25]
Ìselọ́jọ̀
àtúnṣeỌ̀nà ìselọ́jọ̀ méjì ló wà tí a máa ń lò láti ṣe tíì zobo tea, àwọn ọ̀nà àbáláyé ni nutmeg, lime àti cloves èyí tí ó máa ń jẹ́ kí ohun mímu náà wà lọ́tun.[26][27]
Sodium benzoate ní ìfọkànsí ti ìdá 0.1% tàbí àpòpọ̀ citric acid àti magnesium sulfate ni àpapọ̀ kẹ́míkà tí ó di lílò ní ṣíṣe zobo lọ́jọ̀ fún ọjọ́ pípẹ́ tí yóò sì jẹ́ kí bọ́ lọ́wọ́ kábọ̀nù. Ìselọ́jọ̀ ti àtọwọ́dá máa ń di lílà pẹ̀lú fruit juice láti ba à lè ṣe ìkorò rẹ̀ lọ́jọ̀ lásìkò ìgbéjáde rẹ̀.[28][29][30][31][32]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Sobolo (Bissap Drink)". Retrieved 19 March 2015.
- ↑ "GES investigates teacher's assault of student who criticised her 'sobolo' drink". MyJoyOnline.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-02-17. Retrieved 2020-06-07.
- ↑ Online, Peace FM. "Woman Quits Journalism To Sell 'Sobolo'". www.peacefmonline.com. Archived from the original on 2020-06-07. Retrieved 2020-06-07.
- ↑ Agyeman, Adwoa (2020-02-17). "GES investigates teacher's assault of pupil over 'sobolo' drink". Adomonline.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-06-07.
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs namedinfobox2
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs named:02
- ↑ Hopkins, A. L.; Lamm, M. G.; Funk, J. L.; Ritenbaugh, C. (2013). "Hibiscus sabdariffa L. In the treatment of hypertension and hyperlipidemia: A comprehensive review of animal and human studies". Fitoterapia 85: 84–94. doi:10.1016/j.fitote.2013.01.003. PMC 3593772. PMID 23333908. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=3593772.
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs named:12
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs named:03
- ↑ Oboh, G.; Elusiyan, C. A. (2004). "Nutrient Composition and Antimicrobial Activity of Sorrel Drinks (Soborodo)". Journal of Medicinal Food 7 (3): 340–342. doi:10.1089/jmf.2004.7.340. PMID 15383229.
- ↑ "How To Make Zobo Drink In Ten Easy Steps". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2017-08-31. Retrieved 2022-09-05.
- ↑ "Benefits of taking Zobo". The Nation Newspaper (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-10-02. Retrieved 2022-07-01.
- ↑ "How To Make Zobo Drink In Ten Easy Steps". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2017-08-31. Retrieved 2022-07-01.
- ↑ "How to harness health benefits of zobo drink". Daily Trust (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-03-16. Retrieved 2022-07-01.
- ↑ Online, Tribune (2021-02-18). "Why regular consumption of zobo drink with hypertension medication should be avoided —Expert". Tribune Online (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-07-01.
- ↑ "How To Make Zobo Drink In Ten Easy Steps". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2017-08-31. Retrieved 2022-09-05.
- ↑ "How to prepare zobo drink". The Nation Newspaper (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-07-20. Retrieved 2022-07-01.
- ↑ onnaedo (2015-09-08). "How to make Zobo drink". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2022-07-01. Retrieved 2022-07-01.
- ↑ "Goodlife introduces another drink; Zobo Ginger variant - Premium Times Nigeria" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-03-02. Retrieved 2022-07-01.
- ↑ "FIIRO has developed over 250 food processing techs, says DG". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-11-12. Retrieved 2022-07-01.
- ↑ "Nigerian author hawks zobo drink on the streets - Premium Times Nigeria" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-02-23. Retrieved 2022-07-01.
- ↑ "Roselle - plant". Encyclopedia Britannica. Revised and updated by Melissa Petruzzello. Archived from the original on 2022-04-20.
- ↑ Online, Tribune (2022-03-05). "Chilled zobo drink for the weather". Tribune Online (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-07-01.
- ↑ "Goodlife Zobo Ginger drink unveiled during Showtime Friday". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-03-01. Retrieved 2022-07-01.
- ↑ omotolani (2022-03-03). "7 health benefits of zobo drink (Hibiscus tea)". Pulse Nigeria. Retrieved 2022-07-01.
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs named:22
- ↑ "Physical and chemical preservation of zobo drink". ResearchGate. https://www.researchgate.net/figure/Effects-of-physical-and-Chemical-preservation-methods-on-Zobo-drink_tbl2_305278715.
- ↑ "Making Money From Zobo Drink Production". Independent Newspaper Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-05-20. Retrieved 2022-07-01.
- ↑ "Preservatives in zobo drink". ResearchGate. https://www.researchgate.net/publication/305278715.
- ↑ "My Sobolo". Graphic Online (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-06-07.
- ↑ Online, Peace FM. "Health Benefits Of Sobolo". www.peacefmonline.com. Archived from the original on 2020-06-07. Retrieved 2020-06-07.
- ↑ "Reasons to drink more Sobolo". Ghana Web. 17 March 2017.