Simson Shituwa

Àlùfáà ti ìlú Namibia

Simson Teteinge Haivela Shituwa (tí a bí ní ọdún 1871 Oilambo, Oukwanyama, Angola — tí ó sì fi ayé sílẹ̀ ní ọjọ́ ọgbọ̀n oṣù kìní ọdún 1969[1]) jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùsọ́ àgùntàn méje tí Matti Tarkkanen yàn ní Oniipa, Ovamboland, ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹsàn-án ọdún 1925 lábẹ́ ìdarí Bíṣọ́bù Tampere, Jaakko Gummerus.[2]

A bí Shituwa ní ọdún 1871 sí inú ìdílé Shituwa shaHaivela àti Namutenya. A ṣe ìrìbọmi fun ní ọjọ́ kẹ́rìndínlógún oṣù kẹta ọdún 1902. Ó kọ́ nípa iṣẹ́ àlùfáà láàrin ọdún 1922 sí 1925 ní Oniipa.[1]

Ó ṣiṣẹ́ ní Endola láàrin ọdún 1925 sí 1940 àti láàrin ọdún 1945 sí 1969 àti ní Eenhana láàrín ọdún 1941–l sí 1944.[1]

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 1.2 Nambala, Shekutaamba V. V. (1995). Ondjokonona yaasita naateolohi muELCIN 1925–1992. Oniipa, Namibia: ELCIN. p. 192. 
  2. Peltola 1958, p. 212.