Sokari Ekine
Sokari Ekine jẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà,[1] blogger[2][3] àti oǹkọ̀wé. Ó ṣiṣẹ́ oníròyìn ní Pambazuka News tí ó sìn ti kọ̀wé fún Feminist Africa àti New Internationalist. Ekine ti fìgbà kan ní ìkànnì ìtakùrọ̀sọ ayélujára láàárín ọdún 2004 àti 2014, níbi tí ó ti máa ń tàkùrọ̀sọ nípa ẹ̀tọ́ obìnrin, ẹ̀tọ́ ìbálòpọ̀ akọ àti akọ, abo àti abo, àti ọ̀rọ̀ nípa àwùjọ. Ó ti dìjọ kọ̀wé pẹ̀lú àwọn oǹkọ̀wé mìíràn, bẹ́ẹ̀ ló ti ṣe lámèyítọ́ fún ìwé mẹ́rin, ó sìn tí ṣe olùkọ́ àwọn ọmọdé ní Haiti.
Sokari Ekine | |
---|---|
Iṣẹ́ | Ajàfẹ́tọ̀ọ́, blogger, oǹkọ̀wé |
Gbajúmọ̀ fún | Women's rights, LGBTI rights and environmental campaigns |
Website | sokariekine.me |
Ekine ti ṣe lámèyítọ́ fún ìwé tí àkọlé rẹ̀ ń jẹ́ Blood and Oil: Testimonies of Violence from Women of the Niger Delta lọ́dún 2001,[4] SMS Uprising: Mobile Phone Activism in Africa (2010),[5] African Awakenings pẹ̀lú Firoze Manji lọ́dún 2011, àti Queer African Reader pẹ̀lú Hakima Abbas lọ́dún 2013.
Ayé àti ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀
àtúnṣeEkine jẹ́ ọmọ bíbí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà nípasẹ̀ bàbá rẹ̀, ṣùgbọ́n tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ United Kingdom. Ó dàgbà sí Nigeria, ṣùgbọ́n nígbà tó yá, ó kọjá sí England láti lọ kẹ́kọ̀ọ́ síi. [6] Ó kàwé gboyè dìgírì nínú ìmọ̀ sáyẹ́ńsì ìmọ̀-ẹ̀rọ tuntun àti dìgírì kejì nínú ìmọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ní University of London.[7]
Ekine gbé ní Amẹ́ríkà fún àìmọye ọdún kí ó tó padà sí United Kingdom, níbi tí ó ti gba iṣẹ́ olùkọ́ yunifásítì .[6][7] Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìtàkùn ayélujára lọ́dún 1995.[8] Wọ́n wo àrùn jẹjẹrẹ fún Ekine lọ́dún 2000,èyí ni ó sọ ọ́ dèrò Spain lọ́dún 2004.[6]
Àwọn ìwé tí Ekine kọ àti àwọn tí ó ṣe lámèyító fún
àtúnṣe- Blood and Oil: Testimonies of Violence from Women of the Niger Delta. Centre for Democracy & Development, 2001. ISBN 978-1902296128. Second edition, 2011. "Testimonies by women of the Niger Delta on State sponsored and multinational violence over a period of 10 years from 1990."[9]
- SMS Uprising: Mobile Activism in Africa. Pambazuka, 2010. ISBN 978-1906387358. Texts by Ken Banks, Nathan Eagle, Juliana Rotich, Christiana Charles-Iyoha, Anil Naidoo, Berna Twanza Ngolobe, Christian Kreutz, Redante Asuncion-Reed, and Amanda Atwood.
- African Awakening: The Emerging Revolutions. Pambazuka, 2011. Co-edited with Firoze Manji. ISBN 978-0857490216.
- Queer African Reader. Pambazuka, 2013. Co-edited with Hakima Abbas. ISBN 978-0857490995.
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Herringer, Mark (1 August 2013). "Open development and social impact bonds: rethinking healthcare delivery". The Guardian. Retrieved 2018-08-21.
- ↑ Ford, Liz (2 April 2009). "Bloggers seek to influence G20 on development". The Guardian. Retrieved 2018-08-21.
- ↑ "Found in translation". The Guardian. 12 December 2005. Retrieved 2018-08-21.
- ↑ Vidal, John; Branigan, Tania (22 July 2002). "Nigerian women take on ChevronTexaco". The Guardian. Retrieved 2018-08-21.
- ↑ Perkins, Anne (3 February 2010). "Preparing for a mobile phone uprising in Africa". The Guardian. Retrieved 2018-08-21.
- ↑ 6.0 6.1 6.2 "Nigerian blogger tackles taboos". BBC News. 5 July 2005. http://news.bbc.co.uk/1/hi/technology/4649607.stm.
- ↑ 7.0 7.1 "About". Black Looks. Archived from the original on 1 December 2017. Retrieved 8 November 2017.
- ↑ "Blogging Queer Africa. Interview with Sokari Ekine, April 2015". Barnard Center for Research on Women. Scholar and Feminist Online. Retrieved 21 November 2017.
- ↑ Sokari Ekine. Blood and Oil: Testimonies of Violence from Women of the Niger Delta. https://archive.org/details/SokariEkineBloodandOilTestimoniesofViolencefromWomenoftheNigerDelta_0.