Seriki Williams Abass ( 1870–1919)[1] jẹ́ oníṣòwò ẹrú tẹ́lẹ̀ tí ó fìgbàkan jẹ́ ìkan lára àwọn ẹrú Abass ti Dahomey. Williams tí ó ń jẹ́ jẹ́ orúkọ olówó trẹ̀ tí ó ràá tí ó sì mu lọ sí orílẹ̀ èdè Brazil ní ibi tí ó ti kọ́ oríṣi èdè mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Abass jẹ́ mùsùlùmí tí ó sì jẹ oyè Séríkí àdínì ti ìlú Badagry. Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ Anago Osho tí ó jẹ́ aṣọ́bodè ilé ọnà Seriki Williams Abass, ọ̀gbẹ́ni Seriki Williams Abass jẹ́ ẹrú tí olówó rẹ̀ , Williams fẹ́ràn tí ó sì kọ̀ láti ta ẹrú yìí nítorí pé ó jẹ́ ẹrú tí ọpọlọ rẹ̀ pé tí ìwà rẹ̀ sí dára púpọ̀. Ọpọlọ ẹrú yìí pé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ó sì gbọ́ èdè mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, Gẹ̀ẹ́sì, Dọ́ọ̀ṣì, Àgùdà àti sípáníṣì. Nígbà tí ó yá, olówó rẹ̀ ní kí ó darapọ̀ mọ́ oun nínú òwò ẹrú. Olówó rẹ̀ yìí ni ó ṣokùnfa bí ó ṣe padà sí ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú. Nígbà tí ó dé orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ó kọjá sí ofin ní ègbẹ́ ìsàlẹ̀ èkó ní erékùṣù èkó. [2]

Seriki Williams Abass
Ère Seriki Williams Abass
Ọjọ́ìbíìlú Ijoga Orile ní ìpínlẹ̀ Ogun
Orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Ọmọ orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Iṣẹ́Oníṣòwò ẹrú

Ìgbà èwe

àtúnṣe
 
Brazilian Barracoon

Wọ́n bí Abass sí ìlú Ijoga Orile ní ìpínlẹ̀ Ogun, orúkọ àbísọ rẹ̀ sì ni Famerilekun. Oníṣòwò ẹrú, Williams ní ó ràá lọ́wọ́ Abass, tí ó sì múu lọ sí orílẹ̀ èdè Brazil. Nítorí ìwà rẹ̀ tó dára, ó kọ̀ láti tàá tí ̣rú yìí sì ń báa gbé. Olówó rẹ̀, Williams yìí ni ó ṣokùnfa bí ó ṣe padà sí ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú, Áfíríkà. Nígbà tí ó dé orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ó gbé ní Erékùṣù Èkó kí ó tó kọjá sí Ìlú Badagry.[2] Olówó rẹ̀, Williams àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ní ó kọ́ Brazilian Barracoon tí wọ́n fi ọparun kọ́ ní ọdún 1840 fún. Abass fẹ́ ìyàwo ọgọ́rún-léméjìdínlọ́gbọ̀.[2] Ó jẹ oyè Seriki àdínì gbogbo ilẹ̀ Yorùbá.[2]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe