Sandra Nkaké (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ 15 Oṣù Kọkànlá, Ọdún 1973) jẹ́ òṣèrébìnrin àti akọrin ọmọ orílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù

Sandra Nkaké
Ọjọ́ìbí15 Oṣù Kọkànlá 1973 (1973-11-15) (ọmọ ọdún 51)
Yaoundé
Orílẹ̀-èdèCameroonian
Iṣẹ́Actress, screenwriter, presenter, film editor
Ìgbà iṣẹ́1996-present

Ìsẹ̀mí rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí Nkaké ní ìlú Yaoundé, orílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù ní ọdún 1973. Nígbà tí ó pé ọmọ ọdún 12, ó kó lọ sí orílẹ̀-èdè Faransé.[1] Nkaké ti fẹ́ràn orin kíkọ láti ìgbà èwe rẹ̀, àti pàápàá ó fẹ́ràn okùnrin akọrin kan tí wọ́n pè ní Prince.[2] Síbẹ̀síbẹ̀, ó fẹ́ láti di olùkọ́ni lédè Gẹ̀ẹ́sì. Ó kẹ́kọ̀ọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga Sorbone tí ó wà ní orílẹ̀-èdè Paris. Nígbàtí ó pé ọmọ ogún ọdún, ó yí ọkàn rẹ̀ padà láti kọjúmọ́ eré ìtàgé ṣíṣe. Lẹ́hìnwá ni ó lọ ṣe àyẹ̀wò fún ipa eré kan tó sì tibẹ̀ di òṣèré. Nkaké kó àkọ́kọ́ ipa rẹ̀ nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ The Crucible ní ọdún 1994, èyí tí Thomas Ledouarec darí. Ní ọdún tí ó tẹ̀le, ó kópa nínu eré Le Dindon.[3]

Nkaké ṣe àkọ́kọ́ ipa sinimá àgbéléwò rẹ̀ nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Les Deux Papas et la Maman ní ọdún 1996, èyí tí Jean-Marc Longval ṣe adarí rẹ̀.[4] Lẹ́hìnwá rẹ̀, ó kópa nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn sinimá àgbéléwò àti àwọn eré tẹlifíṣọ̀nù míràn, ṣùgbọ́n Nkaké gbìyànjú láti ri dájú wípé ó síì fọkàn sí iṣẹ́ orin rẹ̀ náà. Ní ọdún 1996, ó kópa nínu iṣẹ́ orin kan tí wọ́n pè ní Ollano trip-hop project ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Hélène Noguerra. Ní àkókò àwọn ọdún 2000, Nkaké fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn akọrin míràn bíi Jacques Higelin, Daniel Yvinec and the National Jazz Orchestra, Julien Lourau, àti Rodolphe Burger.[5] Ó tún ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú Gerald Toto àti David Walters fún ti iṣẹ́ àkànṣe Urban Kreol Project.[6]

Ní ọdún 2008, Nkaké ṣe àgbéjáde àkọ́kọ́ àkójọpọ̀ àwọn orin rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Mansaadi, èyí tí ó kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn eré orin sínú tó fi mọ́ àwọn eré orin tí ó ṣe ní ilẹ̀ Áfríkà àti Brasil.[7] Ní ọdún 2012, ó ṣe àgbéjáde ẹ̀kejì àkójọpọ̀ àwọn orin rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Nothing for Granted, ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Ji Drû. Láti ilé-iṣẹ́ orin tí wọ́n pè ní Jazz Village Record Label ni ó ti gbé orin náà jáde. Ó gba àmì-ẹ̀yẹ kan níbi ayẹyẹ Victoires du Jazz ní Oṣù Keèje Ọdún 2012.[8] Ní Oṣù Kẹẹ̀sán Ọdún 2017, ó ṣe àgbéjáde ẹ̀kẹẹ̀ta àkójọpọ̀ àwọn orin rẹ̀ tí ó pe àkọ́lé rẹ̀ ní Tangerine Moon Wishes.[9]

Àwọn iṣẹ́ orin rẹ̀

àtúnṣe
  • 2008 : Mansaadi (Cornershop/Naïve)
  • 2012 : Nothing For Granted (Jazz Village/Harmonia Mundi)
  • 2017 : Tangerine Moon Wishes (Jazz Village)

Àwọn àṣàyàn eré rẹ̀

àtúnṣe
  • 1996 : Les Deux Papas et la Maman
  • 2000 : The Girl
  • 2003 : Bienvenue au gîte
  • 2004 : Casablanca Driver
  • 2009 : King Guillaume
  • 2011 : Toi, moi, les autres
  • 2014 : Not My Type
  • 2015 : Mes chers disparus (TV series) : Brigitte Elbert
  • 2016 : Bienvenue au Gondwana
  • 2017 : La Fin De La Nuit : Nanda
  • 2017 : Une saison en France
  • 2018 : Photo de Famille

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Sandra Nkake". FranceInter (in French). Retrieved 12 November 2020. 
  2. "Sandra Nkake". FranceInter (in French). Retrieved 12 November 2020. 
  3. "Sandra Nkake". FranceInter (in French). Retrieved 12 November 2020. 
  4. "Sandra Nkaké annonce la sortie d’un nouvel album" (in French). https://www.musicinafrica.net/node/24851. Retrieved 12 November 2020. 
  5. "Sandra Nkake". FranceInter (in French). Retrieved 12 November 2020. 
  6. "Généreuse Sandra Nkaké" (in French). https://musique.rfi.fr/musique/20090529-genereuse-sandra-nkake. Retrieved 12 November 2020. 
  7. "Sandra Nkake". FranceInter (in French). Retrieved 12 November 2020. 
  8. "Victoires du Jazz : Bojan Z et Sandra Nkake consacrés" (in French). https://www.fip.fr/victoires-du-jazz-bojan-z-et-sandra-nkake-consacres-16203. Retrieved 12 November 2020. 
  9. "Musique / Les bons vœux de Sandra Nkaké" (in French). Archived from the original on 8 November 2021. https://web.archive.org/web/20211108013203/https://lejsd.com/content/les-bons-v%C5%93ux-de-sandra-nkak%C3%A9. Retrieved 12 November 2020. 

Àwọn ìtakùn Ìjásóde

àtúnṣe