Ile-ikawe Simeon Adebo jẹ́ ilé-ìkàwé gbogbogbò tí ó wà ní ìlú Abẹ́òkúta, ni Ipinlẹ Ògùn . Ilé-ìkàwé yìí ni a fi sọrí olóògbé Simeon Adébò tí ó tún jẹ́ agbẹjọ́rò àti aṣojú orílẹ̀-èdè Náíjíríà tẹ́lẹ̀. Ilé-ìkàwé náá jẹ́ olú ilé-ìkàwé fún gbogbo ilé-ìkàwé t'ókù ní ìpínlẹ̀ Ògùn. Ìtàn ilé-ìkàwé ní ìpínlẹ̀ Ògùn ni ó bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kẹtá oṣù kejì ọdún 1976, tí wọ́n sì ṣe ì̀filọ́ọ́lẹ̀ rẹ̀ ní ọdún 1990.[1][2]

Àwòrán Simeon Adebo Library

Wọ́n dá ilé-ìkàwé Simeon Adébọ̀ sílẹ̀ ní ọjọ́ kínní osù kejì ọdún 1976 nígbà tí wọ́n dá ìpínlẹ̀ náà sílẹ̀ látì ẹkùn ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Nàíjíríà. Wọ́n sì ṣí olú ilè-ìkàwé náà ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù keje ọdún 1990.[2] [2]

Awọn itọkasi

àtúnṣe