Samuel Adéṣùjọ Adémúlégún jẹ́ ọ̀gá kan lábẹ́ ilé-iṣẹ́ ológun ilẹ̀ Nàìjíríà. Òun ni ọ̀gá àgbà àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ ní ọdún 1966, tí ó dì dé ipò ọ̀gágun pátá pátá fún àwọn ọmọ.ológun ilẹ̀ ní ilẹ̀ Nàìjíríà. Ó gba ipò ọ̀gá 'Officer Corps níbi iṣẹ́ ológun ní ọdún 21949, òun àti Aguiyi Ironsi, Zakariya Maimalari àti Babáfẹ́mi Ògúndípẹ̀. Ó tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ológun tí wọ́n ń díje sí ipò GOC, ẹ́yìn tí ẹni tó dipò náà mú tẹ́lẹ́ fẹ̀yìn tì ní ọdún 1965. Àwọn ọmọ lẹ́yìn rẹ̀ níbi iṣẹ́ ológun ń fọmú nígba tí wọ́n ri wípé ọ̀gá wọn ń ṣe àṣepọ̀ pẹ́lú ọ̀kan lára àwọn olóṣèlú tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ahmadu Bello. Wọ́n pa òun àti ìyàwó rẹ̀ nínú ìdìtẹ̀gnàjọba ọdún 1966, nínú ìdìtẹ̀gbàjọba tí Timothy Onwuatuegwu léwájú rẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ni ní ibùdò ilé-ẹ̀kọ́ ìkọ́ni àwọn ológun ni ó já wọlé rẹ̀ tí ó sì yìnbọn lu òun àti ìyàwó rẹ̀lórí ibùsùn wọn. [1]

Àwọn Ìtọ́ka sí

àtúnṣe
  1. Muffett, D.J.M. (1982). Let truth be told (2. impr. ed.). Zaria, Nigeria: Hudahuda Pub. Co.. p. 32. ISBN 9782368067.