Ṣeun Àjàyí jẹ́ òṣèrékùnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìlú Ijebu Ibefun, ní Ìpínlẹ̀ Ògùn, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1] Ó gbajúmọ̀ fún ìkópa rẹ̀ nínú fíìmù orí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Hustle. Wọ́n bí Ajayi ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kẹta, ní Ìpínlẹ̀ Kaduna, òun sì ní àbígbẹ̀yìn láàárín àwọn ọmọ márùn-ún tí àwọn òbí rẹ̀ bí. Nígbà tí ó wà ní ọmọdún mẹ́sàn-án, àwọn òbí rẹ̀ kó kúrò ní Eko. Bàbá rè jẹ́ òṣìṣẹ́ ìjọba tó ti fẹ̀yìntì, ìyá rè sì jẹ́ oníṣòwò. Ìpínlẹ̀ Èkó ló ti bẹ̀rẹ̀ ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀, títí tí ó fi wọ University of Lagos, níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè B.A nínú ìmọ̀ Theatre Arts.

Seun Ajayi
Ọjọ́ìbí31 March
Kaduna
Orílẹ̀-èdèNigerian
Iléẹ̀kọ́ gígaUniversity of Lagos
Iṣẹ́Actor
Gbajúmọ̀ fúnHustle

Ayé àti iṣé rè

àtúnṣe

Wọ́n ti yan Ajayi fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì-ẹ̀yẹ ní Africa Movie Academy Awards (AMAA) àti ní Africa Magic Viewer’s Choice Award gẹ́gé bí i òṣèrékùnrin tó dára jù lọ.

Ó ní ju wákàtí 136 lórí ìwòran Pan-African nínú fíìmù Hustle, ẹ̀bùn Ajayi náà ti farahàn nínú àwọn fíìmù bí i Ojukokoro: Greed, God Calling, The Ghost and the House of Truth, àti 93 Days. Àwọn fíìmù mìíràn tó kópa nínú ni The Maze, Gidi Culture, Have a Nice Day, Crimson àti Gidi Up.

Ajayi ti lo ohùn rẹ̀ fún ìpolongo oríṣiríṣi ọjà, fíìmù àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Lára àwọn ilé-iṣẹ́ tó ti fi ohùn rẹ̀ polówó fún ni; Uber, Keystone bank, First Bank, The Guardian, Ndani Communications, Total, Olam, Temple Productions, Telemundo, àti DSTV.

Ìgbésí ayé rẹ̀

àtúnṣe

Arábìnrin Damilola Oluwabiyi ni ìyàwó Ajayi, ọjọ́ kẹsàn-án oṣù kẹsàn-án, ọdún 2017 sì ni wọ́n ṣe ìgbeyàwó.[2] Fọ́nrán Ajayi bọ́ sí gbàgede, níbi tí ó ti ń ṣàjọyọ̀ pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ ní ọjọ́ ìgbéyàwó wọn.[3] Ní oṣù kìíní ọdún 2019, òun àti ìyàwó rẹ̀ bí ọmọ àkọ́kọ́ wọn, tó jẹ́ ọkùnrin.[4]

Àtòjọ àwọn fíìmù rẹ̀

àtúnṣe

Fíìmù àgbéléwò

àtúnṣe

Fíìmù kékeré

àtúnṣe
  • Erased (2016)[7]
  • Stuck (2019)[8]
  • Closed

Fíìmù orí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán

àtúnṣe

Àwọn fíìmù orí ẹ̀rọ-ayélujára

àtúnṣe
  • Crimson (as Akin)

Àwọn àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n ti yan Seun Ajayi fún àwọn àmì-ẹ̀yẹ bí i:

  • The Future awards Africa prize for acting,
  • Best actor in a supporting role at Africa Movie Academy Award
  • Best Actor in a comedy series at the Africa Magic Viewer's Choice Awards
  • Revelation of the year at City People Movie Award.

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "5 things you should know about actor". Pulse.ng (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2016-04-01. Archived from the original on 2020-02-21. Retrieved 2019-05-17. 
  2. "Actor speaks about epic first kiss moment at his wedding". Pulse.ng (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-02-10. Retrieved 2019-05-17. 
  3. "First thing to do when assigned a movie role is… —Actor Seun Ajayi". Tribune Online (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-01-12. Archived from the original on 2019-05-17. Retrieved 2019-05-17. 
  4. "Seun Ajayi welcomes son with wife". Pulse.ng (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-01-25. Archived from the original on 2019-05-17. Retrieved 2019-05-17. 
  5. "Alex Ekubo, Ali Nuhu Nominated For BON Awards 2016 [FULL LIST]". Nigerian Bulletin - Naija Trending News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-05-17. 
  6. "BB Sasore releases official trailer for new movie, 'God Calling'". Pulse.ng (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-11-18. Archived from the original on 2019-05-17. Retrieved 2019-05-17. 
  7. BellaNaija.com (2016-05-13). "Nigerian Short Film “Erased” starring Tope Tedela, Diana Yekinni, Seun Ajayi & More to be Showcased at Cannes Festival 2016 | Watch the Trailer". BellaNaija (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-05-17. 
  8. "Ozioma Ogbaji’s Short Film "Stuck" starring Seun Ajayi, Lala Akindoju & Uzoamaka Aniunoh is a Must Watch". BellaNaija (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-01-23. Retrieved 18 May 2020.