Sneh Gupta (tí a bí ní ọjọ́ kejìlá osù kàrún ọdún 1957) jẹ́ Olùdarí Alásẹ Sucheta Kriplani Shiksha Niketan (SKSN), ilé-ìwé ibùgbé fún àwọn ọmọ tí ó ní ìpènijà ti ara. A mọ̀ọ́ fún iṣẹ́ rẹ̀ lórí èto amóhùnmáwòrán Sale of the Century àti Angels, bákańnà pẹ̀lú ipa tí ó kó gẹ́gẹ́ bí Ọmọba-bìnrin Sushila nínú eré. [1] Ó tún dá ilé-iṣẹ́ tí ó se ìṣelọ́pọ̀ sílẹ̀.[1]

Sneh Gupta
Ọjọ́ìbíSneh Lata Gupta
Ọjọ́ kejìlá Osù kàrún Ọdún 1957
Nairobi, Kenya
Iṣẹ́
  • Aláṣẹ àti Olùdarí ilé-ìwé
  • Òsèré
  • Olùdásílẹ̀
Ìgbà iṣẹ́1977–di àsìkò yí

Ìgbésí ayé

àtúnṣe

A bí Gupta ní Kenya ní ọjọ́ kejìlá Oṣù Kàrún ọdún 1957, gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ márùn fún àwọn òbí rẹ̀ tí ó jẹ́ Indian. Bàbá rẹ̀ jẹ́ olùkọ́, ó sì lọ sí gbogbo ilé-ìwé èyíkèyí tí ó kọ́. [2]

Ó rìnrìn-àjò lààkọ́kọ́ bí ọmọde láti le tẹ̀lé iṣẹ́ olùkọ́ bàbá rẹ̀. [1] Síbẹ̀síbẹ̀, kò fẹ́ ní ǹkankan ṣe àti pé ó fẹ́ òmìnira tirẹ̀, ó fi ilé sílẹ̀ ní ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún tí ó sì lo ọdún kan láti kẹ́kọ̀ọ́ ní Germany ṣaájú kí ó tó wá sí England. [2]

Eré Ṣíṣe àti àwòṣe

àtúnṣe

Ní àkókò tí ó ń gbé ní Bedford lẹ́yìn tí ó kó kúrò ní United Kingdom ní ọdún 1974, Gupta kọ́kọ́ kéẹ̀kọ́ọ́ láti di nọ́ọ̀sì. [3] Tí ó sì sọ pé òhun ṣe bẹ́ẹ̀ fún yẹ̀yẹ́, ó pinnu láti ṣe ìdánwò Miss Anglia TV, tí ó sì borí, ó sì tún gba òkìkí ní ọdún 1977. [4] [3] Èyí ni ó jẹ́ kí ó di olóòtú fún èto ITV gameshow Sale of the Century pẹ̀lu Nicholas Parsonsfún ọdún kan títí di ọdún 1978, lẹ́yìn èyí ó ṣí ilé ìtajà asaralóge ti ìgbàlódé kan tí a pè ní “Plumage” ní Bedford. [3] Gupta wá gbìyànjú iṣẹ́ àwòṣe ṣùgbọ́n ó fi sílẹ̀, nígbà tí ó rí wípé òhun kò le ṣe é pẹ̀lú iṣẹ́ eré ṣíṣe. Gupta tẹ̀síwájú láti ṣe ìfarahàn nínú Turtle's Progress,[5] Lingalongamax,[5] Crossroads,[6] Doctor Who (1984's Resurrection of the Daleks),[7] Kim,[8] Tandoori Nights.[9] àti Octopussy.[10]

Ní ọdún 1981 ó kópa nínú eré An Arranged Marriage, eré ITV kan nípa Sikh kan tí ó lọ sí Midlands ní ọdún 1950s, àti ìgbéyàwó tí a ṣètò fún àti fún ọmọbìrin rẹ́. Ìtàn náà dá lórí àlàyé láti àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn sikh tí ó lé ní àádọ́talénígba. [11] Iṣé rẹ̀ nínú The Far Pavillions engages in suttee, ìṣẹ̀lẹ̀ tí Roy West ṣe àpèjúwe ní Liverpool Echo gẹ́gẹ́ bí "ọ̀kan nínú àwọn ìfojúsí tí ó ṣe pàtàkí jùlọ nínú àwọn eré òhun." [12] Ó jẹ́ àlejò lórí Blankety Blank ní ọdún 1987. [13] Gupta ṣe àfihàn Switch On To English, ìdíje fún àwọn tí ó ń sọ ède gẹ̀ẹ́sì bí èdè kejì, ní ọdún 1986, [14] àti Bol Chaal, ètò ẹ̀kọ́ ède Hindi àti Urdu, ní ọdún 1989. [15] Ní ọdún 1991, ó wà lára olóòtú fún The magazine programme One World pẹ̀lú Mike Shaft.[16]

Ní Ọdún 1987, Gupta gé irun rẹ̀ pẹ̀lú ìgbìyànjú láti yàgò fún títẹ̀ síta bí ọ̀dọ́mọdébìrin, tí ó ní ìwà pẹ̀lẹ́ sùgbọ́n tí kò ní àànfání sí àwọn ipa tí ó lérò fún. [17] Ó tún ṣe àgbékalẹ̀ ilé-iṣẹ́ ìṣelọ́pọ̀ tirẹ̀. [18]

Iṣẹ́ ìṣelọ́pọ̀

àtúnṣe

Gupta kó lọ sí India ní ọdún 1996 lẹ́yìn tí ó ti gbé ní England. Ní India, ó ti ṣiṣẹ́ lórí àwọn ìwé-ìpamọ́ bí olùwádìí, olùṣàkóso ipò, amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ olùdásílẹ̀, àti olùdarí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olùgbóhùnsáfẹ́fẹ́. [19]

Alásẹ àti Olùdarí SKSN

àtúnṣe

Gupta jẹ́ alásẹ àti olùdarí Sucheta Kriplani Shiksha Niketan (SKSN), ilé-ìwé fún àwọn ọmọ ilé-ìwé tí ó ní ìpèníjà ara. [19] ó sì tẹ̀síwájú láti bẹ̀rẹ̀ èto Indian Mixed Ability Group Events (IMAGE) programme ní ọdún 2004 [20] tí ó sì yọrí sí ìpilẹ̀ṣẹ̀ ti Indiability Foundation ní ọdún 2011.

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe

 

  1. 1.0 1.1 1.2 Donnell, Alison (2002) (in en). Companion to Contemporary Black British Culture. Routledge. p. 132. ISBN 9780415262002. https://books.google.com/books?id=VfdpdZ9DwH0C&pg=PA132&dq=sneh+gupta+alison+donnell&hl=en&sa=X&ved=2ahUKEwjbrf7h3vPvAhXbgf0HHQ_aAAkQ6AEwAHoECAAQAw#v=onepage&q=sneh%20gupta%20alison%20donnell&f=false. Donnell, Alison (2002). Companion to Contemporary Black-British Culture. Routledge. p. 132. ISBN 9780415262002.
  2. 2.0 2.1 Gifford, Zerbanoo (2002) (in en). The Golden Thread: Asian Experiences of Post-Raj Britain. Pandora Press. p. 201. ISBN 9780044406051. https://books.google.com/books?id=G21nAAAAMAAJ&q=sneh+gupta+german&dq=sneh+gupta+german&hl=en&sa=X&ved=2ahUKEwjO3aLM2_PvAhVk_7sIHfWiDI4Q6AEwAXoECAAQAw. Gifford, Zerbanoo (2002). The Golden Thread: Asian Experiences of Post-Raj Britain. Pandora Press. p. 201. ISBN 9780044406051.
  3. 3.0 3.1 3.2 "Feathers will fly". 
  4. One World – MikeSHAFT.com
  5. 5.0 5.1 Smyllie, Patricia (14 May 1979). "Double Vision". Daily Mirror: p. 19. 
  6. Pratt, Mike (16 May 1982). "By public demand". Sunday Mirror: p. 19. 
  7. Cook, Benjamin (February 2021). "Starship Troopers". Doctor Who Magazine (560): 20–22. ISSN  . 
  8. "Sneh Gupta". British Film Institute. Retrieved 14 April 2021. 
  9. "Channel 4". Sandwell Evening Mail: p. 18. 16 October 1987. 
  10. "Change of direction". Reading Evening Post: p. 13. 7 October 1989. 
  11. "Wedded to tradition?". 
  12. "The Raj and the motel princess". 
  13. "Television". 
  14. "Sunday: BBC1". 
  15. "Change of direction". 
  16. "Change of direction". Reading Evening Post: p. 13. 7 October 1989. 
  17. Roy, Amit (7 May 1989). "Eastern promise wasted - Asian actresses". The Sunday Times. 
  18. Wavell, Stewart (24 September 1989). "Turning up the voice of Asia - People". The Sunday Times. 
  19. 19.0 19.1 Executive Director - SKSN
  20. Sneh Gupta | sportanddev.org