Sandra Aguebor jẹ́ mẹ̀kó ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.[2] Òun ni obìnrin àkọ́kọ́ tí ó má se iṣẹ́ mẹ̀kó ní Nàìjíríà[3]. Òun ní olùdásílẹ̀ Lady Mechanic Initiative tí ó gbé kalẹ̀ láti rán àwọn obìnrin tí ó lè tọ́jú ara wọn.[4] Ó kọ́ wọn ní iṣẹ́ mẹ̀kó. Aguebor sọ wípé ó nira fún obìnrin láti dì mẹ̀kó. Ní ọdún 2015, wọn ṣe eré nípa ìtàn ayé rẹ̀[5], eré náà sí gba àmì ẹ̀yẹ níbi ayẹyẹ New York Film Festival[6]. Àkọlé eré náà ni Sandra Aguebor : The Lady Mechanic. Wọ́n yàán fún àmì ẹ̀yẹ COWSOL award, èyí tí ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó gbé kalẹ̀ láti lè fi ìyìn fún àwọn èèyàn tí ó tí kópa sí ìdàgbàsókè ìpínlè náà[7][8]. Ó gbà àmì ẹ̀yẹ Inspirational woman of the year láti ọ̀dọ̀ gómìnà tẹ́lẹ̀, Akinwunmi Ambode.[9] Ìjọba àpapọ̀ tí Nàìjíríà sí ti fun ní àmì ẹ̀yẹ.[10]

Sandra Aguebor
Ọjọ́ìbí1970s [1]
Benin City
Orílẹ̀-èdèNigeria
Ẹ̀kọ́Pan-Atlantic University
Iṣẹ́Mechanic
Gbajúmọ̀ fúnBeing the first female Nigerian mechanic

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe