S.M. Raji àti J.I. Ogunranti
Àkójọ̀pọ̀ orin Ifá Ajẹmọ́dù Ojú-Ìwé 91-110.
àtúnṣeLílé: Olówó tutu dodo ó ó ó
Ẹ̀là tutu nini in in.
Ilé Olúwẹri kì í gbóná
Ègbè: Olówó tutu dodo ó ó ó,
Ẹ̀là tutu nini in in,
Ilé Olúwẹri kì í gbóná
Orin Yorùbá Ojú-Ìwé 1-3.
àtúnṣeOrin ni èso àṣà ìsẹ̀ǹbáyé àti ìtàn àwùjọ ènìyàn. Káàkiri ilẹ̀ adúláwọ̀ ni ẹ̀mí orin àti ijó ti jẹ́ ẹ̀mí ìgbésí ayé. Sọ́sọ́sọ́ ni ìrinlẹ̀ àti ìmúnilọ́kàn wọn máa ń wọ gbogbo ìgbésí ayé àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ẹnì kọ̀ọ̀kan, ní ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ àti ní àwùjọ. Orin rí bí i díńgí tí a fi ń tún ìwà ènìyàn ṣe.
Orin Ifá Ojú-Ìwé 4-5.
àtúnṣeOríṣìíríṣìí ọ̀nà ni a le gbà mọ ohun tí à ń pè ní orin Ifá. Orin Ifá ni orin tí Ọ̀rúmìlà máa ń kọ nígbà ayé rẹ̀. Bí Baba ń lọ, bí ń bọ̀, ẹnu rẹ̀ kì í dákẹ́. Bí ò ki Ifá, yóò máa sun Ìyẹ̀rẹ̀-Ifá. Bí ò sun ìyẹ̀rẹ̀-Ifá, yóò máa kọ orin Ifá.
Òrúnmìlà àti orin Ifá 6-7 Kò sí bí a óò ti perí ajá tí a kò ní perí ìkòkò tí a fi ṣè é. A ò le sọ̀rọ̀ nípa orin-Ifá kí á yọ ti Ẹ̀dú sílẹ̀. Bí Ọbàtálá; Ọbàtárìṣà; Ọba Tapatapa tí í bá wọn gbóde ìrànjé ti ní orin tirẹ̀ náà ni Orò: Yínni-yínni gbín-ín-kin; Ọ̀gọ̀gọ̀ rumọ̀-rumọ̀.Ó rumọ̀ láyé. Ó tún rumọ̀ lọ́run ní orin tí wọn fi ń yìn ín.
Ìwúlò orin Ifá Ojú-Ìwé 8-9. Ohùn ẹnu Yorùbá tó dùn, tó dún, tó sì jinlẹ̀ ni Orin Ifá. Ẹlòmìíràn le gbàgbé ara rẹ̀ síbi tí ó bá ti ń wòran eré-Ifá. Síṣe-léré rẹ̀ ni kò tó wò ni? Ìwọ́hùn inú orin ibẹ̀ ni ò tó wò ni? Àbí àwọn ọ̀rọ̀ kàǹ-kà tí ń kọ́ni lọ́gbọ́n tí ó kún inú rẹ̀ fọ́fọ́fọ́?
Àkóónú inú orin Ifá Ojú-Ìwé 10. Àkóónú orin Ifá kò gbọdọ̀ kọjá àwọn nǹkan tó ń bẹ láàrin àwùjọ tí bí i. Àwọn nǹkan bí ọ̀rọ̀ ìbà jíjú, oríkì, ètò ìṣèlú, èto owó àti ohun mìíràn tó jẹ àwọn ènìyàn lógún, àwọn nǹkan tó jẹ́ bárakú fún wọn, ìmọ̀ràn àti àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ àti èyí tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yin.
Ìgbékalẹ̀ orin Ifá Ojú-Ìwé 11. Àwọn tó ń fi ojú ààtò wo lítírésọ̀ sọ pé kò sí ohun tó dára tí kò ní ààtò tó dára. Orin náà ní ẹjẹ́wọ̀n-ọ́n bí a bá fẹ́ kó dùn, kó dún, kó sì pẹ́ lọ́kàn ẹni. Ènìyàn ò gbọdọ̀ máa to nǹkan lódìlódì. Ẹni tó bá gbé ìyá igbá lé ọmọrí igbá tit ò ó lódì.
Èwọ́ Ojú-Ìwé 12. Irú ẹ̀wọ́ ìlù yìí ni à ń lù sí orin tí a fi ṣe àpẹrẹ lókè yìí. Gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ̀, ìlú yìí gbọ́dọ̀ máa wọ́ nílẹ̀ ni.
Jàbàtá Ojú-Ìwé 12. Irú òrin Ifá ìsàlẹ̀ yìí ni a máa ń kọ sí i pé:- Lílé: Ẹ wáà báni ṣe é é é, Ẹ̀yín ará ọ̀run un un, Ẹ wáà báni ṣe é è e, Ẹyín ará ọ̀run un un un, Ẹ̀yín ín alááṣekù; Ẹ wá báni ṣe é é.
Mẹ́tamẹ́ta Ojú-Ìwé 13. Irú orin-Ifá ìṣàlẹ̀ yìí ni a máa ń kọ sí i pé: Lílé: Àṣẹ̀ṣe o ò o; La ó bọ káá wa tó ó bọ̀rìṣà o; Ikin ẹni, àṣẹ̀ṣe
Ẹ̀sá Ojú-Ìwé 13-14. Ẹ̀ka ìlù yìí máa ń le díẹ̀. Ẹni tí ń lu kon-kon-kolo yóò máa ṣá agogo lọ ní tirẹ̀ ni. Onípapapa náà ò sì ní í dáwọ́ dúró. Ènìyàn le mú irú ìlù yìí le. A sì tún le mú un dẹ̀. Ibí yìí gan-an ni òógùn ti ń bọ́ kíkan-kíkan lára ọmọ Awo tó bá le jó ju òkòtó lọ. Ohùn ẹni tí ń dárin le pin nígbà tí alágogo bá lé e láré kọjá ibi agbára rẹ̀ mọ.
Ètò ohùn inú orin Ifá Ojú-Ìwé 15-17.
àtúnṣeOhun tó máa ń tètè hàn sí ènìyàn tó bá fẹ́ tú ìfun àti ẹ̀dọ̀ iṣẹ́ kan wò ni ohun tó jẹ etí lógún. Dídùn àti dídùn ibẹ̀. Ọ̀gbẹ̀rì akọrin-Ifá ni yóò máa fi oríṣìí ohùn kan náà gbe ara wọn. Bí ohùn òkè bá wà ní orí ìlà àkọ́kọ́, fún àpẹrẹ, ohùn tí ọ̀rọ̀ tí ó wá ní ìlà tí a óò fi gbè é gbọ́dọ̀ tako ti àkọ́kọ́ ní ìbẹ̀rẹ̀, ààrin tàbí ní ìparí.
Èto Èrò inú orin Ifá Ojú-Ìwé 18.
àtúnṣeÓ ní irú àwọn ọ̀rọ̀ tí a le tò mọ́ ara wọn nínú orin Ifá.
Fún Àpẹrẹ:
Lílé: Ifá ni n ó ma sìn o o o,
Mo forin kọ o ò o,
Ifa ni n ó ma sìn,
Mo forin kọ.
Ọ̀pẹ̀ ni n ó ma sìn o ò o;
Ẹ má pa mí o ò o;
Ifá ni ó ma sìn
Mo forin kọ.
Bátànì orin Ifá Ojú-Ìwé 19.
àtúnṣeKì í ṣe gbogbo ìgbà ni ìlà kan inú orin-Ifá máa ń gbé èrò kan jáde. Ó le jẹ́ pé tí a bá ka ìlà orin méjì sí mẹ́ta ni a óò tó rí èrò tí orin kan gbé jáde. Ẹ jẹ́ kí á tún wo àpẹẹrẹ orin òkè yìí wò lẹ́ẹ̀kan sí i. A kò le mọ èrò ọ̀kọrin yìí tí a bá gbọ́ ìlà kìíní orin yìí láìgbọ́ ìlà kejì.
Orin Ifá aláàdáákọ Ojú-Ìwé 20
àtúnṣeÀwọn orin-Ifá kan wà tí a kì í gbọ́ ju ohùn ẹnì kan lọ níbẹ̀. Àpẹrẹ irú orin bẹ́ẹ̀ ni orin tí Babaláwo ń kọ nígbà tí ó ń dáfá rẹ̀ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù. Irú irin-Ifá aládàákọ báyìí náà ń fi ipò tí akọrin wà hàn.
Orin Ifá Alájùmọ̀kọ (Oní-lílé àti ègbè) Ojú-Ìwé 21-24.
àtúnṣeÓ kéré parí, ènìyàn méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n máa ń kọ irú orin yìí. Bí babaláwo méjì bá pàdé ara wọn, wọ́n le sun ìyẹ̀rẹ̀ Ifá. Wọ́n sì le kọrin ki Ifá. Àwọn ọmọ ìkọ́ṣẹ́ Ifá náà le kó ara wọn jọ lati máa fi orin-Ifá dá ara wọn lára yá. Tí wọn bá ń ṣe ìpàdè Awo tàbí tí wọn bá ń ṣọdún ifá, Irú bátànì orin Ifá yìí ni a sáábà máa ń lò jù.
Ìlànà tí Akọrin Ifá Máa ń tẹ̀lé Lójú Agbo Eré Ojú-Ìwé 25-30.
àtúnṣeÓ dàbí pé ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú orin Ifá ní kíkọ ni ọ̀nà tí à ń gbà gbé e kalẹ̀ lọ́nà eré. Eré àwògbádùn ni eré orin Ifá ní kíkọ. Ó máa ń irú orin tí wọn fi ń irú orin tí wọn le fí kásẹ̀ eré nílẹ̀. Nígbà tí akọrin Ifá bá ń ṣiṣẹ́ tó gbà yìí lọ, ó níláti bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìyẹ̀rẹ̀ Ifá ní sísun pé:
Ìsọ̀wọ́lò-èdè Inú Orin Ifá Ojú-Ìwé 31.
àtúnṣeKò sí ohun tí ale pè ní ewì ní ilẹ̀ Yorùbá tí a ò ní bá onírúurú ọnà-èdè níbẹ̀. Ó kàn jẹ́ pé àwọn ọnà-èdè wọ̀nyí ṣodo sínú orin-Ifá ju àwọn ohùn ẹnu Yorùbá yòókù lọ. Bí a bá sọ pé orin kan dára, èdè rẹ̀ ló wuyì. Èdè inú orin gbọ́dọ̀ fanimọ́ra.
Àkójọpọ̀ Orin Ifá Ojú-Ìwé 32-90.
àtúnṣeLílé: Atótó ó ó ó;
Atótó Arére, ẹ yáa dákẹ́
Ifá fẹ́ fọhùn;
Ẹ ẹ dákẹ́.
Ègbè: Ọ̀rúnmìlà o ò;
Aatótó ó ó ó;
Atótó ó ó Aaarére e e,
Ẹ yá a dákẹ́,
Ifá fẹ́ fọhùn,
Ẹ dákẹ́.
Iwe ti a yewo
àtúnṣeS.M Raji, J.I. Ogunranti (2004) Ọ̀pẹ̀ ń fọ dídùn 1 Orin Ifá Kingson Publishers. ISBN 978-42602-1-8.