Sana Mouziane
Sana Mouziane (tí wọ́n bí ní ọdún 1980) jẹ́ òṣèrébìnrin àti akọrin ọmọ orílẹ̀-èdè Mòrókò.
Sana Mouziane | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 1980 (ọmọ ọdún 44–45) Casablanca |
Orílẹ̀-èdè | Moroccan |
Iṣẹ́ | Actress, singer |
Ìsẹ̀mí rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bí Mouziane ní ìlú Casablanca. Nígbàtí àwọn òbí rẹ̀ kọrawọn sílẹ̀, ó di ẹni tí ó n gbẹ́ ní ìlú Marrakesh. Mouziane lọ sí ìlú Lọ́ndọ̀nù nígbà tí ó wà lọ́mọ ọdún mẹ́sàn-án.[1] Ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa orin kíkọ ó sì wà nínu ẹgbẹ́ orin kan. Àkọ́kọ́ orin rẹ̀ tí ó kọ lójú ọ̀pọ̀ èrò wáyé nígbà tí ó wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún níbi ayẹyẹ Darlington International Festival.[2] Ó sọ di mímọ̀ wípé gbígbé òun ní Ilẹ̀gẹ̀ẹ́sì tún kún láti la òun lọ́yẹ̀ nípa bí òun ti le gbé ayẹ́ ìrọ̀rùn.[3]
Mouziane ṣe àgbéjáde àkọ́kọ́ orin àdákọ rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ "Inta Lhoub" ní ọdún 2004. Ó kó àkọ́kọ́ ipa sinimá àgbéléwò rẹ̀ nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Women in Search of Freedom ní ọdún 2005, èyí tí Ines Al Dégheidi darí. Fíìmù náà dá lóri àwọn obìnrin tí wọ́n wà láàrè, ó sì gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àmì-ẹ̀yẹ níbi ayẹyẹ àjọ̀dún fíìmù kan. Ní ọdún tí ó tẹ̀le, ó kópa nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Ashra Haramy.[4] Ní ọdún 2007, Mouziane kópa gẹ́gẹ́ bi obìnrin tí ó n ṣe àgbèrè pẹ̀lú àbúrọ̀ ọkọ rẹ̀ kan nínu eré Samira's Garden. Ipa yìí ni ó fun ní àmì-ẹ̀yẹ òṣèrébìnrin tí ó dára jùlọ níbi ayẹyẹ Panafrican Film and Television Festival of Ouagadougou ní ọdún 2009.[5] Ní ọdún 2012, Mouziane kó ipa Zahra nínu eré L'enfant cheikh, èyí tí Hamid Bennani darí. Ó kó ipa Martha nínu eré ti ọdún 2013 kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ The Bible.[6] Ní ọdún 2017, Mouziane kópa nínu eré La Nuit Ardente, èyí tí Bennani darí.[7] Ó sọ di mímọ̀ wípé òun fẹ́ràn láti máa ṣe àwọn ipa tí ó ní ìpèníjà.[8]
Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀
àtúnṣe- 2005: Awọn Obirin Ninu Wiwa Ominira
- 2006: Ashra Haramy
- 2007: Ọgbà Samira
- 2008: Ge Loose
- 2010: Ilọkuro Cairo
- 2012: L'enfant cheikh
- 2013: Bibeli (jara TV)
- 2014: L'anniversaire
- 2014: Ọmọ Ọlọrun
- 2017: La Nuit Ardente
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Le mariage de Sana Mouziane & Alan Dearsley". Chicadresse (in French). 26 March 2018. Archived from the original on 28 October 2021. Retrieved 10 November 2020.
- ↑ "Sanaa Mouziane : Une étoile montante" (in French). 27 October 2007. https://www.bladi.net/sanaa-mouziane-cinema.html. Retrieved 11 November 2020.
- ↑ "Sanaa Mouziane: «Je me retrouve dans les rôles «audacieux»" (in French). 25 September 2016. https://aujourdhui.ma/culture/cinema/sanaa-mouziane-je-me-retrouve-dans-les-roles-audacieux. Retrieved 10 November 2020.
- ↑ "Sana Mouziane «comme nouvelle maman, j’ai beaucoup appris en ligne»". L'internaute (in French). Retrieved 10 November 2020.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ wa Micheni, Mwenda (29 March 2009). "East Africa's Absence felt at Fespaco". Africine. Retrieved 10 November 2020.
- ↑ "Sana Mouziane «comme nouvelle maman, j’ai beaucoup appris en ligne»". L'internaute (in French). Retrieved 10 November 2020.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ Rachet, Olivier (22 September 2017). "« La Nuit ardente » de Hamid Bénani: une ode aux femmes et à la liberté". Le Site Info (in French). Archived from the original on 29 October 2021. Retrieved 10 November 2020.
- ↑ Jadraoui, Siham (25 September 2016). "Sanaa Mouziane: «Je me retrouve dans les rôles «audacieux»" (in French). Aujourdhui Le Maroc. https://aujourdhui.ma/culture/cinema/sanaa-mouziane-je-me-retrouve-dans-les-roles-audacieux. Retrieved 10 November 2020.