Sani Musa Abdullahi, tí wọ́n tún mọ̀ sí Sani Danja tàbí Danja tí wọ́n bí ní ogúnjọ́ oṣù Kẹrin ọdún 1973 jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé, olùgbéré-jáde, alájótà àti olórin ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà .[2] Ó kópa nínú àwùjọ Kannywood àti Nollywood.[3] Ní oṣù Kẹ́rin ọdún 2018, tí ó jẹ́ Etsu Nupe , Yahaya Abubaka, wé láwàní fun gẹ́gẹ́ bí Zakin Arewa. [4][5]

Sani Musa Danja
Ọjọ́ìbí20 Oṣù Kẹrin 1973 (1973-04-20) (ọmọ ọdún 51)
Fagge, Kano, Nigeria[1]
Orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Iṣẹ́Òṣèré orí-ìtàgé, Olùgbéré-jáde, Adarí eré àti Singer, Alájótà
Olólùfẹ́Mansura Isa
Àwọn ọmọ4

Iṣẹ́ rẹ̀

àtúnṣe

Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ eré ìtàgé Hausa ní ọdún 1999 nínú eré Daliba. Danja ti gbé àwọn eré ó sì ti darí àwọn eré bíi: Manakisa, Kwarya tabi Kwarya, Jaheed, Nagari, Wasiyya, Harsashi, Gidauniya, Daham, Jarida, Matashiya, àti àwọn mìíràn. Danja di ìlú-mòọ́ká ní ọdún 2012 nínú eré Daughter of the River. [6][7]

Àwọn àṣàyàn eré rẹ̀

àtúnṣe

Sani ti kópa nínú eré , ó sì ti gbé eré jáde ó sì ti darí eré Kannywood àti Nollywood. Lárà rẹ̀ ni :[8]

Àkọ́lé eré Ọdún
Yar agadez 2011
A Cuci Maza 2013
Albashi (The salary) 2002
Bani Adam 2012
Budurwa 2010
Da Kai zan Gana 2013
Daga Allah ne'’ (Is from the God) 2015
Daham 2005
Dan Magori 2014
Duniyar nan 2014
Fitattu 2013
Gani Gaka 2012
Gwanaye 2003
Hanyar Kano 2014
Kukan Zaki (The lion's cry) 2010
The other side 2016
Buri uku a duniya (Three wishes in the world) 2016

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Sani Danja [HausaFilms.TV – Kannywood, Fina-finai, Hausa Movies, TV and Celebrities]". hausafilms.tv. Retrieved 21 January 2019. 
  2. Blueprint (2017-10-14). "It pains how people download our films – Danja". Blueprint Newspapers Limited (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-09-24. 
  3. "Nollywood – Kannywood Scene". Retrieved 5 February 2019. 
  4. "Kannywood actor, Sani Danja Turbaned as Zaki Af Arewa". Modern Ghana. 26 April 2018. Retrieved 21 January 2019. 
  5. "Kannywood: Sani Danja turbaned by Etsu Nupe". Premium Times Nigeria. 10 August 2017. Retrieved 21 January 2019. 
  6. "Kannywood Star Actor Becomes Richest Northern Entertainer". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2014-09-26. Retrieved 2020-09-24. 
  7. "Kannywood actor, Sani Danja, makes Nollywood debut". Premium Times Nigeria. 1 September 2012. Retrieved 22 January 2019. 
  8. "Sani Danja [HausaFilms.TV – Kannywood, Fina-finai, Hausa Movies, TV and Celebrities]". hausafilms.tv. Retrieved 23 January 2019.