Rozena Maart (tí wọ́n bí ní ọdún 1962[1]) jẹ́ òǹkọ̀wé ilẹ̀ South Africa, àti ọ̀jọ̀gbọ́n tó ń gbé ní ìlú Durban lọ́wọ́lọ́wọ́. Òun ni olùṣàkóso fún Centre for Critical Research on Race and Identity. Ó gbajúmọ̀ fún ìwé kíkọ rẹ̀, àti àwọn iṣẹ́ rẹ̀ lórí ẹlẹ́yàmẹyà àti ìwà-ipá sí àwọn obìnrin. Ó ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí i olùkọ́ káàkiri ilẹ̀ Canada, United States àti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ní àgbáyé.

Ìgbésí ayé rẹ̀

àtúnṣe

District Six ní ìlú Cape Town, ní South Africa ni wọ́n bi sí. Wọ́n fi ipá lé ẹbí rẹ̀ kúrò ní District Six ní ọdún 1973 látàri àṣẹ ìjọba ti ọdún 1987. Nígbà tí ó wà ní ọmọdún mẹ́rìnlélógún (24), wọ́n yàn án fún àmì-ẹ̀yẹ "Woman of the Year" tí wọ́n ṣe ní Johannesburg, fún iṣẹ́ rè lórí títako ìwà ipá sí àwọn obìnrin, àti fún bíbẹ̀rẹ̀ ẹgbẹ́ Black feminist organization ní Cape Town, pẹ̀lú obìnrin mẹ́rin àti Women Against Repression (WAR).

Ó kó lọ sí ìlú Canada ní ọdún 1989, ó sì ṣe àgbéjáde ìwé ewì rẹ̀ àkọ́kọ́ ní ọdún 1990, tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Talk About It!. Ó gba àmì-ẹ̀yẹ ti Journey Prize ní ọdún 1992 fún ìwé ìtàn kékeré rẹ̀, ìyẹn ìwé "No Rosa, No District Six", tó padà hàn nínú apá kejì ìwé náà, ìyẹn "Rosa's District Six." Ó jẹ́ òǹkọ̀é fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé, ewì, ìwé ìtàn kékeré àti ìwé adálórí ìtàn gidi. Èyí tó kọ gbẹ̀yìn ni The Writing Circle, tí ó tẹ̀ jáde ní ọdún 2007 (TSAR Publications), tí wọ́n sì fi ṣe fíìmù àgbéléwò. Ìwé rẹ̀, Rosa's District Six jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìwé tó ń tà wàràwàrà ní Canada ní ọdún 2006, àti ní HOMEBRU lọ́dún-un 2006, ní South Africa.

Ó gba oyè PhD láti University of Birmingham, U.K. (1993–1996) Centre for Cultural Studies.[2]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Àdàkọ:Cite LAF
  2. "Resume | Rozena Maart". Archived from the original on 2014-12-23. Retrieved 2014-12-14.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)