Silébu ni ègé ọ̀rọ̀ tí ó kéré jùlọ tí a lè pè jáde ní ẹnu ní orí ìsẹ́mií kan ṣoṣo. Iye ibi tí ohùn bá ti jẹ yọ nínú ọ̀rọ̀ kan ní yóo fi iye sílébù tí ọ̀rọ̀ náà ní hàn. Bí àpẹẹrẹ:

Kú - sílébù kan - Ibi kan soso ni ohùn ti jẹ yọ (Ohun òkè)

Ì-wé - sílébù méjì - Ibi méji ni ohùn ti jẹ yọ. (Ohùn ìsàlẹ̀ àti òkè)

Wọ́n ti dé.- sílébù mẹ́ta - Ibi mẹ́ta ni ohùn ti jẹ yọ (Ohùn òkè, àárín àti òkè).

Ìhun Sílébù

àtúnṣe

Apá méji ni ó wà nínú ìhun sílébù. Apá bẹ́ẹ̀ nìwọ̀nyí:

Odò Sílébù

àtúnṣe

Èyí ni ipín tí a máa ń gbọ́ jù lọ tí a bá pe sílébù síta. Òun niagbáterù ohùn nínú ihun sílébù. Kò sí sílébù tí ki í ní odò nínú ihun rẹ̀. Fáwẹ̀lì tàbí kọ́ńsónánti àránmú aṣesílébù 'n' ni wọ́n ń dúró bíi odò sílébù. Àpeere:

Ì-wé = 'i' àti 'é' ni odò sílébù

Apààlà Sílébu

àtúnṣe

Èyí ni àwọn iró tí a ki í gbọ́ ketekete tí a bá pe ọ̀rọ̀ síta. Kọ́ńsánánti ni ó máa ń dúró bíi apààlà sílébù. Àpeere: Ì-wé = 'w' ni apààlà sílébù Ì-tàn = 't' ni apààlà sílébù dù-n-dú = 'd' àti 'd' ni apààlà sílébù.

Ara apá méji yií ni abẹ̀rẹ̀ àti apẹ̀kun sílébù ti ṣú yọ. Àpẹẹrẹ:

(i) Abẹ̀rẹ̀ Sílébu: Èyí ni iró tó bere sílébu. Wón lè jé kóńsónántì tàbí fáwèli. Àpẹẹrẹ: Kan-ga = 'k' àti 'g' ni abẹ̀rẹ̀ sílébù.

(ii) Apẹ̀kun Sílébu: Èyí ni iró fáwẹ̀lì tí ó parí sílébù. Àpẹẹrẹ: wá = 'á' ni apẹ̀kun sílébu kún = 'ún' ni apẹ̀kun sílébù.

Ẹ̀yà ìhun sílébu

àtúnṣe

Oríṣi ẹ̀yà ìhun sílébu mẹ́ta ni ó wà ní èdè Yorùbá. Ẹ̀yà ìhun sílébù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni àfihàn báyií: F, KF, N: F (Silébù onífáwẹ̀lì kan); KF (Sílébù alákànpọ̀ kọ́ńsónánti àti fáwẹ̀lì); Ń (Kọ́ńsónánti àránmúpe aṣesílébù). Bí àpeere: àlàyé (à-là-yé) F KF KF dùndú (dù-n-dú) KF N KF

Sílébù ẹlẹ́yọ Fáwẹ̀lì

àtúnṣe

Sílébù lè ní ègé iró kan ṣoṣo nínú ihun. Àpeere:

Ìhun ọ̀rọ̀ ẹlẹ́yọ sílébù; Alàyé àti Àpẹẹrẹ...

(i) Ẹyọ fáwẹ̀lì kan ṣoṣo lè dúró bíi sílébù: (F)

(ii) Àkànpọ̀ kọ́ńsónánti àti fáwèli le dúró bíi sílébù: (KF)

(iii) Ẹyọ kọ́ńsónánti àránmúpè aṣesílébù lè dá dúró bíi sílébù. (N) Kọ̀nkọ̀ = kọ̀-n-kọ̀ gbangba = gba-n-gba bànkù = bà-n-kù Bánkólé = Bá-n-kó-lé Bánké = Bá-n-ké géndé = gé-ń-dé sóńsó = só-ń-só síńdódó = sí-ń-dó-dó

Ọ̀rọ̀ ọlọ́pọ̀ sílébù

àtúnṣe

Ìwọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n ní ju sílébù kan lọ nínú ìhun. Ìpín wọn sí iye sílébù àti ihun wọn.

Onísílébù Méjì

Adé = A-dé - f-kf ; Ṣùgbọ́n = ṣù-gbọ́n - kf-kf

Onísílébù mẹ́ta

Nǹkan = N-ǹ-kan - k-n-kf; Ọ̀gẹ̀dẹ̀ = ọ̀-gẹ̀-dẹ̀ - f-kf-kf

Onísílébù mẹ́rin

Àpẹẹrẹ = à-pẹ-ẹ-rẹ - f-kf-f-kf; Ọ̀kọ̀ọ̀kan = ọ̀-kọ̀-ọ̀-kan - f-kf-f-kf

Onísílébù márùn-ún

Àkátàǹpò = à-kà-tà-ǹ-pò - f-kf-kf-n-kf; Alagbalúgbú = a-la-gba-lú-gbú = f-kf-kf-kf-kf

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe